Jona 1 – YCB & BDS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jona 1:1-17

Jona sá ní iwájú Olúwa

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona ọmọ Amittai wá, wí pé: 2“Dìde lọ sí ìlú ńlá Ninefe kí o sì wàásù sí i, nítorí ìwà búburú rẹ̀ gòkè wá iwájú mi.”

3Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa.

4Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́. 5Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́.

Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra. 6Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.”

7Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. 8Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?”

9Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.”

10Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú Olúwa ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀).

11Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó ṣe sí ọ kí Òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí Òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle.

12Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.”

13Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. 14Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” 15Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. 16Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Olúwa gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.

17Ṣùgbọ́n Olúwa ti pèsè ẹja ńlá kan láti gbé Jona mì. Jona sì wà nínú ẹja náà ni ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.

La Bible du Semeur

Jonas 1:1-16

La fuite de Jonas

1L’Eternel adressa la parole à Jonas1.1 Sur Jonas, voir 2 R 14.25-27., fils d’Amittaï, en ces termes : 2Mets-toi en route, va à Ninive1.2 Capitale de l’Empire assyrien, l’une des grandes puissances de l’époque. la grande ville et proclame des menaces contre ses habitants, car l’écho de leur méchanceté est parvenu jusqu’à moi.

3Jonas se mit en route pour s’enfuir à Tarsis1.3 A l’opposé de la direction dans laquelle l’Eternel l’envoyait, peut-être Tartessos en Espagne, colonie minière phénicienne située près de Gibraltar., loin de la présence de l’Eternel. Il descendit au port de Jaffa1.3 Port maritime de Jérusalem, aujourd’hui faubourg de Tel-Aviv (voir Ac 10.5)., où il trouva un navire en partance pour Tarsis. Il paya le prix de la traversée et descendit dans le bateau pour aller avec l’équipage à Tarsis, loin de la présence de l’Eternel.

4Mais l’Eternel fit souffler un grand vent sur la mer et déchaîna une si grande tempête que le navire menaçait de se briser. 5Les marins furent saisis de crainte, et chacun se mit à implorer son dieu. Puis ils jetèrent la cargaison par-dessus bord pour alléger le navire. Quant à Jonas, il était descendu dans la cale du bateau, il s’était couché et dormait profondément. 6Le capitaine s’approcha de lui et l’interpella : Hé quoi ! Tu dors ! Mets-toi debout et prie ton Dieu. Peut-être Dieu se souciera-t-il de nous et nous ne périrons pas.

7Pendant ce temps, les matelots se dirent entre eux : Allons, tirons au sort pour savoir qui nous attire ce malheur.

Ils tirèrent donc au sort et Jonas fut désigné. 8Alors ils lui demandèrent : Fais-nous savoir qui nous attire ce malheur ! Quelles sont tes occupations ? D’où viens-tu ? De quel pays ? Et de quel peuple es-tu ?

9Jonas leur répondit : Je suis hébreu et je crains l’Eternel, le Dieu du ciel qui a fait la mer et la terre.

10Il leur apprit qu’il s’enfuyait loin de la présence de l’Eternel. Aussi ces hommes furent-ils saisis d’une grande crainte et lui dirent : Pourquoi as-tu fait cela ?

11Comme la mer se démontait de plus en plus, ils lui demandèrent : Que te ferons-nous pour que la mer se calme et cesse de nous être contraire ?

12Il leur répondit : Prenez-moi et jetez-moi à la mer, et la mer se calmera, car je sais bien que c’est à cause de moi que cette grande tempête s’est déchaînée contre vous.

13Ces hommes se mirent d’abord à ramer de toutes leurs forces pour regagner la côte, mais ils n’y parvinrent pas, car la mer se déchaînait toujours plus contre eux. 14Alors ils crièrent à l’Eternel et dirent : O Eternel, nous t’en prions, ne nous fais pas périr à cause de cet homme et ne nous tiens pas responsables de la mort d’un innocent. Car toi, ô Eternel, tu as fait ce que tu as voulu.

15Puis ils prirent Jonas et le jetèrent par-dessus bord. Aussitôt, la mer en furie se calma. 16Alors l’équipage fut saisi d’une grande crainte envers l’Eternel ; ils lui offrirent un sacrifice et s’engagèrent envers lui par des vœux.