Luku 11 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 11:1-54

Jesu ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àdúrà

111.1: Mk 1.35; Lk 3.21; 5.16; 6.12; 9.18,28; 5.33; 7.18.Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

211.2-4: Mt 6.9-13.Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé:

“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,

kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín.

Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe,

bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.

3Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.

411.4: Mk 11.25; Mt 18.35.Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá;

nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè,

Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ”

511.5-8: Lk 18.1-8.Ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrín ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta. 6Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’ 7Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu, a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!’ 8Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fi fún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánnu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un tó bí ó ti ń fẹ́.

911.9-13: Mt 7.7-11.11.9: Mt 18.19; 21.22; Mk 11.24; Jk 1.5-8; 1Jh 5.14-15; Jh 15.7; 16.23-24.“Èmí sì wí fún yín, ẹ béèrè, a ó sì fi fún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. 10Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè, ó rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, ó rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.

11“Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò béèrè àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò fún un ní ejò? 12Tàbí bí ó sì béèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekèe? 13Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”

Jesu àti Beelsebulu

1411.14-23: Mt 12.22-30; 10.25; Mk 3.23-27.11.14-15: Mt 9.32-34.Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn. 15Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” 1611.16: Mt 12.38; 16.1; Mk 8.11; Jh 2.18; 6.30.Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.

17Ṣùgbọ́n òun mọ èrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di ahoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó. 18Bí Satani ba yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. 19Bí ó ba ṣe pé nípa Beelsebulu ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, nípa ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídàájọ́ yín. 20Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé nípa ìka ọwọ́ Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.

21“Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ni ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà. 22Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.

2311.23: Lk 9.50.“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì bá mi kójọpọ̀, ó fọ́nká.

2411.24-26: Mt 12.43-45.“Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi; nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, ‘Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá.’ 25Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 26Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkára rẹ̀ lọ wá, wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀, ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”

2711.27: Lk 1.42; 23.29.Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan gbóhùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”

28Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”

Àmì ti Jona

2911.29-32: Mt 12.39-42.11.29: Mt 16.4; Mk 8.12; Lk 11.16; Jn 3.4-5.Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí, wọ́n ń wá àmì; a kì yóò sì fi àmì kan fún un bí kò ṣe àmì Jona wòlíì! 30Nítorí bí Jona ti jẹ́ àmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò ṣe jẹ́ àmì fún ìran yìí. 3111.31: 1Ọb 10.1-10; 2Ki 9.1-12.Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí. 3211.32: Mt 12.6.Àwọn ará Ninefe yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona; sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Jona lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.

Òwe nípa fìtílà tí a tàn

3311.33: Mt 5.15; Mk 4.21; Lk 8.16.“Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òsùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé ba à lè máa rí ìmọ́lẹ̀. 3411.34-35: Mt 6.22-23.Ojú ni fìtílà ara: bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn. 35Nítorí náà kíyèsi i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn. 36Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apá kan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

Ègún mẹ́fà

3711.37: Lk 7.36; 14.1.Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun. 3811.38: Mk 7.1-5.Nígbà tí Farisi náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun.

3911.39-41: Mt 23.25-26.11.39: Lk 7.13.Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ. 40Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú? 4111.41: Tt 1.15; Mk 7.19.Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.

4211.42: Mt 23.23-24; Le 27.30; Mt 6.8.“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.

4311.43: Mt 23.6-7; Mk 12.38-39; Lk 20.46.“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà.

4411.44: Mt 23.27.“Ègbé ni fún un yín, 11.44 ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”

45Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.”

4611.46: Mt 23.4.Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà.

4711.47-48: Mt 23.29-32; Ap 7.51-53.“Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa. 48Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn. 4911.49-51: Mt 23.34-36.11.49: 1Kọ 1.24; 1Kọ 2.3.Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’ 50Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí; 5111.51: Gẹ 4.8; 2Ki 24.20-21; Sk 1.1.láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.

5211.52: Mt 23.13.“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.”

53Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀. 54Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú lẹ́nu kí wọn bá à lè fi ẹ̀sùn kàn án.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

路加福音 11:1-54

教導門徒禱告

1有一天,耶穌在某地禱告完畢,有個門徒對祂說:「主啊,請教導我們禱告,像約翰教他的門徒一樣。」

2耶穌對他們說:「你們應該這樣禱告,

『天父,願人都尊崇你的聖名,

願你的國度降臨,

願你的旨意在地上成就,

就像在天上成就一樣11·2 有古卷無「願你的旨意在地上成就,就像在天上成就一樣」。

3願你天天賜給我們日用的飲食。

4求你饒恕我們的罪,

因為我們也饒恕那些虧欠我們的人。

不要讓我們遇見誘惑,

拯救我們脫離那惡者11·4 有古卷無「拯救我們脫離那惡者」。。』」

5耶穌又對他們說:「假設你在半夜跑去朋友家請求說,『朋友,請借給我三個餅吧, 6因為有一位朋友遠道而來,我家沒有什麼可以招待他。』 7那個人在屋裡應聲說,『請別打攪我,門已經鎖上了,我和孩子們也已經上床了,我不能起來給你拿餅。』

8「我告訴你們,那人雖不念朋友之情,但是倘若你不肯甘休,繼續請求,他最終會起來滿足你的願望。

9「我告訴你們,祈求,就會給你們;尋找,就會尋見;叩門,就會給你們開門。 10因為凡祈求的,就得到;尋找的,就尋見;叩門的,就給他開門。

11「你們中間做父親的,如果孩子要餅,你會給他石頭嗎?11·11 有古卷無「如果孩子要餅,你會給他石頭嗎?」要魚,你會給他蛇嗎? 12要雞蛋,你會給他蠍子嗎? 13你們雖然邪惡,尚且知道把好東西給兒女,天父豈不更要賜聖靈給那些求祂的人嗎?」

耶穌和別西卜

14有一次,耶穌趕出一個使人啞巴的鬼。鬼一出去,啞巴就能說話了,大家都很驚奇。 15有人卻說:「祂是靠鬼王別西卜趕鬼。」 16還有些人想試探耶穌,要求祂行個神蹟證明自己是上帝派來的。

17耶穌知道他們的心思,就說:「一個國內部自相紛爭,必然滅亡;一個家內部自相紛爭,必然崩潰。 18同樣,若撒旦內部自相紛爭,牠的國怎能維持呢?你們說我是靠別西卜趕鬼, 19若我是靠別西卜趕鬼,你們的子弟又是靠誰趕鬼呢?因此,他們要審判你們。 20但若我是靠上帝的能力趕鬼,就是上帝的國已降臨在你們中間了。

21「壯漢全副武裝地看守自己的住宅,他的財物會很安全。 22但是,來了一個比他更強壯的人,把他制伏後,奪去他所依靠的武裝,並把他搶來的東西分給了人。 23誰不與我為友,就是與我為敵;誰不和我一起收聚,就是故意拆散。

24「有個污鬼離開了牠以前所附的人,在乾旱無水之地四處遊蕩,尋找安歇之處,卻沒有找到。於是牠說,『我要回到老地方。』 25牠回去後,看見裡面打掃得又乾淨又整齊, 26就去帶來了七個比自己更邪惡的鬼一起住在那裡。那人的下場比從前更慘了。」

誰更有福

27耶穌說話的時候,人群中有個婦人高喊:「生你養你的人真有福啊!」

28耶穌回答說:「但那聽了上帝的話又去遵行的人更有福。」

可悲的邪惡世代

29這時聚集的人越來越多,耶穌說:「這是一個邪惡的世代,人們只想看神蹟,但除了約拿的神蹟以外,再沒有神蹟給他們看。 30正如約拿成了尼尼微人的神蹟,人子也要成為這世代的神蹟。

31「在審判的日子,南方的女王和這世代的人都要起來11·31 起來」或作「復活」,下同32節。,她要定這個世代的罪,因為她曾不遠千里來聽所羅門王的智言慧語。看啊!這裡有一位比所羅門王更偉大。

32「在審判的日子,尼尼微人和這世代的人都要起來,尼尼微人要定這個世代的罪,因為他們聽到約拿的宣告,就悔改了。看啊!這裡有一位比約拿更偉大。

燈的比喻

33「沒有人點了燈卻將它放在地窖裡或斗底下,人總是把燈放在燈臺上,讓進來的人可以看見光。 34你的眼睛就是身體的燈,你的眼睛明亮,全身就光明;你的眼睛昏花,全身就黑暗。 35因此要小心,不要讓你心裡的光變為黑暗。 36如果你全身光明、毫無黑暗,你整個人就熠熠生輝,好像有燈光照在你身上。」

譴責法利賽人

37耶穌說完這番話後,有一個法利賽人來請祂吃飯,祂便應邀入席。 38這位法利賽人看見耶穌飯前沒有行猶太人洗手的禮儀,十分詫異。 39主對他說:「你們法利賽人洗淨杯盤的外面,你們裡面卻充滿了貪婪和邪惡。 40愚蠢的人啊,人裡外不都是上帝所創造的嗎? 41只要你們發自內心地去施捨,一切對你們都是潔淨的。

42「法利賽人啊,你們有禍了!你們將薄荷、茴香、各樣蔬菜獻上十分之一,卻忽略了上帝的公義和仁愛。後者是你們本該做的,前者也不可忽略。

43「法利賽人啊,你們有禍了!你們喜歡在會堂裡坐首位,又喜歡在街市上聽到別人的問候。 44你們有禍了!因為你們就像沒有墓碑的墳墓,人們從上面走過也不知道。」

譴責律法教師

45一位律法教師對耶穌說:「老師,你這話把我們也侮辱了!」

46耶穌回答說:「你們這些律法教師也有禍了!你們把沉重難負的擔子放在別人肩上,自己卻連一根指頭也不肯動。

47「你們有禍了,你們為先知修造墳墓,而他們正是被你們祖先殺害的! 48所以你們是見證人,你們讚同祖先的行為,因為他們殺了先知,你們為先知造墳墓。 49因此,充滿智慧的上帝說,『我要差遣先知和使徒到他們那裡,有些要被殺害,有些要遭迫害』, 50-51使創世以來,自亞伯一直到在祭壇和聖所之間被殺的撒迦利亞等眾先知的血債,都由這個世代承擔。我實在告訴你們,這些罪責都要由這個世代承擔。

52「律法教師啊,你們有禍了!你們拿走了知識的鑰匙,自己不進去,還阻擋那些正要進去的人。」

53耶穌離開那裡後,法利賽人和律法教師開始激烈地反對祂,用各種問題刁難祂, 54伺機找把柄陷害祂。