Kolose 2 – YCB & CCB

Yoruba Contemporary Bible

Kolose 2:1-23

1Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodikea àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí. 2Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀. 32.3: Isa 45.3.Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí. 4Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma ba à fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín ṣìnà. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsi ètò yín àti bí ìdúró ṣinṣin yín nínú Kristi ti rí.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú ẹ̀mí nínú Kristi

6Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. 7Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

8Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.

9Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, 102.10: Ef 1.21-22.ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

13Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. 152.15: Ef 1.21.Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.

162.16: Ro 14.1-12.Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: 172.17: Ef 1.23.Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ. 18Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ní inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn angẹli lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nípa èrò ti ọkàn ara rẹ̀. 192.19: Ef 1.22; 4.16.Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.

202.20: Ga 4.3.Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, 21Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á, 222.22: Isa 29.13; Mk 7.7.Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn? 23Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.

Chinese Contemporary Bible 2022 (Simplified)

歌罗西书 2:1-23

1我希望你们知道,为了你们和老底嘉人,以及那些从未和我见过面的人,我怎样努力奋斗, 2为要使你们众人心受鼓励,在爱中联结,有丰富笃定的真知灼见,可以认识上帝的奥秘。这奥秘就是基督, 3祂里面蕴藏着一切智慧和知识的宝藏。 4我讲这番话是为了防止有人用花言巧语迷惑你们。 5现在,我人虽不在你们那里,心却和你们在一起,看到你们井然有序,对基督坚信不移,我很喜乐。

生活以基督为中心

6你们既然接受了基督耶稣为主,就当继续遵从祂, 7按照你们所受的教导在祂里面扎根成长,信心坚固,满怀感恩。

8你们要谨慎,免得有人用空洞虚假的哲学把你们掳去。这些哲学不是出于基督,而是出于人的传统和世界的基本规条。 9因为上帝的本质全部有形有体地蕴含在基督里, 10你们在基督里得到了丰盛的生命。祂是一切执政者和掌权者的元首。

11你们也在基督里受了非人手所行的割礼,是基督为除掉你们罪恶本性而行的割礼。 12你们接受洗礼时已经与基督一同埋葬了,并借着相信上帝使基督从死里复活的大能,与基督一同复活了。 13你们从前死在过犯和未被割除的本性中,但现在上帝却使你们与基督一同活了过来。上帝赦免了我们一切的过犯, 14撤销了指控我们违背律法的罪状,把它钉在十字架上,将它消除。 15祂扫除了灵界的诸多权势,用十字架上的胜利公开羞辱它们。

16所以,不可让人在饮食、节期、朔日2:16 “朔日”即每月初一。或安息日的事上论断你们。 17这些都不过是将来之事的影子,实体就是基督。 18有些人喜欢故作谦卑,敬拜天使,沉迷于所看见的幻象,你们不要因他们而失去得奖赏的资格。他们随从自己堕落的思想无故自高自大, 19没有与身体的头基督联结。其实,全身靠关节和筋络维系,从基督得到供应,按上帝的旨意渐渐成长。

20你们既然和基督一同死了,摆脱了世界的基本规条,为什么仍像活在世俗中, 21服从“不可拿、不可尝、不可摸”等规条呢? 22这些规条不过是人的戒律和说教,经不起应用, 23看似充满智慧,其实只不过是自创宗教、自表谦卑、苦待己身,对于克制邪情私欲毫无用处。