Lefitiku 1 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 1:1-17

Ọrẹ ẹbọ sísun

1Olúwa sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé, 2“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.

3“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa 4kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un. 5Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká. 6Òun yóò bó awọ ara ẹbọ sísun náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́. 7Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà. 8Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò tó ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 9Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

10“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká. 12Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 13Kí ó fi omi ṣan nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ẹbọ sísun tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

14“ ‘Bí ó bá sì ṣe pé ti ẹyẹ ni ẹbọ sísun ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí Olúwa, ǹjẹ́ kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá nínú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé. 15Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16Kí ó yọ àjẹsí ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà-oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà. 17Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má ya á tan pátápátá. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

Bibelen på hverdagsdansk

3. Mosebog 1:1-17

Regler for brændofre, henvendt til folket

1Herren kaldte på Moses fra åbenbaringsteltet 2og sagde: „Giv Israels folk følgende instrukser: Når en af jer vil give en offergave til Herren, kan han bringe et af sine husdyr: et stykke kvæg, et får eller en ged. 3Hvis han bringer et stykke kvæg som brændoffer, skal det være en tyr uden skavanker. Han skal bringe dyret hen til åbenbaringsteltets indgang som en gave til Herren. 4Der skal han lægge sin hånd på tyrens hoved, så Herren kan modtage det som hans stedfortrædende offer og tilgive hans synd. 5Manden skal derefter slagte dyret i Herrens påsyn, og præsterne skal bringe blodet som et offer til Herren ved at stænke det på siderne af alteret, der står ved indgangen til teltet. 6Derefter skal han flå dyret og partere det. 7Præsterne skal starte et bål på alteret 8og lægge det parterede dyr inklusive dets hoved og alt fedtet oven på alterbrændet. 9Tyrens indvolde og skanke skal han vaske med vand, før de bliver lagt på alteret. På den måde skal præsterne brænde det hele, og det bliver et offer, som behager Herren.

10Hvis brændofferdyret er et får eller en ged, gælder det samme: Dyret skal være et handyr uden fysiske defekter. 11Manden, som bringer offerdyret, skal slagte dyret ved alterets nordside, og præsterne skal stænke blodet på siderne af alteret. 12Så skal manden partere dyret, og præsterne skal lægge det parterede dyr inklusive dets hoved og alt fedtet oven på alterbrændet. 13Men indvoldene og skankene skal han først vaske med vand. Således skal præsterne brænde det hele på alteret som et brændoffer til Herrens velbehag.

14Hvis nogen ønsker at bringe en fugl som brændoffer, skal det være en turteldue eller en ung due. 15Præsten skal bringe fuglen til alteret, nippe halsen over på den, lade blodet løbe ned ad alterets side og brænde fuglens hoved på alteret. 16Derefter skal han fjerne fuglens kro og fjer og kaste dem på askedyngen ved alterets østside. 17Så skal han rive vingerne løs uden at skille dem helt fra kroppen og så brænde resten af fuglen på alteret. På den måde bliver det et lifligt offer for Gud.