Luku 10 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 10:1-42

Jesu rán méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde

110.1: Lk 9.1-2,51-52; 7.13.Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan méjìléláàádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. 210.2: Mt 9.37-38; Jh 4.35.Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. 310.3-12: Mt 10.7-16; Mk 6.8-11; Lk 9.2-5; 22.35-36.Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. 4Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.

510.5: 1Sa 25.6.“Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ 6Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. 710.7: 1Kọ 10.27; 9.14; 1Tm 5.18; De 24.15.Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín, nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.

8“Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín. 9Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ 10Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, 1110.11: Ap 13.51.‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ 1210.12: Mt 11.24; Gẹ 19.24-28; Jd 7.Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.

1310.13-15: Mt 11.21-23; Lk 6.24-26.“Ègbé ni fún ìwọ, Korasini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. 14Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. 15Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.

1610.16: Mt 10.40; 18.5; Mk 9.37; Lk 9.48; Jh 13.20; 12.48.“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

17Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

1810.18: If 12.9; Jh 12.31.Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá, kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 2010.20: Ek 32.32; Sm 69.28; Da 12.1; Fp 4.3; Hb 12.23; If 3.5; 13.8; 21.27.Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”

2110.21-22: Mt 11.25-27.10.21: 1Kọ 1.26-29.Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.

2210.22: Mt 28.18; Jh 3.35; 13.3; 10.15; 17.25.“Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba, àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”

2310.23-24: Mt 13.16-17; Jh 8.56; Hb 11.13; 1Pt 1.10-12.Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. 24Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

Òwe aláàánú ará Samaria

2510.25-28: Mt 22.34-39; Mk 12.28-31.10.25: Mk 10.17; Mt 19.16; Lk 18.18.Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?”

2710.27: De 6.5; Le 19.18; Ro 13.9; Ga 5.14; Jk 2.8.Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

2810.28: Lk 20.39; Le 18.25.Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

29Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

30Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. 31Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì. 32Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì. 3310.33: Lk 9.51-56; 17.11-19; Jh 4.4-42.Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. 34Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 35Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’

36“Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”

Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”

Ní ilé Marta àti Maria

3810.38-42: Jh 12.1-3; 11.1-45.Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. 39Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

4110.41: Lk 7.13.Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

New International Reader’s Version

Luke 10:1-42

Jesus Sends Out the Seventy-Two

1After this the Lord appointed 72 others. He sent them out two by two ahead of him. They went to every town and place where he was about to go. 2He told them, “The harvest is huge, but the workers are few. So ask the Lord of the harvest to send out workers into his harvest field. 3Go! I am sending you out like lambs among wolves. 4Do not take a purse or bag or sandals. And don’t greet anyone on the road.

5“When you enter a house, first say, ‘May this house be blessed with peace.’ 6If someone there works to bring peace, your blessing of peace will rest on them. If not, it will return to you. 7Stay there, and eat and drink anything they give you. Workers are worthy of their pay. Do not move around from house to house.

8“When you enter a town and are welcomed, eat what is given to you. 9Heal the sick people who are there. Tell them, ‘God’s kingdom has come near to you.’ 10But what if you enter a town and are not welcomed? Then go into its streets and say, 11‘We wipe from our feet even the dust of your town. We do it to warn you. But here is what you can be sure of. God’s kingdom has come near.’ 12I tell you this. On judgment day it will be easier for Sodom than for that town.

13“How terrible it will be for you, Chorazin! How terrible for you, Bethsaida! Suppose the miracles done in you had been done in Tyre and Sidon. They would have turned away from their sins long ago. They would have put on the rough clothing people wear when they’re sad. They would have sat down in ashes. 14On judgment day it will be easier for Tyre and Sidon than for you. 15And what about you, Capernaum? Will you be lifted up to the heavens? No! You will go down to the place of the dead.

16“Whoever listens to you listens to me. Whoever does not accept you does not accept me. But whoever does not accept me does not accept the one who sent me.”

17The 72 returned with joy. They said, “Lord, even the demons obey us when we speak in your name.”

18Jesus replied, “I saw Satan fall like lightning from heaven. 19I have given you authority to walk all over snakes and scorpions. You will be able to destroy all the power of the enemy. Nothing will harm you. 20But do not be glad when the evil spirits obey you. Instead, be glad that your names are written in heaven.”

21At that time Jesus was full of joy through the Holy Spirit. He said, “I praise you, Father. You are Lord of heaven and earth. You have hidden these things from wise and educated people. But you have shown them to little children. Yes, Father. This is what you wanted to do.

22“My Father has given all things to me. The Father is the only one who knows who the Son is. And the only ones who know the Father are the Son and those to whom the Son chooses to make the Father known.”

23Then Jesus turned to his disciples. He said to them in private, “Blessed are the eyes that see what you see. 24I tell you, many prophets and kings wanted to see what you see. But they didn’t see it. They wanted to hear what you hear. But they didn’t hear it.”

The Story of the Good Samaritan

25One day an authority on the law stood up to test Jesus. “Teacher,” he asked, “what must I do to receive eternal life?”

26“What is written in the Law?” Jesus replied. “How do you understand it?”

27He answered, “ ‘Love the Lord your God with all your heart and with all your soul. Love him with all your strength and with all your mind.’ (Deuteronomy 6:5) And, ‘Love your neighbor as you love yourself.’ ” (Leviticus 19:18)

28“You have answered correctly,” Jesus replied. “Do that, and you will live.”

29But the man wanted to make himself look good. So he asked Jesus, “And who is my neighbor?”

30Jesus replied, “A man was going down from Jerusalem to Jericho. Robbers attacked him. They stripped off his clothes and beat him. Then they went away, leaving him almost dead. 31A priest happened to be going down that same road. When he saw the man, he passed by on the other side. 32A Levite also came by. When he saw the man, he passed by on the other side too. 33But a Samaritan came to the place where the man was. When he saw the man, he felt sorry for him. 34He went to him, poured olive oil and wine on his wounds and bandaged them. Then he put the man on his own donkey. He brought him to an inn and took care of him. 35The next day he took out two silver coins. He gave them to the owner of the inn. ‘Take care of him,’ he said. ‘When I return, I will pay you back for any extra expense you may have.’

36“Which of the three do you think was a neighbor to the man who was attacked by robbers?”

37The authority on the law replied, “The one who felt sorry for him.”

Jesus told him, “Go and do as he did.”

Jesus at the Home of Martha and Mary

38Jesus and his disciples went on their way. Jesus came to a village where a woman named Martha lived. She welcomed him into her home. 39She had a sister named Mary. Mary sat at the Lord’s feet listening to what he said. 40But Martha was busy with all the things that had to be done. She came to Jesus and said, “Lord, my sister has left me to do the work by myself. Don’t you care? Tell her to help me!”

41“Martha, Martha,” the Lord answered. “You are worried and upset about many things. 42But few things are needed. Really, only one thing is needed. Mary has chosen what is better. And it will not be taken away from her.”