Luku 3 – YCB & HTB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 3:1-38

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe

13.1: Lk 23.1; 9.7; 13.31; 23.7.Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene, 23.2: Jh 18.13; Ap 4.6; Mt 26.3; Jh 11.49.tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù. 33.3-9: Mt 3.1-10; Mk 1.1-5; Jh 1.6,23.Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, 43.4-6: Isa 40.3-5.bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé,

“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,

‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,

ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

5Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún,

gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ.

Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,

àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.

63.6: Lk 2.30.Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

73.7: Mt 12.34; 23.33.Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 83.8: Jh 8.33,39.Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 93.9: Mt 7.19; Hb 6.7-8.Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”

10Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”

11Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

12Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”

13Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”

14Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”

153.15: Ap 13.25; Jh 1.19-22.Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 163.16-18: Mt 3.11-12; Mk 1.7-8; Jh 1.26-27,33; Ap 1.5; 11.16; 19.4.Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú, Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. 17Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” 18Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìyìnrere fún wọn.

193.19-20: Mt 14.3-4; Mk 6.17-18.Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe, 20Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígbà tí ó fi Johanu sínú túbú.

Ìtẹ̀bọmi àti ìtàn ìdílé Jesu

213.21-22: Mt 3.13-17; Mk 1.9-11; Jh 1.29-34.3.21: Lk 5.16; 6.12; 9.18,28; 11.1; Mk 1.35.Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, 223.22: Sm 2.7; Isa 42.1; Lk 9.35; Ap 10.38; 2Pt 1.17.Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

233.23-38: Mt 1.1-17; Gẹ 5.3-32; 11.10-26; Ru 4.18-22; 1Ki 1.1-4,24-28; 2.1-15.3.23: Jh 8.57; Lk 1.27.Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,

tí í ṣe ọmọ Eli, 24tí í ṣe ọmọ Mattati,

tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki,

tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

25tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi,

tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili,

tí í ṣe ọmọ Nagai, 26tí í ṣe ọmọ Maati,

tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei,

tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,

27tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa,

tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli,

tí í ṣe ọmọ Neri, 28tí í ṣe ọmọ Meliki,

tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu,

tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,

29tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri,

tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati,

tí í ṣe ọmọ Lefi, 30tí í ṣe ọmọ Simeoni,

tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,

31tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna,

tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani,

tí í ṣe ọmọ Dafidi, 32tí í ṣe ọmọ Jese,

tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi,

tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,

33tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu,

tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi,

tí í ṣe ọmọ Juda. 34Tí í ṣe ọmọ Jakọbu,

tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu,

tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,

35tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu,

tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi,

tí í ṣe ọmọ Ṣela. 36Tí í ṣe ọmọ Kainani,

tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu,

tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,

37tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku,

tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli,

tí í ṣe ọmọ Kainani. 38Tí í ṣe ọmọ Enosi,

tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu,

tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.

Het Boek

Lucas 3:1-38

1In het vijftiende regeringsjaar van keizer Tiberius, toen Pontius Pilatus landvoogd was van Judea, Herodes viervorst van Galilea, zijn broer Filippus viervorst van Iturea en het gewest Trachonitis, en Lusánias viervorst van Abilene. 2onder den hogepriester Annas en Káifas, kwam Gods woord tot Johannes, den zoon van Zakarias, in de woestijn. 3Toen trad hij op in heel de omtrek van de Jordaan, en preekte een doopsel van boetvaardigheid tot vergiffenis der zonden; 4zoals geschreven staat in het boek der voorspellingen van den profeet Isaias: De stem van een roepende in de woestijn. Bereidt de weg des Heren, Maakt recht zijn paden. 5Elk ravijn zal worden gedempt, Iedere berg en heuvel worden geslecht; De kronkelpaden zullen recht, De oneffene wegen effen worden. 6En alle vlees zal zien Gods heil. 7Hij sprak dus tot de scharen, die uitliepen, om door hem te worden gedoopt: Adderenbroed, wie heeft u geleerd, de komende wraak te ontvluchten? 8Brengt dus waardige vruchten van boetvaardigheid voort: en gaat niet zeggen bij uzelf: We hebben Abraham tot vader. Want ik zeg u, dat God de macht heeft, om uit deze stenen voor Abraham kinderen te verwekken. 9Reeds ligt de bijl aan de wortel der bomen. Iedere boom, die geen goede vruchten draagt, wordt omgehouwen, en in het vuur geworpen. 10Het volk ondervroeg hem en sprak: Wat moeten we doen? 11Hij gaf hun ten antwoord: Wie twee paar kleren heeft, moet delen met hem, die er geen heeft; en wie te eten heeft, moet hetzelfde doen. 12Ook tollenaars kwamen ten doop, en zeiden hem: Meester, wat moeten wij doen? 13Hij zei hun: Vordert niet meer, dan wat is vastgesteld. 14Ook soldaten ondervroegen hem, en zeiden: En wij, wat moeten wij doen? Hij zei hun: Doet niemand overlast aan, maakt u niet aan afpersing schuldig, en weest tevreden met uw soldij. 15Maar toen het volk in spanning kwam, en allen zich begonnen af te vragen, of Johannes misschien de Christus kon zijn. 16verklaarde Johannes aan allen: Ik voor mij doop u met water, maar er komt er Een, die machtiger is dan ik: ik ben niet waardig, zijn schoenriem los te maken. Hij zal u dopen met den Heiligen Geest en met vuur. 17Hij heeft zijn wan in de hand, en Hij zal zijn dorsvloer zuiveren: de tarwe verzamelen in zijn schuur, maar het kaf verbranden in onuitblusbaar vuur. 18Zo bracht hij, met nog veel andere vermaningen, de blijde boodschap aan het volk. 19Maar toen de viervorst Herodes door hem werd berispt naar aanleiding van Heródias, de vrouw van zijn broer, en over al de misdaden die hij had bedreven, 20voegde Herodes nog dit er aan toe, dat hij Johannes in de kerker sloot. 21Toen nu al het volk zich liet dopen, en ook Jesus gedoopt was, ging eensklaps, terwijl Hij aan het bidden was, de hemel open, 22en daalde de Heilige Geest in lichamelijke gedaante als een duif op Hem neer. En er klonk een stem uit de hemel: Gij zijt mijn welbeminde Zoon; in U heb Ik welbehagen. 23Toen Jesus optrad, was Hij ongeveer dertig jaar oud. Hij was, naar men meende, de zoon van Josef, den zoon van Eli, 24zoon van Mattat, zoon van Levi, zoon van Melki, zoon van Jannai, zoon van Josef, 25zoon van Mattatias, zoon van Amos, zoon van Naóem, zoon van Esli, zoon van Naggai, 26zoon van Maät, zoon van Mattatias, zoon van Semëín, zoon van Josef, zoon van Juda, 27zoon van Jóannan, zoon van Resa, zoon van Zoróbabel, zoon van Salátiël, zoon van Neri, 28zoon van Melki, zoon van Addi, zoon van Kosam, zoon van Elmadám, zoon van Er, 29zoon van Jesus, zoon van Eliëzer, zoon van Joram, zoon van Mattat, zoon van Levi, 30zoon van Simeon, zoon van Juda, zoon van Josef, zoon van Jonam, zoon van Eljakim, 31zoon van Mélea, zoon van Menna, zoon van Máttata, zoon van Natan, zoon van David, 32zoon van Jesse, zoon van Obed, zoon van Boöz, zoon van Salmon, zoon van Naässon, 33zoon van Ammínadab, zoon van Admin, zoon van Arni, zoon van Esron, zoon van Fares, zoon van Juda, 34zoon van Jakob, zoon van Isaäk, zoon van Abraham, zoon van Tara, zoon van Nachor, 35zoon van Seróeg, zoon van Ragaóe, zoon van Paleg, zoon van Eber, zoon van Sala, 36zoon van Kaïnán, zoon van Arpaksád, zoon van Sem, zoon van Noë, zoon van Lamek, 37zoon van Matóesala, zoon van Henok, zoon van Jared, zoon van Maláleël, zoon van Kaïnán, 38zoon van Enos, zoon van Set, zoon van Adam, zoon van God.