Luku 8 – YCB & CARS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 8:1-56

Òwe afúnrúgbìn kan

18.1-3: Lk 4.15; Mk 15.40-41; Mt 27.55-56; Lk 23.49.Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, 2àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Maria tí a ń pè ní Magdalene, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò. 3Àti Joanna aya Kusa tí í ṣe ìríjú Herodu, àti Susana, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn.

48.4-8: Mt 13.1-9; Mk 4.1-9.Nígbà tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, àwọn ènìyàn láti ìlú gbogbo sì tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, 5“Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀: bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ. 6Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta; bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní omi. 7Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa. 88.8: Mt 11.15.Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọ̀rọ̀ọ̀rún ju èyí ti a gbin lọ.”

Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó pariwo sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”

98.9-10: Mt 13.10-13; Mk 4.10-12; Isa 6.9-10; Jr 5.21; El 12.2.Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?” 10Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí,

“ ‘kí wọn má ba à rí,

àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’

118.11-15: Mt 13.18-23; Mk 4.13-20.8.11: 1Tẹ 2.13; 1Pt 1.23.“Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 12Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là. 13Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn. 14Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó. 15Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.

Àtùpà lórí tábìlì

168.16: Mk 4.21; Mt 5.15; Lk 11.33.“Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àkéte; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀. 178.17: Mk 4.22-23; Mt 10.26-27; Lk 12.2-3; Ef 5.13.Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba. 188.18: Mk 4.24-25; Mt 13.12; 25.29; Lk 19.26.Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin máa kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣe bí òun ní.”

Àwọn ìyá àti arákùnrin Jesu

198.19-21: Mt 12.46-50; Mk 3.31-35.Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn. 20Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn fẹ́ rí ọ.”

218.21: Lk 11.28; Jh 15.14.Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”

Jesu bá rírú omi okun wí

228.22-25: Mt 8.23-27; Mk 4.35-41; 6.47-52; Jh 6.16-21.Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ. 23Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu.

248.24: Lk 5.5; 8.45; 9.33,49; 17.13.Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!”

Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé. 25Ó sì wí fún wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?”

Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?”

Jesu wo ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù sàn

268.26-39: Mt 8.28-34; Mk 5.1-20.Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili. 27Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì. 288.28: Mk 1.24; Jh 2.4.Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 29(Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkígbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì ja gbogbo ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).

30Jesu sì bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”

Ó sì dáhùn pé, “Ligioni,” nítorí ẹ̀mí èṣù púpọ̀ ni ó wa nínú rẹ. 31Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun.

32Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì gba fún wọn. 33Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.

34Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà. 35Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jesu wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n. 36Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá. 37Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gadara yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó si kúrò.

38Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jesu rán an lọ, wí pé, 39“Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.” Ó sì lọ, o sì ń ròyìn ka gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá fún òun tó.

Òkú obìnrin kan àti obìnrin aláìsàn kan

408.40-56: Mt 9.18-26; Mk 5.21-43.Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. 41Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun, 42nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ.

Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè. 43Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, 44Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.

458.45: Lk 8.24.Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?”

Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”

468.46: Lk 5.17; 6.19.Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”

47Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà. 488.48: Mt 9.22; Lk 7.50; 17.19; 18.42.Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá, máa lọ ní Àlàáfíà.”

49Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”

50Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”

51Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà. 52Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”

53Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú. 54Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!” 55Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ. 568.56: Mt 8.4; Mk 3.12; 7.36; Lk 9.21.Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.

Священное Писание

Лука 8:1-56

Женщины следуют за Исой Масихом

1После этого Иса ходил из города в город и из селения в селение, провозглашая Радостную Весть о Царстве Всевышнего. Его сопровождали двенадцать учеников, 2а также несколько женщин, которые были исцелены от злых духов и болезней: Марьям из Магдалы8:2 Марьям из Магдалы – не стоит путать её с грешницей, которая была в доме у Шимона (см. 7:37)., из которой вышли семь демонов, 3Иоханна, жена Хузы, управляющего домом Ирода, Сусанна и многие другие. Эти женщины помогали Исе и Его ученикам из своих средств.

Притча о сеятеле и семенах

(Мат. 13:1-10; Мк. 4:1-9)

4К Исе продолжали приходить люди из разных городов, и когда собралась большая толпа, Он рассказал им притчу:

5– Сеятель вышел сеять семена. И когда он разбрасывал их, то некоторые упали у самой дороги и были затоптаны и склёваны птицами небесными. 6Другие упали на каменистую почву, и, едва взойдя, ростки засохли от недостатка влаги. 7Третьи упали в терновник, и когда тот разросся, то заглушил их. 8Прочие же упали на хорошую почву. Они взошли и принесли урожай во сто раз больше того, что было посеяно.

Рассказав эту притчу, Иса громко сказал:

– У кого есть уши, чтобы слышать, пусть слышит!

Объяснение притчи о сеятеле и семенах

(Мат. 13:10-23; Мк. 4:10-20)

9И когда ученики спросили, что означает эта притча, 10Иса ответил:

– Вам дано знать тайны Царства Всевышнего, другим же всё остаётся в притчах, чтобы

«они, смотря, не видели

и, слушая, не понимали»8:10 Ис. 6:9..

11– Вот значение этой притчи: семя – это слово Всевышнего. 12Семена, упавшие у дороги, – это те, кто слышит слово, но потом приходит дьявол и похищает слово из их сердец, чтобы они не поверили и не были спасены8:12 Спасены – от пламени ада (см. Иуда 1:23), от гнева Всевышнего и Его судов (см. Рим. 5:9), от суетной жизни (см. 1 Пет. 1:18), от греха (см. Мат. 1:21) и от дьявола (см. 2 Тим. 2:26).. 13Семена, упавшие на камень, – это те, кто с радостью принимает слово, когда слышит его. Но у них нет корня – сначала они верят, но когда приходят времена испытаний, они отступаются. 14Семена, упавшие в терновник, – это те люди, которые слышат слово, но со временем повседневные заботы, богатство и удовольствия заглушают их, и плод их не дозревает. 15Семена же, упавшие на хорошую почву, – это люди, которые, слыша слово, хранят его в добром и честном сердце и приносят плод благодаря своей стойкости.

Ответственность слушающих

(Мк. 4:21-25)

16– Никто, зажёгши светильник, не ставит его под сосуд или под кровать, наоборот, его ставят на подставку, чтобы все входящие видели свет. 17Нет ничего тайного, что не стало бы явным, и нет ничего сокрытого, что не стало бы известным и не вышло на свет. 18Итак, будьте внимательны к тому, как вы слушаете, потому что у кого есть, тому будет дано ещё, а у кого нет, будет отнято и то, что, как ему кажется, он имеет.

Иса Масих говорит о Своей истинной семье

(Мат. 12:46-50; Мк. 3:31-35)

19К Исе пришли Его мать и братья, но из-за толпы не могли подойти к Нему. 20Ему передали:

– Твои мать и братья стоят снаружи и хотят Тебя видеть.

21Но Иса ответил им:

– Мои мать и братья – это те, кто слушает слово Всевышнего и исполняет его.

Усмирение шторма

(Мат. 8:23-27; Мк. 4:36-41)

22Однажды Иса сказал Своим ученикам:

– Переправимся на другую сторону озера.

Они сели в лодку и отправились. 23Пока они плыли, Иса заснул. Внезапно на озере начался шторм, и лодку стало заливать, так что они оказались в опасности. 24Ученики, подойдя, разбудили Ису, говоря:

– Наставник, Наставник, мы гибнем!

Проснувшись, Он запретил ветру и бушующим волнам. Они утихли, и наступил штиль.

25– Где же ваша вера? – сказал Он ученикам. Они же, испуганные и удивлённые, лишь спрашивали друг друга:

– Кто Он, что даже ветрам и воде приказывает, и они повинуются Ему?

Изгнание демонов в стадо свиней

(Мат. 8:28-34; Мк. 5:1-17)

26Они приплыли в Гадаринскую землю, что напротив Галилеи. 27Когда Иса сошёл на берег, Ему навстречу вышел человек из города, одержимый демонами. На нём уже давно не было одежды, и жил он не в доме, а в могильных пещерах. 28Когда он увидел Ису, он бросился к Его ногам и закричал во весь голос:

– Что Ты от меня хочешь, Иса, Сын Бога Высочайшего (Царственный Спаситель)? Умоляю Тебя, не мучь меня! – 29потому что Иса приказал нечистому духу выйти из этого человека. (Демон часто овладевал этим человеком, и тогда, даже если его сковывали по рукам и ногам и стерегли, он разрывал цепи, и демон гнал его в безлюдные места.) 30Иса спросил его:

– Как тебя зовут?

– Полчище8:30 Букв.: «легион» – воинское соединение в римской армии, состоящее примерно из 6 000 человек., – ответил тот, потому что в него вошло много демонов. 31И они стали умолять Ису не отсылать их в бездну. 32Неподалёку на склоне горы в это время паслось большое стадо свиней, и демоны попросили Ису позволить им войти в них. Он позволил. 33Когда демоны вышли из этого человека и вошли в свиней, всё стадо бросилось с обрыва в озеро и утонуло. 34Свинопасы, увидев, что произошло, побежали и рассказали обо всём в городе и в окрестностях. 35Тогда люди сошлись, чтобы посмотреть, что же случилось. Подойдя к Исе, они обнаружили, что человек, из которого были изгнаны демоны, сидит у ног Исы одетый и в здравом уме, и их охватил страх. 36Очевидцы рассказали им о том, как был исцелён одержимый. 37Тогда все жители страны Герасинской стали упрашивать Ису покинуть их края, потому что сильно испугались. Иса сел в лодку и возвратился туда, откуда приплыл. 38Человек, из которого вышли демоны, просил взять его с Собой, но Иса отослал его, сказав:

39– Возвращайся домой и расскажи, что сделал для тебя Всевышний.

Тот пошёл, рассказывая по всему городу о том, что сделал для него Иса.

Господство Исы Масиха над болезнью и смертью

(Мат. 9:18-26; Мк. 5:22-43)

40Когда Иса возвратился, Его приветствовала большая толпа, потому что все ждали Его. 41К Нему подошёл человек по имени Иаир, который был начальником молитвенного дома иудеев, и, павши к Его ногам, стал просить Ису прийти к нему домой: 42его единственная дочь, которой было около двенадцати лет, умирала. Иса пошёл туда в окружении плотной толпы.

43В толпе была женщина, двенадцать лет страдавшая кровотечением; она истратила на врачей все свои средства, но никто не мог её вылечить. 44Она подошла сзади к Исе и прикоснулась к кисточке на краю Его одежды8:44 К краям верхней мужской одежды иудеи пришивали кисточки, в которые обязательно вплетались голубые нити. Эти кисточки должны были напоминать иудеям о необходимости исполнять повеления Всевышнего (см. Чис. 15:38-40; Втор. 22:12).. Кровотечение сразу же остановилось.

45– Кто ко Мне прикоснулся? – спросил Иса.

Никто не признавался, и Петир сказал:

– Наставник, вокруг Тебя толпятся люди и напирают со всех сторон.

46Но Иса сказал:

– Кто-то ко Мне прикоснулся. Я почувствовал, как из Меня вышла сила.

47Тогда женщина, видя, что она не осталась незамеченной, подошла, дрожа, и пала к Его ногам. Перед всем народом она рассказала, почему она к Нему прикоснулась и как сразу же была исцелена. 48Тогда Иса сказал ей:

– Дочь Моя, твоя вера исцелила тебя. Иди с миром.

49Пока Иса ещё говорил, пришёл человек из дома Иаира, начальника молитвенного дома.

– Твоя дочь умерла, – сказал он, – не беспокой больше Учителя.

50Услышав это, Иса сказал Иаиру:

– Не бойся, только верь, и девочка будет спасена.

51Когда Он вошёл в дом, то не позволил никому войти с Ним, кроме Петира, Иохана, Якуба и родителей девочки. 52Люди во дворе уже плакали и рыдали по ней.

– Перестаньте плакать, – сказал Иса, – ведь она не умерла, а спит.

53Они стали смеяться над Ним, потому что знали, что девочка умерла. 54Иса же взял её за руку и сказал:

– Дитя, встань!

55Дух девочки возвратился к ней, и она сразу же встала. Иса сказал, чтобы ей дали есть. 56Родители были поражены, но Иса наказал им никому не рассказывать о том, что произошло.