Luku 7 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 7:1-50

Ìgbàgbọ́ ọ̀gágun Romu kan

17.1-10: Mt 8.5-10,13; Jh 4.46-53.Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ. 2Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. 3Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá. 4Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún. 57.5: Ap 10.2.Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” 6Jesu sì ń bá wọn lọ.

Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi. 7Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. 8Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

9Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.” 10Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.

Jesu jí òkú ọmọ opó kan dìde

117.11-17: Mk 5.21-24,35-43; Jh 11.1-44; 1Ọb 17.17-24; 2Ọb 4.32-37.Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn. 12Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 137.13: Lk 7.19; 10.1; 11.39; 12.42; 13.15; 17.5-6; 18.6; 19.8; 22.61; 24.3.Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”

14Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!” 15Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.

167.16: Lk 7.39; 24.19; Mt 21.11; Jh 6.14.Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!” 17Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

Jesu àti Johanu onítẹ̀bọmi

187.18-35: Mt 11.2-19.Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un. 19Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

20Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”

217.21: Mt 4.23; Mk 3.10.Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú. 227.22: Isa 29.18-19; 35.5-6; 61.1; Lk 4.18-19.Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìyìnrere. 23Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”

24Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì? 25Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba! 26Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ! 277.27: Ml 3.1; Mk 1.2.Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:

“ ‘Wò ó, èmi yóò rán oníṣẹ́ mi síwájú rẹ;

ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

28Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọ̀ ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀jù ú lọ.”

297.29-30: Mt 21.32; Lk 3.12.(Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi. 30Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)

31Jesu sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ? 32Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé,

“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,

ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,

ẹ̀yin kò sọkún!’

337.33: Lk 1.15.Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’ 347.34: Lk 5.29; 15.1-2; 7.36-50.Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’ 35Ṣùgbọ́n ọgbọ́n ni a dá láre nípasẹ̀ ọmọ rẹ.”

A da òróró sí Jesu lára nípasẹ̀ obìnrin ẹlẹ́ṣẹ̀

367.36-50: Mt 26.6-13; Mk 14.3-9; Jh 12.1-8.7.36: Lk 11.37; 14.1.Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun. 37Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá, 38Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.

397.39: Lk 7.16; 24.19; Mt 21.11; Jh 6.14.Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

40Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”

Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”

41“Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta. 427.42: Mt 18.25.Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”

437.43: Lk 10.28.Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.”

Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.”

44Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù. 45Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀. 46Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀. 47Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”

487.48: Mt 9.2; Mk 2.5; Lk 5.20.Ó sì wí fún un pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!”

49Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?”

507.50: Mt 9.22; Mk 5.34; Lk 8.48.Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là, máa lọ ní àlàáfíà.”

New Russian Translation

Луки 7:1-50

Вера римского воина

(Мат. 8:5-13)

1Закончив говорить народу, Иисус отправился в Капернаум. 2Там у одного сотника был болен и лежал при смерти слуга. Сотник очень дорожил этим своим слугой, 3и когда он услышал об Иисусе, то послал к Нему иудейских старейшин с просьбой прийти и исцелить его слугу. 4Старейшины пришли к Иисусу и стали горячо просить Его:

– Этот человек заслуживает Твоей помощи, 5потому что он любит наш народ, и это он построил нам синагогу.

6Иисус пошел с ними. Он уже подходил к дому, когда сотник послал к Нему друзей передать:

– Господи, не утруждай Себя, так как я не достоин, чтобы Ты вошел под крышу моего дома. 7Я и себя не счел достойным прийти к Тебе. Но скажи лишь слово, и мой слуга выздоровеет. 8Ведь и сам я подчиняюсь приказам, и у меня в подчинении тоже есть воины. Я говорю одному: «Ступай!» – и он идет, другому: «Ко мне!» – и тот приходит. Слуге моему говорю: «Сделай это!» – и он делает. 9Иисус, услышав это, удивился и, обернувшись к толпе, шедшей за Ним, сказал:

– Говорю вам, что даже в Израиле Я не встречал такой сильной веры.

10Когда посланные возвратились в дом, они нашли слугу здоровым.

Иисус воскрешает сына вдовы

11Вскоре после этого Иисус пошел в город, называемый Наин, с Ним были Его ученики и много других людей. 12Когда Он подходил к воротам города, из них выносили умершего, единственного сына у матери, а она была вдовой. Вместе с ней из города выходила большая толпа. 13Когда Господь увидел эту женщину, Он сжалился над ней.

– Не плачь, – сказал Он ей.

14Затем Он подошел и прикоснулся к носилкам. Те, кто нес их, остановились, и Иисус сказал:

– Юноша, говорю тебе: встань!

15Умерший сел и начал говорить, и Иисус передал его матери. 16Всех, кто там был, охватил страх, и люди прославляли Бога:

– Великий пророк появился среди нас! Бог посетил Свой народ!

17И молва об Иисусе распространилась по всей Иудее и в окружающих ее землях.

Иисус разрешает сомнения Иоанна

(Мат. 11:2-6)

18Ученики Иоанна рассказали ему обо всех этих событиях. И тогда Иоанн позвал к себе двоих из них 19и послал их к Господу спросить:

– Ты ли Тот, Кто должен прийти, или нам ожидать кого-то другого?

20Они пришли к Иисусу и сказали:

– Иоанн Креститель послал нас к Тебе спросить: Ты ли Тот, Кто должен прийти, или нам ожидать кого-то другого?

21Иисус как раз в это время исцелил множество людей от болезней, недугов, от одержимости злыми духами и многим слепым даровал зрение. 22И Он ответил посланным:

– Пойдите и расскажите Иоанну о том, что вы увидели и услышали: слепые прозревают, хромые ходят, прокаженные очищаются, глухие слышат, мертвые воскресают и бедным возвещается Радостная Весть7:22 См. Ис. 29:18; 35:5-6; 61:1.. 23Блажен тот, кто не усомнится во Мне.

Свидетельство Иисуса об Иоанне Крестителе

(Мат. 11:7-19)

24Когда посланцы Иоанна ушли, Иисус начал говорить народу об Иоанне:

– Что вы ходили смотреть в пустыню? Тростник, колеблемый ветром? 25Тогда что же вы ходили смотреть? Человека, одетого в роскошные одежды? Нет, те, кто одевается в дорогую одежду и живет в роскоши, находятся в царских дворцах. 26Тогда что же вы ходили смотреть? Пророка? Да, и говорю вам, что больше, чем пророка. 27Он тот, о ком написано:

«Вот, Я посылаю перед Тобой Моего вестника,

который приготовит перед Тобой Твой путь»7:27 Мал. 3:1..

28Говорю вам, среди всех рожденных женщинами нет более великого, чем Иоанн. Но наименьший в Божьем Царстве – больше его.

29(И весь народ, и даже сборщики налогов, услышав слова Иисуса, признали Божий путь правым, потому что они приняли крещение Иоанна. 30Фарисеи же и учители Закона, отказавшись принять крещение от него, отвергли Божью волю.)

31– С кем тогда Мне сравнить людей этого поколения? – продолжал Иисус. – На кого они похожи? 32Они как дети, которые сидят на площади и кричат друг другу:

«Мы играли вам на свирели,

а вы не плясали;

мы пели вам похоронные песни,

а вы не плакали».

33Смотрите, вот пришел Иоанн Креститель, не ест хлеба и не пьет вина, и вы говорите: «В нем демон». 34Пришел Сын Человеческий, ест и пьет, и вы говорите: «Вот обжора и пьяница, друг сборщиков налогов и грешников». 35Но мудрость оправдана всеми детьми ее7:35 Существует несколько вариантов толкования этого места, например: 1) правота мудрости видна в жизни тех, кто следует ей; 2) но истинная мудрость не противоречит сама себе. Кроме того, некоторые толкователи полагают, что мудростью здесь назван Сам Иисус (ср.: Прит. 8:22-23; 1 Кор. 1:24)..

Помазание Иисуса дорогим ароматическим маслом

(Мат. 26:6-13; Мк. 14:3-9; Ин. 12:1-8)

36Один из фарисеев пригласил Иисуса к себе на обед. Иисус пришел к нему в дом и возлег у стола. 37В это время одна женщина из этого города, которая была известна как грешница, узнав, что Иисус обедает в доме фарисея, принесла туда алебастровый кувшин, в котором было очень дорогое ароматическое масло. 38Женщина встала сзади у ног Иисуса и, плача, обливала Его ноги слезами. Она стала вытирать Ему ноги своими волосами, целовала их и натирала ароматическим маслом. 39Когда фарисей, пригласивший Иисуса, увидел это, он подумал: «Если бы Этот Человек действительно был пророком, то Он бы знал, что женщина, которая к Нему прикасается, – грешница». 40Тогда Иисус сказал ему:

– Симон, Я хочу тебе что-то сказать.

– Говори, Учитель, – ответил тот.

41– Два человека были должны одному и тому же заимодавцу, – начал Иисус. – Один должен был пятьсот динариев, а другой – пятьдесят. 42И тому, и другому было нечем вернуть долг, и кредитор простил долг им обоим. Кто из них, по-твоему, будет больше любить его?

43Симон ответил:

– Я думаю, тот, кому был прощен больший долг.

– Ты правильно рассудил, – сказал Иисус. 44И, повернувшись к женщине, сказал Симону:

– Ты видишь эту женщину? Я пришел в твой дом, и ты не дал Мне даже воды, чтобы вымыть ноги, а она омыла Мои ноги слезами и вытерла своими волосами! 45Ты даже не поцеловал Меня при встрече, а эта женщина, с тех пор как Я вошел в дом, не перестает целовать Мне ноги. 46Ты не помазал Мне голову маслом, а она драгоценным ароматическим маслом помазала Мне ноги. 47Поэтому Я говорю тебе: ей прощены все грехи, из-за этого она и возлюбила так сильно. А тот, кому мало прощено, и любит мало.

48Потом Иисус сказал женщине:

– Твои грехи прощены.

49Но другие гости, возлежащие за столом, начали переговариваться:

– Кто Он такой, что даже грехи прощает?

50Иисус же сказал женщине:

– Твоя вера спасла тебя, иди с миром.