Jesu kọ́ Nikodemu
13.1: Jh 7.50; 19.39; Lk 23.13; Jh 7.26.Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisi, tí a ń pè ní Nikodemu, ìjòyè kan láàrín àwọn Júù: 23.2: Jh 2.11; 7.31; 9.16; Ap 10.38.Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
33.3: Jh 1.13; 1Pt 1.23; Jk 1.18; 1Jh 3.9.Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”
4Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?
53.5: El 36.25-27; Ef 5.26; Tt 3.5.Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. 63.6: 1Kọ 15.50.Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti Ẹ̀mí ni. 7Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’ 83.8: El 37.9.Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”
9Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”
10Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? 113.11: Jh 8.26; 1.18; 3.32.Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 133.13: Ro 10.6; Ef 4.9.Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 143.14: Nu 21.9; Jh 8.28; 12.34.Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú: 15Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
163.16: Ro 5.8; 8.32; Ef 2.4; 1Jh 4.9-10.“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 173.17: Jh 8.15; 12.47; Lk 19.10; 1Jh 4.14.Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là. 18Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́. 193.19: Jh 1.4; 8.12; Ef 5.11,13.Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. 20Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí. 213.21: 1Jh 1.6.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”
Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu
223.22: Jh 4.2.Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 243.24: Mk 1.14; 6.17-18.Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú. 25Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 263.26: Jh 1.7,28.Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”
273.27: 1Kọ 4.7.Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 283.28: Jh 1.20,23.Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 293.29: Mk 2.19-20; Mt 25.1; Jh 15.11.Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.
313.31: Jh 3.13; 8.23; 1Jh 4.5.“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 323.32: Jh 3.11.Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ 363.36: Jh 3.16; 5.24.Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”
دیدار عیسی و نیقودیموس
1در این میان، مردی بود از گروه فریسیان به نام نیقودیموس، که یکی از اعضای شورای عالی یهود بود. 2او شبی نزد عیسی آمد و گفت: «استاد، ما روحانیون این شهر، همه میدانیم که تو از طرف خدا آمدهای تا ما را تعلیم دهی. نشانههای معجزهآسایت گواه بر این است که خدا با توست.»
3عیسی جواب داد: «براستی به تو میگویم، اگر تولدی تازه پیدا نکنی، هرگز نمیتوانی ملکوت خدا را ببینی.»
4نیقودیموس با تعجب گفت: «منظورت از تولد تازه چیست؟ چگونه امکان دارد پیرمردی مثل من، به شکم مادرش بازگردد و دوباره متولد شود؟»
5عیسی جواب داد: «آنچه میگویم عین حقیقت است. تا کسی از آب و روح تولد نیابد، نمیتواند وارد ملکوت خدا شود. 6زندگی جسمانی را انسان تولید میکند، ولی زندگی روحانی را روح خدا از بالا میبخشد. 7پس تعجب نکن که گفتم باید تولد تازه پیدا کنی. 8درست همانگونه که صدای باد را میشنوی ولی نمیتوانی بگویی از کجا میآید و به کجا میرود، در مورد تولد تازه نیز انسان نمیتواند پی ببرد که روح خدا آن را چگونه عطا میکند.»
9نیقودیموس پرسید: «منظورت چیست؟ من سخنانت را به درستی درک نمیکنم.»
10عیسی جواب داد: «نیقودیموس، تو از علمای دینی اسرائیل هستی؛ چگونه این چیزها را درک نمیکنی؟ 11براستی به تو میگویم که ما آنچه را که میدانیم و دیدهایم میگوییم ولی شما نمیتوانید باور کنید. 12من از امور این دنیا با شما سخن میگویم و شما باور نمیکنید. پس اگر از امور آسمان با شما صحبت کنم چگونه باور خواهید کرد؟ 13چون هیچکس تا به حال به آسمان بالا نرفته که از آنجا برگشته باشد. اما پسر انسان از آسمان به این جهان آمده است. 14همانگونه که موسی در بیابان مجسمهای برنزی از مار را بر بالای چوبی بلند کرد، پسر انسان نیز باید بلند کرده شود، 15تا هر که به او ایمان آوَرَد، حیات جاویدان یابد. 16زیرا خدا به قدری مردم جهان را دوست دارد که یگانه پسر خود را فرستاده است، تا هر که به او ایمان آورد، هلاک نشود بلکه زندگی جاوید بیابد. 17خدا پسر خود را به جهان نفرستاد تا مردمان را محکوم سازد، بلکه تا جهان را بهوسیلهٔ او نجات بخشد.
18«کسانی که به او ایمان بیاورند، هیچ نوع محکومیت و هلاکتی در انتظارشان نیست؛ ولی کسانی که به او ایمان نیاورند، از هم اکنون محکومند، چون به یگانه پسر خدا ایمان نیاوردهاند. 19محکومیت بیایمانان به این دلیل است که نور از آسمان به این جهان آمد ولی مردم تاریکی را بیشتر از نور دوست داشتند، چون اعمال و رفتارشان بد است. 20مردم از نور آسمانی نفرت دارند، چون میخواهند در تاریکی، گناه ورزند؛ پس به نور نزدیک نمیشوند، مبادا کارهای گناهآلودشان دیده شود و به سزای اعمالشان برسند. 21ولی درستکاران با شادی به سوی نور میآیند تا همه ببینند که آنچه میکنند، پسندیدهٔ خداست.»
عیسی و یحیی
22پس از آن، عیسی و شاگردانش اورشلیم را ترک گفتند. او مدتی در ناحیۀ یهودیه با اهالی آنجا به سر برد و ایشان را تعمید میداد. 23یحیی در این هنگام نزدیک سالیم در محلی به نام عینون مردم را تعمید میداد، چون در آنجا آب زیاد بود و مردم برای تعمید نزد وی میآمدند. 24این پیش از آن بود که یحیی به زندان بیفتد.
25روزی، میان یکی از یهودیان و شاگردان یحیی بر سر آیین تطهیر بحثی درگرفت. 26شاگردان یحیی نزد او آمدند و گفتند: «استاد، آن شخصی که آن طرف رود اردن بود و گفتی که مسیح است، اکنون او نیز مردم را تعمید میدهد و همه نزد او میروند، در صورتی که باید پیش ما بیایند.»
27یحیی جواب داد: «کسی نمیتواند چیزی دریافت کند، مگر آنچه که از آسمان به او عطا شود. 28کار من این است که راه را برای مسیح باز کنم تا مردم همه نزد او بروند. شما خود شاهدید که من صریحاً گفتم که مسیح نیستم، بلکه آمدهام تا راه را برای او باز کنم. 29در یک عروسی، عروس پیش داماد میرود و دوست داماد در شادی او شریک میشود. من نیز دوست دامادم و از خوشی داماد خوشحالم. 30او باید روزبهروز بزرگتر شود و من کوچکتر.
31«او از آسمان آمده و مقامش از همه بالاتر است. من از این زمین هستم و فقط امور زمینی را درک میکنم. 32او آنچه را که دیده و شنیده است بیان میکند، ولی عدهٔ کمی سخنان او را باور میکنند. 33کسی که سخنان او را باور میکند، تأیید میکند که خدا حقیقت است، 34زیرا او از جانب خدا فرستاده شده است. او کلام خدا را بیان میکند، چرا که خدا روح خود را بدون حد و حصر به او میبخشد. 35پدر آسمانی ما او را دوست میدارد، و همه چیز را به دست او سپرده است. 36هر که به پسر خدا ایمان بیاورد، حیات جاویدان دارد. اما هر که از پسر خدا اطاعت نکند، هرگز حیات جاویدان را تجربه نخواهد کرد، بلکه خشم خدا بر او باقی میماند.»