1Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa, 21.2: 1Jh 1.1; Ap 1.21; Hb 2.3.àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́. 31.3: Ap 1.1.Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ, 41.4: Jh 20.31.kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Johanu onítẹ̀bọmi
51.5: Mt 2.1; 1Ki 24.10; 2Ki 31.2.Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti. 6Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn. 7Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.
8Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀. 91.9: Ek 30.7.Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. 10Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.
111.11: Lk 2.9; Ap 5.19.Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. 131.13: Lk 1.30,60.Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. 14Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ, ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. 151.15: Nu 6.3; Lk 7.33.Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. 16Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. 171.17: Mt 11.14; 17.13; Ml 4.5.Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”
18Sekariah sì wí fún angẹli náà pé, “Àmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.”
191.19: Da 8.16; 9.21; Mt 18.10.Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá. 20Sì kíyèsi i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”
21Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sekariah, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹmpili. 22Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsi wí pé ó ti rí ìran nínú tẹmpili, ó sì ń ṣe àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.
23Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀. 24Lẹ́yìn èyí ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, 25Ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó síjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrín àwọn ènìyàn.”
Ìsọtẹ́lẹ̀ ibi Jesu
26Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti, 27sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria. 28Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”
29Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. 301.30: Lk 1.13.Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 311.31: Lk 2.21; Mt 1.21.Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. 32Òun ó pọ̀, ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é, Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún. 331.33: Mt 28.18; Da 2.44.Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
341.34: Lk 1.18.Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”
351.35: Mt 1.20.Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò síji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. 36Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀, èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. 371.37: Gẹ 18.14.Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”
38Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
Maria bẹ Elisabeti wò
39Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea; 40Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti. 41Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, 421.42: Lk 11.27-28.Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí. 43Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá? 44Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀. 45Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́, nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
Orin Maria
46Maria sì dáhùn, ó ní:
“Ọkàn mi yin Olúwa lógo.
47Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀
ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó,
láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;
Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
láti ìrandíran.
51Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;
o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,
o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa
ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,
ní ìrántí àánú rẹ̀;
551.55: Mt 7.20; Gẹ 17.7; 18.18; 22.17.sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,
àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
56Maria sì jókòó tì Elisabeti níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
Ìbí Johanu onítẹ̀bọmi
57Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan. 58Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
591.59: Le 12.3; Gẹ 17.12.Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀. 60Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”
61Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é. 63Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn. 64Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run. 65Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn, a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea. 66Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
Orin Sakariah
67Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:
68“Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa
ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70(bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
71Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́
àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
72Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa,
àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
73ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
74láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
75ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
761.76: Lk 7.26; Ml 4.5.“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:
nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
771.77: Mk 1.4.láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
781.78: Ml 4.2; Ef 5.14.nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;
nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
791.79: Isa 9.2; Mt 4.16.Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní
òkùnkùn àti ní òjìji ikú,
àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”
801.80: Lk 2.40; 2.52.Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.
1Daar reeds velen ondernomen hebben, een verhaal samen te stellen van de gebeurtenissen, die onder ons zijn geschied, 2en zoals ze ons door de eerste ooggetuigen en bedienaars van het Woord zijn overgeleverd, 3kwam het ook mij wenselijk voor, beste Teófilus, na alles, van de aanvang af, nauwkeurig te hebben onderzocht, het ordelijk voor u te beschrijven, 4om u de waarachtigheid te doen zien van de leer, waarin ge onderwezen zijt. 5In de dagen van Herodes, koning van Judea, was er een priester Zakarias geheten, uit het priesterlijk geslacht van Abias; zijn vrouw behoorde tot de dochters van Aäron, en heette Elisabet. 6Beiden waren rechtschapen in de ogen van God, en leefden onberispelijk in al de geboden en voorschriften van den Heer. 7Ze hadden geen kinderen; want Elisabet was onvruchtbaar, en beiden waren reeds hoogbejaard. 8Eens, dat zijn afdeling de beurt had, om de dienst voor God te verrichten, 9werd hij, zoals dit bij de priesters gebruikelijk was, door het lot aangewezen, om de tempel des Heren binnen te gaan en wierook te offeren. 10En al het volk stond buiten te bidden op het uur van het wierookoffer. 11Daar verscheen hem een engel des Heren, die rechts van het wierookaltaar stond. 12Zakarias ontstelde bij dit gezicht, en beefde van angst. 13Maar de engel sprak tot hem: Vrees niet, Zakarias, want uw gebed is verhoord; Elisabet, uw vrouw, zal u een zoon schenken, en ge zult hem Johannes noemen. 14Ge zult juichen en jubelen, en velen zullen zich over zijn geboorte verheugen. 15Want hij zal groot zijn voor den Heer; hij zal geen wijn drinken, noch sterke drank; en reeds van de schoot zijner moeder af zal hij worden vervuld van den Heiligen Geest. 16En vele kinderen van Israël zal hij bekeren tot den Heer hun God; 17hij zal voor Hem uitgaan met de geest en de macht van Elias, om de harten der vaders tot de kinderen terug te brengen, en de weerspannigen tot de gezindheid van rechtvaardigen, en den Heer een goedgestemd volk gaan bereiden. 18Maar Zakarias zei tot den engel: Waaraan zal ik dat erkennen? Want ik ben oud, en ook mijn vrouw is reeds op jaren. 19De engel antwoordde hem: Ik ben Gábriël; ik sta voor Gods aanschijn, en ben gezonden, om u toe te spreken, en u deze blijde boodschap te brengen. 20Zie, ge zult stom zijn en niet kunnen spreken, tot de dag waarop dit geschieden zal; omdat ge mijn woorden niet hebt geloofd, die te hunner tijd in vervulling zullen gaan. 21Intussen stond het volk op Zakarias te wachten, en verwonderde zich er over, dat hij zolang in de tempel bleef. 22Maar toen hij buiten kwam, en niet tot hen kon spreken, begrepen ze, dat hij in de tempel een verschijning gezien had; wel maakte hij gebaren, maar hij bleef stom. 23Toen zijn diensttijd voorbij was, ging hij naar huis. 24Enige tijd later kwam zijn vrouw Elisabet in gezegende omstandigheden; ze verborg zich vijf maanden lang, en sprak: 25Dit heeft de Heer voor mij gedaan, toen Hij neerzag, om mijn schande bij de mensen weg te nemen. 26In de zesde maand werd de engel Gábriël door God naar een stad van Galilea gezonden, Názaret genaamd, 27tot een maagd, die verloofd was aan een man, die Josef heette, en uit het huis van David was; de naam van de maagd was Maria. 28De engel trad bij haar binnen, en sprak: Wees gegroet, vol van genade. De Heer is met u; gij zijt de gezegende onder de vrouwen. 29Ze verschrok van dit woord, en vroeg zich af, wat die groet kon beduiden. 30De engel zeide haar: Vrees niet, Maria, want gij hebt genade gevonden bij God. 31Zie, gij zult in uw schoot ontvangen, en een Zoon baren; en gij zult Hem Jesus noemen. 32Hij zal groot zijn, en Zoon van den Allerhoogste worden genoemd. God de Heer zal Hem de troon van zijn vader David geven; Hij zal koning zijn over het huis van Jakob in eeuwigheid, 33en aan zijn koningschap zal geen einde komen. 34Maria sprak tot den engel: Hoe kan dit geschieden, daar ik geen man beken? 35De engel antwoordde haar: De Heilige Geest zal op u neerdalen, en de kracht van den Allerhoogste zal u overschaduwen; daarom ook zal wat uit u wordt geboren, heilig zijn, en de Zoon van God worden genoemd. 36Zie, uw bloedverwant Elisabet heeft ook een zoon ontvangen in haar ouderdom, en zij, die onvruchtbaar heette, is in haar zesde maand; 37want niets is onmogelijk bij God. 38Nu sprak Maria: Zie de dienstmaagd des Heren; mij geschiede naar uw woord. En de engel ging van haar heen. 39In die dagen ging Maria op weg, en spoedde zich het bergland in, naar een stad van Juda. 40Ze kwam in het huis van Zakarias, en begroette Elisabet. 41Toen Elisabet de groet van Maria vernam, sprong het kind op in haar schoot, en werd Elisabet van den Heiligen Geest vervuld. 42Met luider stem hief ze aan: Gij zijt de gezegende onder de vrouwen, en gezegend is de vrucht van uw schoot! 43Wat valt mij te beurt, dat de moeder van mijn Heer naar mij toekomt? 44Want zie, zodra de klank van uw groet mij in de oren klonk, sprong het kind van vreugde op in mijn schoot. 45Zalig zij, die geloofd heeft; want wat haar namens den Heer is gezegd, zal worden vervuld. 46Maria sprak: Mijn ziel prijst groot den Heer, Mijn geest jubelt van vreugde 47In God, mijn Redder; 48Want Hij ziet op de geringheid neer van zijn dienstmaagd. Zie, van nu af prijzen mij zalig Alle geslachten; 49Want de Machtige heeft aan mij grote dingen gedaan: Zijn Naam is heilig! 50Zijn barmhartigheid reikt van geslacht tot geslacht Over hen, die Hem vrezen; 51Hij toont de kracht van zijn arm, En slaat de trotsen van harte uiteen. 52De machtigen haalt Hij neer van de troon, Maar Hij verheft de geringen; 53Behoeftigen overlaadt Hij met gaven, En rijken zendt Hij ledig heen. 54Hij heeft Zich over Israël, zijn dienaar, ontfermd; Zijn barmhartigheid indachtig: 55Zoals Hij tot onze vaderen sprak: Aan Abraham en zijn zaad voor altijd. 56Maria bleef ongeveer drie maanden bij haar; toen keerde ze terug naar huis. 57Zo kwam voor Elisabet de tijd van haar moederschap, en ze baarde een zoon. 58Haar buren en familie hoorden, dat de Heer haar grote barmhartigheid had betoond, en ze deelden in haar vreugde. 59Op de achtste dag kwam men het kind besnijden, en men wilde het Zakarias noemen, naar de naam van zijn vader. 60Maar zijn moeder nam het woord en sprak: Neen, Johannes zal hij heten. 61Ze zeiden haar: Er is niemand in uw familie, die deze naam heeft. 62Nu gaven ze zijn vader een teken, hoe hij hem wilde noemen. 63Hij vroeg een schrijfbordje, en schreef: Zijn naam is Johannes. Allen waren er over verwonderd. 64Maar op hetzelfde ogenblik ging zijn mond en tong los; hij sprak, en zegende God. 65Al hun buren werden met ontzag vervuld, en in heel het bergland van Judea werden al deze dingen besproken. 66Allen, die het hoorden, dachten er over na, en zeiden: Wat zal er toch worden van dat kind? Waarachtig, de hand des Heren was met hem! 67En zijn vader Zakarias, vervuld van den Heiligen Geest, profeteerde en sprak: 68Geloofd zij de Heer, Israëls God! Want Hij heeft zijn volk bezocht en verlost, 69En ons een hoorn van redding verwekt In het huis van David, zijn dienaar. 70Zoals Hij eeuwen geleden beloofd had Door de mond zijner heilige profeten: 71Om ons redding te brengen van onze vijanden, En uit de hand van al, die ons haten. 72Om Zich te ontfermen over onze vaderen, En zijn heilig Verbond te gedenken, 73De eed, die Hij zwoer, Aan Abraham, onzen vader. 74Om ons te vergunnen, om zonder vrees, Uit de hand onzer vijanden verlost, 75Hem te dienen, vroom en rechtschapen, Voor zijn aanschijn al onze dagen. 76En Gij nu, kleine knaap, Zult profeet van den Allerhoogste worden genoemd; Want ge zult uitgaan voor den Heer, Om zijn wegen te bereiden. 77Om zijn volk het heil te doen kennen In de vergiffenis zijner zonden, 78Door de tedere ontferming van onzen God, Die ons de Dageraad uit den hoge zal brengen. 79Om te verlichten, die in duisternis zijn, En in de schaduw van de dood zijn gezeten; Om onze schreden te richten Naar de weg van de vrede. 80En de knaap groeide op, en kreeg een krachtige geest. Hij bleef in de woestijn tot de dag, dat hij voor Israël zou optreden.