Johanu 20 – YCB & LB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 20:1-31

Òfo ibojì

120.1-10: Mt 28.1-8; Mk 16.1-8; Lk 24.1-10.Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì. 2Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

320.3-10: Lk 24.11-12.Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. 4Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. 5Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. 6Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. 7Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀. 8Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. 920.9: Lk 24.26,46.(Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú). 10Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

Jesu fi ara han Maria Magdalene

11Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. 1220.12: Lk 24.4; Mt 28.5; Mk 16.5.Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí.

1320.13: Jh 20.2.Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” 1420.14: Mt 28.9; Jh 21.4.Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni.

15Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”

Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.”

16Jesu wí fún un pé, “Maria!”

Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”).

1720.17: Jh 20.27; Mt 28.10; Jh 7.33.Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi. Ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín, àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”

1820.18: Lk 24.10,23.Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.

Jesu fi ara han àwọn Aposteli

1920.19-20: Lk 24.36-39.Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” 20Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

2120.21: Jh 17.18; Mt 28.19.Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.” 2220.22: Ap 2.4,33.Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́! 2320.23: Mt 16.19; 18.18.Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.”

Jesu fi ara han Tomasi

2420.24: Jh 11.16.Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé. 25Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”

Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

26Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.” 2720.27: Lk 24.40.Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

28Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”

2920.29: 1Pt 1.8.Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́, alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”

3020.30: Jh 21.25.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí. 3120.31: Jh 3.15.Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

En Levende Bok

Johannes 20:1-31

Jesus står opp fra de døde

1Tidlig på søndag morgenen, som er dagen etter hviledagen, mens det ennå var mørkt, kom Maria Magdalena til graven og oppdaget at steinen var rullet bort fra inngangen.

2Hun sprang da straks fra stedet og begynte å lete etter Simon Peter og den disippelen som Jesus elsket20:2 Hvilken disippel Johannes siktet til, blir avslørt i 21:20-24. og sa: ”De har flyttet Herren Jesus fra graven, og vi vet ikke hvor de har lagt ham.”

3-4Peter og den andre disippelen sprang av sted til graven for å se etter. Den andre disippelen sprang fortere enn Peter og kom først fram. 5Han bøyde seg ned og så inn i graven. Der så han lintøyet ligge, men han gikk ikke inn. 6Litt etter kom Simon Peter, og han gikk inn i graven. Han så også lintøyet som lå der. 7I tillegg lå også det svøpet som hadde dekket hodet på den døde. Det var rullet sammen og lå for seg selv. 8Da gikk også den andre disippelen inn, han som hadde kommet først til graven. Han så og trodde. 9Før dette hadde de ikke skjønt det Gud hadde forutsagt i Skriften20:9 ”Skriften” for jødene er Bibelens første del, den som vi kaller Det gamle testamente. om at Jesus måtte dø og så bli levende igjen.

Jesus viser seg for Maria Magdalena

10Etterpå gikk de to disiplene hjem. 11Men Maria sto og gråt utenfor graven. Hun bøyde seg framover og så inn i graven. 12Da fikk hun se to hvitkledde engler som satt der kroppen til Jesus hadde ligget. En ved hodeplassen og en ved fotenden.

13Englene spurte henne: ”Hvorfor gråter du?”

Hun svarte: ”De har tatt bort Herren min. Nå vet jeg ikke hvor de har lagt ham.”

14Da hun hadde sagt dette, så hun seg om og fikk øye på en som sto der, men at det var Jesus skjønte hun ikke.

15Jesus spurte henne: ”Hvorfor gråter du? Hvem leter du etter?” Hun trodde det var gartneren og svarte: ”Dersom det er du som har båret ham bort, da si meg hvor du har lagt ham, slik at jeg kan hente ham.”

16Jesus sa til henne: ”Maria.” Straks vendte hun seg mot ham og utbrøt: ”Rabbuni!” Det er arameisk20:16 Eller: hebraisk, det vil si hebreerne eller jødenes språk. Men hverdagens språk for Israels folk var arameisk. og betyr mester.

17Jesus sa: ”Ikke rør meg, for jeg har ennå ikke vendt tilbake til min Far i himmelen. Men gå til brødrene mine og si at jeg skal vende tilbake til min Far i himmelen og deres Far i himmelen, til min Gud og deres Gud.”

18Maria Magdalena gikk da til disiplene og fortalte at hun hadde sett Herren Jesus, og hun fortalte alt han hadde sagt.

Jesus viser seg for disiplene

19Dette skjedde på søndagen, som er den første dagen i uken. Samme kvelden samlet disiplene seg bak låste dører av frykt for de religiøse lederne. Plutselig sto Jesus midt iblant dem og sa: ”Fred være med dere alle!” 20Så viste han hendene sine og siden sin. Gleden gikk ut over alle grenser da disiplene fikk se Herren Jesus.

21Jesus sa igjen: ”Fred være med dere! På samme måten som min Far i himmelen har sendt meg, sender jeg nå dere.” 22Så pustet han på dem og sa: ”Ta imot Guds Hellige Ånd.20:22 Ånd, åndedrett og vind er samme ordet på gresk. Jesus sitt åndedrett ble derfor symbol for Guds Ånd. 23Jeg gir dere i oppdrag å fortelle alle mennesker at Gud har tilgitt syndene deres, men også å fortelle med dypt alvor at det går an å stelle seg slik at de ikke får noen tilgivelse.20:23 Deres oppdrag var å forkynne for menneskene slik at den som aksepterte frelsen Jesus gir, skulle få tilgivelse for syndene sine, mens de andre ikke ble tilgitt.

Jesus viser seg for Tomas

24En av disiplene, han som het Tomas og ble kalt Tvillingen, hadde ikke vært sammen med de andre da Jesus kom. 25Disiplene sa til ham: ”Vi har sett Herren Jesus.” Men Tomas svarte: ”Dersom jeg ikke får se skaden etter spikrene i hendene hans og får ta på sårene med fingrene mine, og om jeg ikke får røre ved såret i siden hans med hendene mine, da kan jeg ikke tro.”

26Neste søndag20:26 På gresk: åtte dager senere. I det greske språket, og på mange andre språk, regner de den dagen noe skjer, som dag nummer en. Jesus hadde stått opp på en søndag, og nå var det søndag igjen. var disiplene igjen samlet. Denne gangen var Tomas sammen med de andre. Til tross for at dørene var låste, sto Jesus plutselig midt iblant dem og sa: ”Fred være med dere!” 27Han sa til Tomas: ”Her er hendene mine. Ta på sårene med fingrene dine. Se, her er siden min. Ta på såret med hendene dine. Ikke tvil lenger, men tro!”

28Da utbrøt Tomas: ”Min Herre og min Gud.”

29Jesus sa til ham: ”Nå tror du fordi du har sett meg. Lykkelige er dem som ikke har sett meg, men likevel tror.”

Hensikten med denne boken

30Disiplene fikk se Jesus gjøre mange andre mirakler i tillegg til dem som er skrevet ned i denne boken. 31De som står her, er skrevet ned for at dere skal tro at Jesus er Messias, den lovede kongen og Guds sønn, og for at dere skal få liv i ham ved å tro på ham.