Lefitiku 5 – YCB & APSD-CEB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 5:1-19

1“ ‘Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé kò sọ̀rọ̀ nígbà tí a bi í ní gbangba pé kó jẹ́rìí nípa nǹkan tó rí tàbí nǹkan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù ú.

2“ ‘Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi. 3Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ohunkóhun tó lè mú ènìyàn di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi. 4Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yówù tó ti búra láì kíyèsi ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi. 5Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀ 6àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú wa fún Olúwa, abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.

7“ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun. 8Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan, 9kí ó sì wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó ro sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dáríjì í.

11“ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá, kí ó mú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 12Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 13Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ”

Ẹbọ ẹ̀bi

14Olúwa sọ fún Mose pé, 15“Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni. 16Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ nínú ti àwọn ohun mímọ́, kí ó sì fi ìdámárùn-ún kún iye rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà. Àlùfáà yóò sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe ètùtù fún, a ó sì dáríjì í.

17“Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin Olúwa, bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ 18kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dáríjì í. 19Ẹbọ ẹ̀bi ni, ó ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí Olúwa.”

Ang Pulong Sa Dios

Leviticus 5:1-19

1Kon ang usa ka tawo modumili sa pagsulti ngadto sa korte bahin sa mga butang nga iyang nakita o nahibaloan, may tulubagon siya. 2Kon may makahikap sa bisan unsa nga butang nga giisip nga hugaw, sama sa patayng lawas sa hugaw nga mga mananap,5:2 hugaw nga mga mananap: Ang buot ipasabot, mga mananap nga dili mahimo kan-on o ihalad sa Ginoo. Tan-awa ang kapitulo 11. makasala siya ug makapahugaw kini kaniya,5:2 makapahugaw kini kaniya: Ang buot ipasabot, dili siya takos nga motambong sa mga seremonya sa ilang relihiyon. bisan wala niya mahibaloi nga nakahikap siya. 3Kon nakahikap siya sa hugaw nga mga butang sa tawo5:3 hugaw nga mga butang sa tawo: Tan-awa ang kapitulo 12-15. nga wala niya mahibaloi, nga tungod niini nakapahimo kaniyang hugaw, nakasala siya sa higayon nga mahibaloan na niya kini.

4Kon manumpa ang usa ka tawo diha-diha sa walay paghunahuna kon maayo o daotan ang iyang gipanumpaang buhaton, nakasala siya kon maamgohan na niya ang iyang gihimo. 5Kon nahibaloan sa tawo nga nakasala siya sa bisan asa niini, kinahanglan nga isulti niya kini. 6Ug isip bayad sa sala nga iyang nahimo, maghalad siya sa Ginoo ug usa ka bayeng karnero o kanding isip halad sa paghinlo. Ang pari ang mohalad niini ug mahinloan siya gikan sa iyang sala.

7Apan kon dili siya makahimo paghalad ug karnero o kanding, maghalad na lang siya ug duha ka salampati o duha ka tukmo isip bayad sa iyang sala: ang usa halad sa paghinlo ug ang usa halad nga sinunog. 8Dad-on niya kini ngadto sa pari ug unahon paghalad sa pari ang halad sa paghinlo. Lubagon sa pari ang liog niini, apan dili niya putlon. 9Ug isablig niya ang uban nga dugo niini sa kilid sa halaran, ug ang nahibilin nga dugo ipatulo niya sa kinaubosang bahin sa halaran. Halad kini sa paghinlo. 10Ihalad usab dayon sa pari ang usa pa ka halad nga sinunog, sumala sa pamaagi sa paghalad niini. Pinaagi sa paghimo sa pari niini, mahinloan ang tawo gikan sa iyang sala ug pasayloon siya sa Ginoo.

11Apan kon dili pa gayod siya makahimo paghalad ug duha ka salampati o duha ka tukmo, maghalad na lang siya ug usa ka kilo nga maayong klase sa harina. Kinahanglan nga dili niya kini butangan ug mantika ug insenso kay halad kini sa paghinlo, ug dili halad sa pagpasidungog sa Ginoo. 12Dad-on niya kini ngadto sa pari ug kuhaan kini sa pari ug usa ka kumkom isip paghinumdom sa Ginoo. Ug ang iyang kinuha sunogon niya sa halaran kauban sa uban pa nga mga halad nga alang sa Ginoo pinaagi sa kalayo. Halad kini sa paghinlo. 13Pinaagi sa paghimo niini sa pari, mahinloan ang tawo sa bisan asa niadto nga mga sala nga iyang nahimo ug pasayloon siya sa Ginoo. Ang nahibilin nga halad nga harina iya na sa pari, sama usab sa gihimo sa halad sa pagpasidungog sa Ginoo.

Ang Halad Isip Bayad sa Sala

14Gisugo pa gayod kini sa Ginoo kang Moises:

15Kon ang usa ka tawo makalapas sa sugo sa Ginoo tungod kay wala niya mahatag ang butang nga alang unta sa Ginoo, bisan wala niya tuyoa, kinahanglan nga maghalad siya ug laking karnero nga walay depekto isip bayad sa iyang sala. O bayran niya ug salapi ang kantidad sa karnero basi sa gibug-aton sa pilak diha sa kilohan nga ginagamit sa mga pari. Kini nga karnero halad isip bayad sa sala.5:15 halad isip bayad sa sala: Tan-awa ang Lista sa mga Pulong sa luyo. 16Kinahanglan nga bayran niya ang wala niya mahatag sa Ginoo, ug dugangan pa niya kini ug 20 porsyento sa kantidad niini. Unya ihatag niya kining tanan sa pari nga mao ang maghalad ug usa ka laking karnero aron mahinloan ang tawo gikan sa iyang sala ug pasayloon siya sa Ginoo.

17Kon ang usa ka tawo nakalapas sa sugo sa Ginoo bisan wala niya mahibaloi, nakasala siya ug may tulubagon siya sa Ginoo. 18-19Kon mahibaloan na niya nga nakasala diay siya, kinahanglan nga magdala siya ngadto sa pari ug laking karnero nga walay depekto, nga ihalad niya isip bayad sa iyang sala. O bayran niya ug salapi ang kantidad sa karnero basi sa gibug-aton sa pilak diha sa kilohan nga ginagamit sa mga pari. Pinaagi sa paghimo niini sa pari, mahinloan ang tawo gikan sa iyang sala nga wala tuyoa ug pasayloon siya sa Ginoo.