Johanu 8 – YCB & GKY

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 8:1-59

1Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.

2Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. 3Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. 4Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà. 5Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” 6Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.

Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. 7Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” 8Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

9Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn olùfisùn rẹ dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”

Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi, máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

Ẹ̀rí Jesu dájú

128.12: Jh 9.5; 12.35; 1.4.Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

138.13-18: Jh 5.31-39.Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

14Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ. 158.15: Jh 7.24; 3.17.Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. 168.16: Jh 5.30.Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni, nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi. 178.17: De 19.15; Mt 18.16.A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. 18Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”

198.19: Jh 14.7.Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”

Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi, ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” 208.20: Mk 12.41; Jh 7.30.Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili, ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.

218.21-22: Jh 7.33-36.Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

22Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

238.23: Jh 3.31; 17.14; 1Jh 4.5.Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. 248.24: Jh 8.28; 4.26; 13.19; Mk 13.6.Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”

Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. 26Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”

27Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. 288.28: Jh 3.14; 12.32.Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ Ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi, ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. 29Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” 308.30: Jh 7.31; 10.42; 11.45.Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

Àwọn ọmọ Abrahamu

318.31: Jh 15.7; 2Jh 9.Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 328.32: 2Kọ 3.17; Ga 5.1.Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

338.33: Mt 3.9; Ga 3.7.Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”

348.34: Ro 6.16; 2Pt 2.19.Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 358.35: Gẹ 21.10; Ga 4.30.Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé, ọmọ ní ń gbé ilé títí láé. 36Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́. 37Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Abrahamu ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí ààyè nínú yín. Jesu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀. 38Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ, ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”

39Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”

Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu. 40Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Abrahamu kò ṣe èyí. 418.41: De 32.6; Isa 63.16; 64.8.Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”

Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà, a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

Àwọn ọmọ èṣù

428.42: Jh 13.3; 16.28.Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi, nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 448.44: 1Jh 3.8,15; Gẹ 3.4; 1Jh 2.4; Mt 12.34.Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

Jesu béèrè nípa ohun tí n ṣe ti ara rẹ̀

488.48: Jh 7.20; 10.20; 4.9.Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”

49Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi. 50Èmi kò wá ògo ara mi, ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́. 51Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”

52Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé.’ 538.53: Jh 4.12.Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú, ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

54Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan, Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe. 55Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin, ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. 568.56: Mt 13.17; Hb 11.13.Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi, ó sì rí i, ó sì yọ̀.”

578.57: Jh 2.20.Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?”

588.58: Jh 1.1; 17.5,24.Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.” 598.59: Jh 10.31; 11.8.Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú, ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.

Holy Bible in Gĩkũyũ

Johana 8:1-59

1No rĩrĩ, Jesũ agĩthiĩ Kĩrĩma-inĩ kĩa Mĩtamaiyũ. 2Na rũciinĩ tene akĩroka o rĩngĩ kũu nja cia hekarũ, kũrĩa andũ othe maamũrigiicĩirie. Nake agĩikara thĩ kũmaruta. 3Arutani a watho hamwe na Afarisai makĩrehe mũtumia wanyiitĩtwo agĩtharia. Makĩmũrũgamia hau mbere ya gĩkundi, 4na makĩĩra Jesũ atĩrĩ, “Mũrutani, mũtumia ũyũ aanyiitwo agĩtharia. 58:5 Alaw 20:10; Gũcook 22:22Thĩinĩ wa watho-rĩ, Musa aatwathire tũhũũrage atumia ta aya na mahiga nyuguto. Rĩu we ũkuuga atĩa?” 68:6 Math 22:5, 18Maahũthagĩra kĩũria gĩkĩ kĩrĩ ta mũtego, nĩgeetha magĩe na ũndũ wa kũmũthitangĩra.

No Jesũ akĩinamĩrĩra, na akĩambĩrĩria kwandĩka thĩ na kĩara gĩake. 78:7 Gũcook 17:7; Arom 2:1, 22Na rĩrĩa maathiire na mbere kũmũũria ũhoro ũcio, akĩinamũka, akĩmeera atĩrĩ, “Angĩkorwo harĩ na ũmwe wanyu ũtarĩ ehia-rĩ, nĩatuĩke wa mbere kũmũikĩria ihiga.” 8Agĩcooka akĩinamĩrĩra rĩngĩ, akĩandĩka thĩ na kĩara.

9Rĩrĩa maiguire ũguo, makĩambĩrĩria kwehera hau ũmwe kwa ũmwe, maambĩrĩirie na arĩa akũrũ, nginya hagĩtigara o Jesũ na mũtumia ũcio arũngiĩ o hau. 10Jesũ akĩinamũka, akĩmũũria atĩrĩ, “Mũtumia ũyũ, agũthitangi marĩ ha? Hatirĩ o na ũmwe wao wagũtuĩra?”

118:11 Joh 3:17; Joh 5:14Nake akĩmũcookeria atĩrĩ, “Mũthuuri ũyũ, gũtirĩ o na ũmwe.”

Nake Jesũ akiuga atĩrĩ, “O na niĩ ndigũgũtuĩra. Thiĩ, na ndũkanacooke kwĩhia.”)

Ũira wa Jesũ nĩ wa Ma

128:12 Joh 6:35; Thim 4:18; Math 5:14Rĩrĩa Jesũ aarĩirie andũ rĩngĩ, akiuga atĩrĩ, “Niĩ nĩ niĩ ũtheri wa thĩ. Ũrĩa wothe ũnũmagĩrĩra ndarĩ hĩndĩ arĩthiiaga na nduma, no arĩgĩaga na ũtheri wa muoyo.”

138:13 Joh 5:31Nao Afarisai makĩmũkararia, makĩmwĩra atĩrĩ, “We ũraheana ũira waku wee mwene; ũira waku ti wa ma.”

148:14 Joh 13:13Nake Jesũ agĩcookia atĩrĩ, “O na ingĩruta ũira wakwa niĩ mwene-rĩ, ũira wakwa nĩ wa ma, nĩgũkorwo nĩnjũũĩ kũrĩa ndoimire o na kũrĩa ndĩrathiĩ. No inyuĩ mũtiũĩ kũrĩa nyumĩte kana kũrĩa ndĩrathiĩ. 158:15 Joh 7:24; Joh 3:17Inyuĩ mũtuanagĩra ciira na ũmũndũ; niĩ ndirĩ mũndũ nduagĩra ciira. 16No o na ingĩtuanĩra ciira-rĩ, itua rĩakwa nĩrĩagĩrĩire, nĩgũkorwo ndituanagĩra ndĩ nyiki. No niĩ ndĩ na Baba, ũrĩa wandũmire. 178:17 Math 18:16Thĩinĩ wa watho wanyu nĩ kwandĩkĩtwo atĩ ũira wa andũ eerĩ nĩ wa ma. 188:18 Joh 5:37Niĩ ndĩraruta ũira wakwa mwene; nake mũira wakwa ũcio ũngĩ nĩ Baba ũrĩa wandũmire.”

198:19 Joh 16:3Ningĩ makĩmũũria atĩrĩ, “Thoguo arĩ kũ?”

Nake Jesũ akĩmacookeria atĩrĩ, “Inyuĩ mũtinjũũĩ, o na Baba mũtimũũĩ. Korwo nĩmũnjũũĩ, o na Baba nĩmũngĩmũũĩ.” 208:20 Mar 12:41; Mar 12:41Nake aaragia ciugo icio akĩrutana hekarũ-inĩ hakuhĩ na harĩa mũhothi warutagĩrwo. No gũtirĩ mũndũ wamũnyiitire nĩ tondũ ihinda rĩake rĩtiarĩ ikinyu.

218:21 Ezek 3:18; Joh 7:34O rĩngĩ Jesũ akĩmeera atĩrĩ, “Nĩngwĩthiĩra, na inyuĩ nĩmũkanjaria no mũgaakua mũrĩ o mehia-inĩ manyu. Kũrĩa ngũthiĩ inyuĩ mũtingĩhota gũũka.”

22Ũhoro ũcio ũgĩtũma Ayahudi morie atĩrĩ, “Kaĩ ekwĩyũraga? Hihi nĩkĩo aroiga atĩ, ‘Kũrĩa ngũthiĩ mũtingĩhota gũũka’?”

238:23 Joh 3:31Nowe akĩmeera atĩrĩ, “Inyuĩ mũrĩ a gũkũ thĩ, niĩ nyumĩte Igũrũ. 24Inyuĩ mũrĩ a thĩ-ĩno; no niĩ ndirĩ wa thĩ-ĩno. Ndamwĩrire atĩ mũgaakua mũrĩ o mehia-inĩ manyu; mũngĩrega gwĩtĩkia ũrĩa njugaga atĩ niĩ nĩ niĩ we, ti-itherũ mũgaakua mũrĩ o mehia-inĩ manyu.”

25Nao makĩmũũria atĩrĩ, “Wee nĩwe ũ.”

Nake Jesũ akĩmeera atĩrĩ, “Niĩ nĩ niĩ o ũrĩa ndũũrĩte ndĩmwĩraga kuuma o kĩambĩrĩria. 268:26 Joh 7:28; Joh 3:32Ndĩ na maũndũ maingĩ ingiuga ma kũmũciirithia namo. No ũrĩa wandũmire nĩ mwĩhokeku, naguo ũrĩa njiguĩte kuuma kũrĩ we nĩguo njĩĩraga kĩrĩndĩ.”

27Nao matiigana kũmenya atĩ aameeraga ũhoro wa Ithe. 288:28 Joh 12:32Nĩ ũndũ ũcio Jesũ akĩmeera atĩrĩ, “Mwarĩkia kwambararia Mũrũ wa Mũndũ-rĩ, nĩguo mũkamenya ũrĩa njugaga atĩ niĩ nĩ niĩ we, na atĩ gũtirĩ ũndũ njĩkaga ndĩĩrĩte, no njaragia o ũrĩa Baba andutĩte. 298:29 Joh 4:34Nake ũrĩa wandũmire arĩ hamwe na niĩ; ndandigĩte ndĩ nyiki, nĩgũkorwo hĩndĩ ciothe njĩkaga maũndũ o marĩa mamũkenagia.” 308:30 Joh 7:31O akĩaragia-rĩ, andũ aingĩ makĩmwĩtĩkia.

Ciana cia Iburahĩmu

31Nake Jesũ akĩĩra Ayahudi arĩa maamwĩtĩkĩtie atĩrĩ, “Mũngĩrũmia ũrutani wakwa-rĩ, mũrĩ arutwo akwa kũna. 328:32 2Akor 3:17Nĩ mũkaamenya ũhoro wa ma, naguo ũhoro ũcio wa ma nĩ ũkaamũkũũra.”

33Nao makĩmũcookeria makĩmwĩra atĩrĩ, “Ithuĩ tũrĩ a rũciaro rwa Iburahĩmu, na tũtirĩ twatuĩka ngombo cia mũndũ o na ũ. Ũngĩkiuga atĩa atĩ nĩtũgakũũrwo?”

348:34 Arom 6:16Nake Jesũ akĩmacookeria atĩrĩ, “Ngũmwĩra atĩrĩ o ma, mũndũ o wothe wĩhagia nĩ ngombo ya mehia. 358:35 Agal 4:30No rĩrĩ, ngombo ti ya gũtũũra mũciĩ nginya tene no mũriũ wa mwene mũciĩ nĩ wa gũtũũra mũciĩ nginya tene. 36Nĩ ũndũ ũcio Mũrũ wa Ngai angĩkamũkũũra-rĩ, nĩmũgakũũrwo kũna. 37Nĩnjũũĩ mũrĩ a rũciaro rwa Iburahĩmu, no nĩmwĩharĩirie kũnjũraga, tondũ ũhoro wakwa ndũrĩ na ũikaro thĩinĩ wanyu. 388:38 Joh 5:19, 30Niĩ ndĩramwĩra maũndũ marĩa nyonete harĩ Baba, na inyuĩ mwĩkaga maũndũ marĩa mũiguĩte kuuma kũrĩ ithe wanyu.”

39Nao makĩmũcookeria atĩrĩ, “Iburahĩmu nĩwe ithe witũ.” Nake Jesũ akĩmeera atĩrĩ,

“Mũngĩrĩ ciana cia Iburahĩmu-rĩ, nĩ mũngĩĩkaga maũndũ marĩa Iburahĩmu eekaga. 408:40 Joh 8:26Ũrĩa kũrĩ nĩ atĩ, inyuĩ nĩmũtuĩte itua rĩa kũnjũraga, o niĩ mũndũ ũrĩa ũmũheete ũhoro ũrĩa wa ma, o ũrĩa ndaiguire kuuma kũrĩ Ngai. Ũguo tiguo Iburahĩmu eekaga. 418:41 Isa 63:16; 64:8Inyuĩ mũreka maũndũ marĩa ithe wanyu ekaga.”

Nao makĩmũkararia makĩmwĩra atĩrĩ, “Ithuĩ tũtirĩ ciana ciumanĩte na ũtharia. Ithuĩ tũrĩ na Baba ũmwe tu, na nĩwe Ngai.”

Ciana cia Mũcukani

428:42 1Joh 5:1; Joh 7:28Jesũ akĩmeera atĩrĩ, “Ngai angĩrĩ Ithe wanyu-rĩ, no mũnyende, nĩgũkorwo ndoimire kũrĩ Ngai, na rĩu ndĩ gũkũ. Ti niĩ mwene ndĩĩtũmĩte, no nĩwe wandũmire. 43Mũraga gũtaũkĩrwo nĩ ũrĩa ndĩroiga nĩkĩ? Tondũ mũtirahota kũmenya ũhoro ũrĩa ndĩraria. 448:44 1Joh 3:8; 2Maũ 18:21Inyuĩ mũrĩ ciana cia ithe wanyu, Mũcukani, na mwendaga kũhingia merirĩria ma ithe wanyu. We aarĩ mũũragani kuuma o kĩambĩrĩria. Ndathingataga ũhoro wa ma, nĩgũkorwo gũtirĩ ũhoro wa ma thĩinĩ wake. Rĩrĩa ekũheenania, aaragia rũthiomi rwake, tondũ we nĩ mũheenania, na nĩwe ithe wa maheeni. 45No tondũ njaragia ũhoro wa ma-rĩ, mũtinjĩtĩkagia. 46Nĩ kũrĩ mũndũ ũmwe wanyu ũngĩonania atĩ ndĩ mwĩhia? Angĩkorwo ndĩraria ũhoro wa ma-rĩ, mũregaga kũnjĩtĩkia nĩkĩ? 47Ũrĩa ũrĩ wa Ngai nĩaiguaga ũrĩa Ngai oigaga. Kĩrĩa kĩgiragia mũmũigue nĩ tondũ mũtirĩ a Ngai.”

Uuge wa Jesũ Igũrũ Rĩake we Mwene

488:48 Math 10:5; Mar 3:22Nao Ayahudi makĩmũcookeria atĩrĩ, “Githĩ tũtirĩ na kĩhooto gĩa kuuga atĩ wee ũrĩ Mũsamaria na ũrĩ na ndaimono?”

49Nake Jesũ akĩmeera atĩrĩ, “Niĩ ndirĩ na ndaimono, no nĩndĩĩte Baba, no inyuĩ mũtindĩĩte. 508:50 Joh 5:41Ndirecarĩria ũgooci wakwa niĩ mwene, no nĩ harĩ na ũmwe ũrĩa ũũcaragia, na nĩwe mũtuanĩri ciira. 51Ngũmwĩra atĩrĩ na ma, mũndũ o wothe angĩrũmia kiugo gĩakwa, ndarĩ hĩndĩ akona gĩkuũ.”

52Ayahudi maigua ũguo, makĩgũthũka makĩmwĩra atĩrĩ, “Rĩu nĩtwamenya atĩ ũrĩ na ndaimono. Iburahĩmu nĩakuire o na anabii magĩkua, no wee ũroiga atĩ mũndũ o wothe angĩrũmia kiugo gĩaku, ndagacama gĩkuũ. 538:53 Joh 8:39Wee ũkĩrĩ mũnene gũkĩra ithe witũ Iburahĩmu? We nĩakuire o na anabii magĩkua. Kaĩ ũreciiria we ũrĩ ũ?”

54Nake Jesũ akĩmacookeria atĩrĩ, “Ingĩĩgooca-rĩ, kwĩgooca gwakwa nĩ gwa tũhũ. Baba, ũrĩa muugaga atĩ nĩwe Ngai wanyu nĩwe ũngoocithagia. 558:55 Joh 7:28, 29O na gũtuĩka mũtimũũĩ, niĩ nĩndĩmũũĩ. Ingiuga atĩ ndimũũĩ, ingĩtuĩka wa maheeni ta inyuĩ, no nĩndĩmũũĩ na nĩnũmĩtie kiugo gĩake. 56Ithe wanyu Iburahĩmu nĩakenaga atĩ nĩakona mũthenya wakwa; na nĩawonire na agĩcanjamũka.”

57Nao Ayahudi makĩmwĩra atĩrĩ, “Wee o na ndũkinyĩtie mĩaka mĩrongo ĩtano, na ũkoiga atĩ nĩwonete Iburahĩmu!”

588:58 Joh 1:2; Thaam 3:14Nake Jesũ akĩmacookeria atĩrĩ, “Ngũmwĩra atĩrĩ na ma, Iburahĩmu atanaciarwo, Niĩ ndũire!” 598:59 Thaam 17:4; Joh 10:31; 11:8Maigua ũguo makĩoya mahiga mamũhũũre namo nyuguto, no Jesũ akĩĩhitha, akiuma kũu hekarũ-inĩ.