Lefitiku 26 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 26:1-46

Èrè ìgbọ́ràn

126.1: Le 19.4; El 20.4,23; De 4.15-18; 27.15.‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

226.2: El 20.8; 23.12; 34.21; 35.2,3; Le 19.3,30; De 5.12-15.“ ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa.

326.3-13: De 7.12-26; 28.1-14.“ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́. 4Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso. 5Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.

6“ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já. 7Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín, wọn yóò sì tipa idà kú. 8Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn, àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.

9“ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín, Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, Èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i, Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín. 10Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde, kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí. 1126.11,12: 2Kọ 6.16.Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín. 12Èmi yóò wà pẹ̀lú yín, Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín, ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi. 13Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.

Ìjìyà fún àìgbọ́ràn

1426.14-45: De 28.16-68.“ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí. 15Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi. 16Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín, Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn. 17Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.

18“ ‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí, Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 19Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín, ojú ọ̀run yóò le koko bí irin, ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le). 20Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.

21“ ‘Bí ẹ bá tẹ̀síwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 22Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárín yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.

23“ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi. 24Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú. 25Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò, Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín, àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín. 26Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.

27“ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi, 28ní ìbínú mi, èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 29Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin. 30Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn, Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín. 31Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́. 32Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà. 33Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun. 34Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un. 35Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.

36“ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín. 37Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín. 38Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.

4026.40,41: Ap 7.51.“ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi. 41Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà. 43Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófo láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórìíra àwọn àṣẹ mi. 44Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá, èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn. 45Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”

46Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mose ní orí òkè Sinai láàrín òun àti àwọn ọmọ Israẹli.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

利未记 26:1-46

遵行诫命蒙祝福

1“你们不可为自己制造偶像,不可竖立神像和神柱,也不可在你们境内安放祭拜用的石像。我是你们的上帝耶和华。 2你们要守我的安息日,敬畏我的圣所。我是耶和华。 3如果你们遵行我的律例,持守我的诫命, 4我就按时降雨给你们,使土地长出庄稼、果树结出果实。 5你们要打粮食打到摘葡萄的时候,摘葡萄摘到播种的时候。你们必丰衣足食,安然居住。

6“我要使你们得享太平,安枕无忧。我要除掉你们境内的猛兽,也要使你们免遭刀剑之灾。 7你们将追赶仇敌,使他们倒在你们刀下。 8你们五人要追赶一百人,一百人要追赶一万人,他们必死在你们刀下。 9我要眷顾你们,使你们生养众多,也要坚守与你们所立的约。 10你们存粮很多,甚至要搬出陈粮来储存新粮。 11我要住在你们中间,我必不厌弃你们。 12我要在你们中间往来。我要做你们的上帝,你们要做我的子民。 13我是你们的上帝耶和华。我曾带领你们离开埃及,使你们不再做埃及人的奴隶。我打碎了压在你们身上的重轭,使你们能昂首挺胸、扬眉吐气。

违背诫命受惩罚

14“如果你们不听从我,不遵行我的这一切诫命; 15如果你们拒绝遵守我的律例,厌弃我的典章,不听从我的命令,破坏我与你们所立的约, 16我要惩罚你们,使你们陷入恐慌、患痨病和热症,使你们眼睛昏花、心力衰竭。你们撒种却一无所获,因为敌人要吃尽你们所种的。 17我要严惩你们,使你们败在敌人手下;你们要被那些恨你们的人统治,即使没有人追赶,你们也要逃命。

18“如果你们受过这些惩罚,仍然不知悔改,我要把比先前严厉七倍的惩罚加在你们身上。 19我要重挫你们的傲气,使你们头上的天如铁,脚下的地如铜。 20你们劳作也是徒然,因为你们的土地必不长庄稼,果树也不结果实。

21“如果你们仍然与我作对,不肯听从我,我要把比先前严重七倍的灾难降在你们身上。 22我要让野兽残害你们的子女,吞噬你们的牲畜,使你们人口锐减,路上杳无人迹。

23“如果你们还是与我作对, 24我也要与你们作对,用比先前严重七倍的灾难击打你们。 25因为你们毁约,我要用战祸报应你们。你们躲进各城的时候,我要在你们中间降下瘟疫,使你们落在敌人手里。 26我要断绝你们的粮源。那时候,十个妇女将用一个烤炉烤饼,按定量分饼给你们,你们吃却吃不饱。

27“如果你们仍然不肯听从我,继续与我作对, 28我也要与你们作对,向你们发烈怒,把比先前严厉七倍的惩罚加在你们身上。 29你们要吃自己儿女的肉。 30我要毁灭你们的丘坛,拆掉你们的香坛,把你们的尸体堆在你们毫无气息的神像上。我厌恶你们。 31我要使你们的城邑沦为废墟,使你们的敬拜场所荒凉,也不再悦纳你们的馨香之祭。 32我要使你们的土地荒废,连占据那里的敌人也为此而震惊。 33我要把你们驱散到各国,还要拔刀追杀你们。你们的土地将荒废,城邑将沦为废墟。 34你们被掳到敌国的时候,你们的土地将荒废,享受安息。 35你们住在那里的时候,没有在安息年让土地安息,因此土地在荒废的日子里将享受安息。

36“我要使你们当中的那些幸存者在敌国心惊胆战,过着风声鹤唳、惶恐不安的生活。 37即使无人追赶,他们也将仓皇逃命,互相绊倒,如同躲避刀剑一样。你们必无力抵挡敌人。 38你们将葬身列国,死在敌人的土地上。 39你们当中的幸存者将因自己的罪和祖先的罪而消亡在敌人的土地上。

认罪悔改蒙眷顾

40“如果他们承认自己和祖先的罪,就是背叛我、与我作对的恶行—— 41以致我与他们作对,把他们流放到敌国;如果他们顽固26:41 顽固”希伯来文是“未受割礼”。的心谦卑下来,甘愿接受刑罚, 42我便履行我与亚伯拉罕以撒雅各所立的约,眷顾那片土地。 43土地被他们离弃,荒无人烟,得享安息。他们却要因拒绝遵守我的典章、厌弃我的律例而饱受惩罚。 44然而,他们流落敌国的时候,我不会弃绝他们,不会因厌恶而毁灭他们,也不会违背我与他们所立的约。我是他们的上帝耶和华。 45我必为他们的缘故履行我与他们祖先所立的约。我曾在列国面前带领他们的祖先离开埃及,为要做他们的上帝。我是耶和华。”

46以上是耶和华借摩西西奈山上颁布给以色列人的律例、典章和法度。