Ọrẹ ẹbọ sísun
1Olúwa sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé; 2“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.
3“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa 4kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un. 5Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká. 6Òun yóò bó awọ ara ẹbọ sísun náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́. 7Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà. 8Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò tó ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 9Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
10“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká 12Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 13Kí ó fi omi ṣan nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ẹbọ sísun tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
14“ ‘Bí ó bá sì ṣe pé ti ẹyẹ ni ẹbọ sísun ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí Olúwa, ǹjẹ́ kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá nínú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé 15Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16Kí ó yọ àjẹsí (àpò oúnjẹ) ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà-oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà 17Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má ya á tan pátápátá. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
Жертва всесожжения
1Господь позвал Моисея и говорил с ним из шатра собрания. Он сказал: 2«Обратись к израильтянам и скажи им: если кто-то из вас приносит Господу в жертву скот, пусть это будет животное из крупного или мелкого скота.
3Если приношение — это всесожжение из крупного скота, пусть жертвующий принесет в жертву самца без изъяна. Пусть он поставит жертву у входа в шатер собрания, чтобы она была угодна1:3 Или: чтобы она сделала его угодным. Господу. 4Пусть он положит руки на голову жертвы всесожжения, и она будет принята от его лица, чтобы совершилось искупление для него. 5Пусть он заколет молодого быка перед Господом, а сыновья Аарона, священники, принесут кровь и окропят со всех сторон жертвенник, который находится у входа в шатер собрания. 6Пусть жертвующий снимет шкуру с туши жертвы всесожжения и разрежет на куски. 7Сыновья священника Аарона разведут на жертвеннике огонь и разложат в огне дрова. 8Затем священники, сыновья Аарона, разложат куски, вместе с головой и жиром, на жертвеннике на горящих дровах. 9Пусть жертвующий вымоет внутренности и ноги жертвы, а священник сожжет их на жертвеннике. Это будет всесожжение, огненная жертва, благоухание, приятное Господу.
10Если приношение — это всесожжение из мелкого скота, из овец или из коз, пусть он принесет в жертву самца без изъяна. 11Пусть он заколет его с северной стороны жертвенника перед Господом, а священники, сыновья Аарона, окропят кровью самца жертвенник со всех сторон. 12Пусть он разрежет тушу на куски, а священник разложит их, вместе с головой и жиром, на горящих дровах жертвенника. 13Пусть он вымоет внутренности и ноги жертвы, а священник принесет их и сожжет на жертвеннике. Это будет всесожжение, огненная жертва, благоухание, приятное Господу.
14Если приношение Господу — это всесожжение из птиц, пусть он принесет в жертву горлицу или молодого голубя. 15Пусть священник принесет птицу к жертвеннику, свернет ей голову и сожжет ее на жертвеннике; кровь пусть будет выцежена к стороне жертвенника. 16Пусть он удалит зоб и перья1:16 Или: зоб и его содержимое. Значение этого евр. слова неизвестно. и бросит их к восточной стороне жертвенника, туда, где пепел. 17Взяв птицу за крылья, пусть он вскроет ее, но не до конца, а потом сожжет на горящих дровах жертвенника. Это будет всесожжение, огненная жертва, благоухание, приятное Господу.