Lefitiku 17 – YCB & APSD-CEB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 17:1-16

Ẹ̀jẹ̀ jíjẹ jẹ́ èèwọ̀

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ‘Ohun tí Olúwa pàṣẹ nìyí, 3bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó 4tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé, ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 5Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa. 6Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa. 7Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.’

8“Kí ó sọ fún wọn pé, ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ 9tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

1017.10-16: Le 3.17; 7.26,27; 19.26; De 12.16,23-25.“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13“ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan, torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.

15“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnra rẹ̀, tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò, ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́. 16Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”

Ang Pulong Sa Dios

Leviticus 17:1-16

Ang mga Patakaran bahin sa Hustong Dapit sa Paghalad ug bahin sa Dugo

1Gisugo sa Ginoo si Moises 2nga isulti kini kang Aaron ug sa iyang mga anak nga lalaki ug sa tanang mga Israelinhon:

3Si bisan kinsa kaninyo nga mohalad ug baka, karnero, o kanding sa laing dapit, 4-5ug dili didto sa Tolda nga Simbahan, nga gitawag usab ug Tolda nga Tagboanan, sama rang nakapatay siya ug tawo. Busa ayaw na ninyo siya isipa nga inyong sakop. Gihimo kini nga patakaran aron himuon ninyo ang paghalad didto sa pultahan sa Tolda ug dili sa laing dapit. Ang inyong halad alang sa pakigda-it ihatag ninyo sa pari nga mao ang mohalad niini ngadto sa Ginoo. 6Isablig sa pari ang dugo sa mananap didto sa halaran sa Ginoo, nga anaa dapit sa pultahan sa Tolda. Unya sunogon niya ang mga tambok sa mananap; ang kahumot niini nga halad makapalipay sa Ginoo. 7Kinahanglan dili na kamo mohalad ngadto sa mga demonyo nga daw kanding, kay kana makapahilayo kaninyo sa Ginoo. Kinahanglan nga tumanon ninyo kini hangtod sa umaabot nga mga henerasyon.

8Timan-i gayod ninyo kini, kamong mga Israelinhon ug ang mga langyaw nga nagapuyo uban kaninyo:

Si bisan kinsa kaninyo nga mohalad ug bisan unsa nga halad didto sa laing dapit 9ug dili didto sa pultahan sa Tolda, ayaw na ninyo siya isipa nga inyong sakop.

10Si bisan kinsa kaninyo nga mokaon ug dugo kapungtan sa Ginoo, ug ayaw na ninyo siya isipa nga inyong sakop. 11Kay ang kinabuhi sa matag binuhat anaa sa iyang dugo, ug gisugo kamo sa Ginoo nga gamiton ninyo kini aron mahinloan kamo gikan sa inyong mga sala. Kay ang dugo nga mao ang nagahatag ug kinabuhi, mao ang makahinlo sa tawo gikan sa iyang mga sala. 12Mao kini ang hinungdan kon nganong dili kamo angay mokaon ug dugo.

13Si bisan kinsa kaninyo o sa mga langyaw nga nagapuyo uban kaninyo nga mangdakop ug mananap o langgam nga mahimong kaonon, kinahanglan nga paagason niya ang dugo niini ug tabonan ug yuta, 14tungod kay ang kinabuhi sa matag binuhat anaa sa iyang dugo. Mao kana nga gisultihan kamo sa Ginoo nga dili kamo mokaon ug dugo sa bisan unsa nga binuhat. Ug si bisan kinsa nga mokaon, ayaw na ninyo siya isipa nga inyong sakop.

15Si bisan kinsa kaninyo o sa mga langyaw nga nagapuyo uban kaninyo nga mokaon sa mananap nga namatay lang o gipatay sa lain nga mananap, kinahanglan labhan niya ang iyang bisti ug maligo, apan isipon pa gihapon siya nga hugaw hangtod sa pagsalop sa adlaw. 16Kon dili niya labhan ang iyang bisti ug dili siya maligo, may tulubagon siya.