Luku 9 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 9:1-62

Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù

19.1-6: Mt 10.1,5,7-11,14; Mk 6.7-12; Lk 10.4-11.Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. 2Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. 3Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. 4Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. 59.5: Ap 13.51.Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.” 6Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìyìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo.

79.7-9: Mt 14.1-2; Mk 6.14-16; Lk 9.19.Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú, 8Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. 99.9: Lk 23.8.Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí, ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn

109.10: Mk 6.30-31; Lk 10.17; Jh 1.44.Nígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida. 119.11-17: Mt 14.13-21; Mk 6.32-44; Jh 6.1-14; Mk 8.4-10.Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.

12Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.”

139.13: 2Ọb 4.42-44.Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.” 14Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn.

Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.” 15Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó. 169.16: Lk 22.19; 24.30-31; Ap 2.42; 20.11; 27.35.Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn. 17Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa agbọ̀n méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù.

Peteru pe Jesu ní Ọmọ Ọlọ́run

189.18-21: Mt 16.13-20; Mk 8.27-30; Jh 1.49; 11.27; 6.66-69.9.18: Lk 3.21; 5.16; 6.12; 9.28; 11.1.Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”

199.19: Lk 9.9; Mk 9.11-13.Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni, àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”

20Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?”

Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.”

21Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan. 229.22: Mt 16.21; Mk 8.31; Lk 9.43-45; 18.31-34; 17.5.Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”

239.23-27: Mt 16.24-28; Mk 8.34–9.1.Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 249.24-25: Mt 10.38-39; Lk 14.27; 17.33; Jh 12.25.Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 269.26: Mt 10.33; Lk 12.9; 1Jh 2.28.Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.

279.27: Lk 22.18; Mt 10.23; 1Tẹ 4.15-18; Jh 21.22.“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”

Ìràpadà

289.28-36: Mt 17.1-8; Mk 9.2-8; 2Pt 1.17-18.9.28: Lk 8.51; 3.21; 5.16; 6.12; 9.18; 11.1.Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. 29Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, 309.30: Ap 1.9-11.Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀, 31tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. 329.32: Jh 1.14.Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró. 339.33: Lk 5.5; 8.24,45; 9.49; 17.13.Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí, jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)

34Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó síji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ. 359.35: Lk 3.22; Jh 12.28-30.Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” 369.36: Mt 17.9; Mk 9.9-10.Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.

Ìwòsàn ọmọkùnrin kan tí o ní ẹ̀mí èṣù

379.37-43: Mt 17.14-18; Mk 9.14-27.Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀. 38Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè pé, “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. 39Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. 40Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”

41Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”

42Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. 439.43-45: Mt 17.22-23; Mk 9.30-32; Lk 9.22; 18.31-34; 17.25.Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, 44“Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín létí, nítorí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.” 45Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti béèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.

Ta ni yí o ga jùlọ

469.46-48: Mt 18.1-5; Mk 9.33-37.Iyàn kan sì dìde láàrín wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn. 47Nígbà tí Jesu sì mọ èrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀. 489.48: Lk 10.16; Mt 10.40.Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀jù.”

499.49-50: Mk 9.38-40; Lk 11.23.9.49: Lk 5.5; 8.24,45; 9.33; 17.13.Johanu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwa rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

50Jesu sì wí fún un, pé, “Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́: nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí i yín, ó wà fún yín.”

Ìtakò àwọn ará Samaria

519.51-56: Mk 10.1; Lk 17.11; Jh 4.40-42.Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu. 529.52: Mt 10.5; Jh 4.4.Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é. 53Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. 549.54: Mk 3.17; 2Ọb 1.9-16.Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?” 55Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí. 56Lẹ́yìn náà Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì lọ sí ìletò mìíràn.

Ìpinnu láti tọ Jesu lẹ́yìn

579.57-60: Mt 8.19-22.Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

58Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

59Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”

60Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn, ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”

619.61: 1Ọb 19.20; Fp 3.13.Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”

62Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”

Habrit Hakhadasha/Haderekh

הבשורה על-פי לוקס 9:1-62

1יום אחד קרא אליו ישוע את שנים־עשר תלמידיו, והעניק להם סמכות וכוח לגרש שדים ולרפא מחלות. 2לאחר מכן שלח אותם לספר לכולם על בוא מלכות האלוהים ולרפא את החולים.

3”אל תיקחו אתכם דבר“, הורה להם ישוע. ”אל תיקחו אתכם מקל הליכה, תרמיל, מזון, כסף ואף לא בגדים להחלפה. 4בכל עיר או כפר התארחו בבית אחד בלבד.

5”אם התושבים לא יקשיבו לדבריכם, צאו מאותה עיר ונערו את העפר מעל רגליכם, כסימן לכך שעשיתם את המוטל עליכם והזהרתם אותם.“

6התלמידים יצאו לדרך, ובעברם מעיר לעיר ומכפר לכפר בישרו את דבר אלוהים וריפאו את החולים.

7כשהגיעו השמועות על כוחו ונפלאותיו של ישוע לאוזני המושל הורדוס, הוא נמלא מבוכה ודאגה, כי היו אנשים שאמרו: ”זהו יוחנן המטביל שקם לתחייה!“ 8או: ”האיש הזה הוא אליהו הנביא!“ היו שאמרו: ”זהו אחד הנביאים שקם לתחייה!“

9”יוחנן?“ תמה הורדוס. ”הרי כרתי את ראשו, אז מיהו האיש שעליו אני שומע ניסים ונפלאות?“ והורדוס חיפש דרך לפגוש את ישוע.

10לאחר שחזרו השליחים ודיווחו לישוע על כל מעשיהם, הוא עזב את הקהל איתם והם הלכו יחד לבית־צידה כדי להיות לבדם. 11אבל ההמונים גילו לאן ישוע הלך והלכו בעקבותיו. ישוע קיבל אותם בחמימות ולימד אותם על מלכות האלוהים. הוא גם ריפא את החולים שביניהם.

12לפנות ערב ניגשו שנים־עשר התלמידים אל ישוע והאיצו בו לשלוח את הקהל אל הכפרים והמשקים שבסביבה כדי לקנות אוכל ולחפש מקום לינה, כי האזור שבו היו היה שומם לגמרי. 13”אתם תאכילו אותם!“ אמר ישוע לתלמידיו.

אך התלמידים אמרו: ”יש לנו רק חמש ככרות לחם ושני דגים. האם אתה רוצה שנלך לקנות אוכל לכל ההמון הזה?“ 14כחמשת־אלפים גברים היו שם (לא כולל נשים וילדים).

”אמרו להם לשבת בשורות של חמישים איש“, הורה ישוע לתלמידיו. 15התלמידים עשו כדבריו והושיבו את הקהל.

16ישוע לקח את חמש ככרות הלחם ואת שני הדגים, הביט לשמים, וביקש מאלוהים שיברך את האוכל. לאחר מכן פרס את הלחם, חתך את הדגים והגיש לתלמידיו שיחלקו לעם. 17כולם אכלו עד ששבעו, וכאשר אספו את הפירורים שנשארו מילאו שנים־עשר סלים.

18יום אחד כשהתפלל ישוע לבדו ורק תלמידיו היו בחברתו, הוא שאל אותם: ”למי חושבים אותי האנשים?“

19”ליוחנן המטביל“, השיבו התלמידים. ”אבל יש החושבים שאתה אליהו הנביא, ואחרים חושבים שאתה אחד מאבותינו הנביאים שקם לתחייה.“

20”למי אתם חושבים אותי?“ המשיך ישוע לשאול.

”אתה משיח אלוהים!“ ענה פטרוס.

21ישוע ציווה עליהם לא לספר זאת לאיש. 22”על בן־האדם לסבול הרבה“, הוסיף ישוע. ”זקני היהודים, ראשי הכוהנים והסופרים ידחו אותו ואף יהרגו אותו, אולם כעבור שלושה ימים יקום לתחייה!“

23לאחר מכן אמר ישוע לכולם: ”מי שרוצה ללכת בעקבותיי חייב להתכחש לעצמו, לוותר על נוחיותו ושאיפותיו, לשאת עמו את צלבו יום־יום ולבוא אחרי. 24כי מי שחפץ להציל את חייו – יאבד אותם, ואילו מי שיוותר על חייו למעני – יציל אותם. 25מה הרוויח אדם שהשיג את העולם כולו אבל הפסיד חיי־נצח?

26”דעו לכם, שכל מי שמתבייש בי ובדברי, הוא יהיה לבושה לבן־האדם כאשר יבוא בכבודו ובכבוד של אביו עם המלאכים הקדושים. 27אני אומר לכם את האמת: בין העומדים פה עתה יש כאלה שלא ימותו לפני שיראו את מלכות האלוהים!“

28כעבור שמונה ימים לקח איתו ישוע את פטרוס, יוחנן ויעקב ועלה על אחד ההרים כדי להתפלל. 29בזמן שישוע התפלל, פניו השתנו ובגדיו הלבינו והבריקו. 30לפתע הופיעו משה רבנו ואליהו הנביא ודיברו איתו. 31הופעתם הייתה מרשימה ומהודרת, והם דיברו עם ישוע על מותו הקרוב בירושלים, שהיה צפוי לפי דבר ה׳.

32בינתיים שקעו פטרוס והאחרים בשינה עמוקה, וכשהתעוררו ראו את כבודו והדרו של ישוע ואת השנים שעמדו לידו. 33כשעמדו אליהו ומשה ללכת קרא פטרוס, בלי לדעת מה הוא אומר: ”רבי, כמה טוב שאנחנו כאן! מדוע לא נקים כאן שלוש סוכות לכבוד – לך, למשה ולאליהו?“

34בעודו מדבר כיסה אותם ענן והם נמלאו פחד. 35ומן הענן קרא קול: ”זהו בני בחירי, שמעו בקולו.“

36לאחר הקול נראה ישוע עומד לבדו. התלמידים לא סיפרו לאיש את אשר ראו אלא חיכו. 37כשירדו מן ההר למחרת, באו אנשים רבים לקראת ישוע, 38ואחד מהם קרא: ”רבי, אני מתחנן לפניך שתביט בבני היחיד. 39שד אוחז בו, הוא גורם לו לצרוח ללא סיבה, משליך אותו על הרצפה ומתיש את כוחו עד שריר נוזל מפיו. השד הזה מדכא את בני מאוד וכמעט שאינו מניח לו לנפשו. 40התחננתי לפני תלמידיך שיגרשו את השד, אבל הם לא יכלו לעשות זאת.“

41”מה עיקש וחסר־אמונה הדור הזה!“ קרא ישוע. ”עד מתי יהיה עלי לסבול אתכם? הביאו אלי את הילד!“

42לפני שהספיק הילד להגיע אל ישוע, השד הפיל אותו ארצה כאשר הוא מפרכס. אולם ישוע גירש ממנו את השד בגערה, ריפא אותו והשיבו לאביו.

43כשראו הנוכחים את הגילוי הזה של כוח אלוהים, נפלה עליהם יראה גדולה.

בעוד הקהל מתפעל ומחליף רשמים על מעשיו הנפלאים, אמר ישוע לתלמידיו: 44”הקשיבו לדברי בתשומת לב: בן־האדם עומד להימסר לידי אנשים.“ 45אולם התלמידים לא הבינו למה התכוון; דבר־מה מנע מבעדם מלהבין והם חששו לשאול אותו למה התכוון.

46בין התלמידים התעורר ויכוח: מיהו החשוב והגדול ביניהם. 47ישוע ידע את מחשבותיהם ולכן קרא לילד קטן, העמידו לידו 48ואמר לתלמידיו: ”מי שמקבל ילד קטן כזה, כאילו מקבל אותי; ומי שמקבל אותי, מקבל למעשה את אבי אשר שלח אותי. הקטן מביניכם – הצנוע והעניו ביותר – הוא הגדול ביניכם!“

49יוחנן תלמידו פנה אליו ואמר: ”רבי, ראינו איש שמגרש שדים בשמך ואמרנו לו לחדול מכך, כי אין הוא שייך לקבוצתנו.“

50”לא הייתם צריכים לומר לו זאת,“ השיב לו ישוע, ”כי מי שאינו נגדכם הוא בעדכם.“

51בהתקרב המועד שבו יילקח לשמים, התכונן ישוע ללכת לירושלים. 52יום אחד הוא שלח לפניו שליחים, כדי שיכינו לו מקום לינה באחד מכפרי השומרונים. 53אולם השומרונים סרבו לתת להם מקום לינה, משום שפניהם של ישוע ותלמידיו היו מועדות לירושלים (לשומרונים היה ויכוח עם היהודים בנוגע לירושלים).

54כשהגיע הדבר לאוזני ישוע ותלמידיו, שאלו יעקב ויוחנן: ”אתה רוצה שנצווה כי תרד אש מהשמים ותשרוף אותם?“ 55אולם ישוע גער בהם, 56והחבורה המשיכה בדרכה אל כפר אחר.

57בדרך אמר מישהו לישוע: ”אדוני, לאן שתלך, אני אלך אחריך!“ 58אולם ישוע השיב לו: ”אל תשכח שאין לי מקום להניח את ראשי. השועלים מתגוררים במחילות האדמה ולציפורים יש קנים, אולם לבן־האדם אין מקום להניח בו את ראשו.“ 59בהזדמנות אחרת אמר ישוע לאיש מסוים: ”בוא אחרי והיה תלמיד שלי.“ האיש הסכים, אולם ביקש לקבור תחילה את אביו.

60”הנח למתים (מבחינה רוחנית) לקבור את המתים שלהם“, אמר לו ישוע. ”ואילו אתה לך להכריז על מלכות האלוהים.“

61איש אחר אמר לישוע: ”אני אלך אחריך, אדוני, אך הרשה לי תחילה ללכת הביתה ולהיפרד מבני משפחתי.“

62אבל ישוע השיב לו: ”השם את ידו על המחרשה ומביט אחריו לא יהיה כשיר למלכות האלוהים.“