Marku 7 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Marku 7:1-37

Mímọ́ àti àìmọ́

17.1-15: Mt 15.1-11; Lk 11.38.Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu, 2wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. 3(Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. 47.4: Mt 23.25; Lk 11.39.Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)

57.5: Ga 1.14.Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”

67.6-7: Isa 29.13.Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:

“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi

ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.

7Ìsìn wọn jẹ́ lásán,

ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

8Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”

9Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. 107.10: Ek 20.12; De 5.16; Ek 21.17; Le 20.9.Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ 11Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kò bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run. 12Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́. 13Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”

14Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. 15Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.”7.15 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ ìwé Marku kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí aláìmọ́. 16 Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.

177.17-23: Mt 15.15-20; Mk 4.10.Nígbà tí Jesu sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa. 187.18-19: 1Kọ 10.25-27; Ro 14.14; Tt 1.15; Ap 10.15.Jesu béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́? 19Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)

207.20-23: Ro 1.28-31; Ga 5.19-21.Nígbà náà, ó fi kún un pé, “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. 21Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, 227.22: Mt 6.23; 20.15.ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara-ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. 23Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”

Ìgbàgbọ́ obìnrin ará Kenaani

247.24-30: Mt 15.21-28.Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. 25Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. 26Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.

27Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

28Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.”

29“Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”

30Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.

Ìwòsàn ọkùnrin odi àti afọ́jú

317.31-37: Mt 15.29-31.Nígbà náà ni Jesu fi agbègbè Tire àti Sidoni sílẹ̀, ó wá si Òkun Galili láàrín agbègbè Dekapoli. 327.32: Mk 5.23.Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, àwọn ènìyàn sì bẹ Jesu pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.

337.33: Mk 8.23.Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. 34Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). 35Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete.

367.36: Mk 1.44; 5.43.Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó. 37Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́rọ̀, odi sì sọ̀rọ̀.”

New International Reader’s Version

Mark 7:1-37

What Makes People “Unclean”?

1The Pharisees gathered around Jesus. So did some of the teachers of the law. All of them had come from Jerusalem. 2They saw some of his disciples eating food with “unclean” hands. That means they were not washed. 3The Pharisees and all the Jews do not eat unless they wash their hands to make them “clean.” That’s what the elders teach. 4When they come from the market, they do not eat unless they wash. And they follow many other teachings. For example, they wash cups, pitchers, and kettles in a special way.

5So the Pharisees and the teachers of the law questioned Jesus. “Why don’t your disciples live by what the elders teach?” they asked. “Why do they eat their food with ‘unclean’ hands?”

6He replied, “Isaiah was right. He prophesied about you people who pretend to be good. He said,

“ ‘These people honor me by what they say.

But their hearts are far away from me.

7Their worship doesn’t mean anything to me.

They teach nothing but human rules.’ (Isaiah 29:13)

8You have let go of God’s commands. And you are holding on to teachings that people have made up.”

9Jesus continued speaking, “You have a fine way of setting aside God’s commands! You do this so you can follow your own teachings. 10Moses said, ‘Honor your father and mother.’ (Exodus 20:12; Deuteronomy 5:16) He also said, ‘Anyone who asks for bad things to happen to their father or mother must be put to death.’ (Exodus 21:17; Leviticus 20:9) 11But you allow people to say that what might have been used to help their parents is Corban. Corban means A Gift Set Apart for God. 12So you no longer let them do anything for their parents. 13You make the word of God useless by putting your own teachings in its place. And you do many things like this.”

14Again Jesus called the crowd to him. He said, “Listen to me, everyone. Understand this. 15-16Nothing outside of a person can make them ‘unclean’ by going into them. It is what comes out of them that makes them ‘unclean.’ ”

17Then he left the crowd and entered the house. His disciples asked him about this teaching. 18“Don’t you understand?” Jesus asked. “Don’t you see? Nothing that enters a person from the outside can make them ‘unclean.’ 19It doesn’t go into their heart. It goes into their stomach. Then it goes out of the body.” In saying this, Jesus was calling all foods “clean.”

20He went on to say, “What comes out of a person is what makes them ‘unclean.’ 21Evil thoughts come from the inside, from a person’s heart. So do sexual sins, stealing and murder. 22Adultery, greed, hate and cheating come from a person’s heart too. So do desires that are not pure, and wanting what belongs to others. And so do telling lies about others and being proud and being foolish. 23All these evil things come from inside a person and make them ‘unclean.’ ”

Jesus Honors a Greek Woman’s Faith

24Jesus went from there to a place near Tyre. He entered a house. He did not want anyone to know where he was. But he could not keep it a secret. 25Soon a woman heard about him. An evil spirit controlled her little daughter. The woman came to Jesus and fell at his feet. 26She was a Greek, born in Syrian Phoenicia. She begged Jesus to drive the demon out of her daughter.

27“First let the children eat all they want,” he told her. “It is not right to take the children’s bread and throw it to the dogs.”

28“Lord,” she replied, “even the dogs under the table eat the children’s crumbs.”

29Then he told her, “That was a good reply. You may go. The demon has left your daughter.”

30So she went home and found her child lying on the bed. And the demon was gone.

Jesus Heals a Man Who Could Not Hear or Speak

31Then Jesus left the area of Tyre and went through Sidon. He went down to the Sea of Galilee and into the area known as the Ten Cities. 32There some people brought a man to Jesus. The man was deaf and could hardly speak. They begged Jesus to place his hand on the man.

33Jesus took the man to one side, away from the crowd. He put his fingers into the man’s ears. Then he spit and touched the man’s tongue. 34Jesus looked up to heaven. With a deep sigh, he said to the man, “Ephphatha!” That means “Be opened!” 35The man’s ears were opened. His tongue was freed up, and he began to speak clearly.

36Jesus ordered the people not to tell anyone. But the more he did so, the more they kept talking about it. 37People were really amazed. “He has done everything well,” they said. “He even makes deaf people able to hear. And he makes those who can’t speak able to talk.”