Johanu 12 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 12:1-50

A fi àmì òróró yàn Jesu ni Betani

112.1-8: Mt 26.6-13; Mk 14.3-9; Lk 7.37-38.Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òsùwọ̀n lita kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.

412.4: Jh 6.71; 13.26.Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 5“Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 612.6: Lk 8.3.Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.

712.7: Jh 19.40.Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. 8Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”

9Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú. 1012.10: Mk 14.1.Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú, 11nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.

Jesu gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalẹmu

1212.12-15: Mt 21.4-9; Mk 11.7-10; Lk 19.35-38.Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. 1312.13: Sm 118.25; Jh 1.49.Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,

“Hosana!”

“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Olùbùkún ni ọba Israẹli!”

14Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

1512.15: Sk 9.9.“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni;

wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,

o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

1612.16: Mk 9.32; Jh 2.22.Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

17Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. 18Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí. 19Nítorí náà àwọn Farisi wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

Jesu sọ nípa ikú rẹ̀

2012.20: Jh 7.35; Ap 11.20.Àwọn Giriki kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ, 2112.21: Jh 1.44; 6.5.Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Filipi wá, ẹni tí í ṣe ará Betisaida tí Galili, wọ́n sì ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jesu!” 22Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu.

2312.23: Jh 13.1; 17.1; Mk 14.35,41.Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ Ènìyàn lógo. 2412.24: 1Kọ 15.36.Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 2512.25: Mt 10.39; Mk 8.35; Lk 9.24; 14.26.Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. 26Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn, àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.

2712.27: Jh 11.33; Mt 26.38; Mk 14.34.“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí. 2812.28: Mk 1.11; 9.7.Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”

Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!” 29Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, “Àrá ń sán.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”

30Jesu sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín. 3112.31: Jh 16.11; 2Kọ 4.4; Ef 2.2.Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde. 3212.32: Jh 3.14; 8.28.Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé, èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!” 33Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.

3412.34: Sm 110.4; Isa 9.7; El 37.25; Da 7.14.Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé, ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé Ọmọ Ènìyàn sókè’? Ta ni ó ń jẹ́ ‘Ọmọ Ènìyàn yìí’?”

3512.35: Jh 7.33; 9.4; Ef 5.8; 1Jh 2.11.Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàrín yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín, ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun ń lọ. 3612.36: Lk 16.8; Jh 8.59.Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.

Àwọn Júù n tẹ̀síwájú nínú àìgbàgbọ́

37Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. 3812.38: Isa 53.1; Ro 10.16.Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé,

“Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́

Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

39Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé,

4012.40: Isa 6.10; Mt 13.14.“Ó ti fọ́ wọn lójú,

Ó sì ti sé àyà wọn le;

kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,

kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,

kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

4112.41: Isa 6.1; Lk 24.27.Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

4212.42: Jh 9.22; Lk 6.22.Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu, 43nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.

4412.44: Mt 10.40; Jh 5.24.Jesu sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi. 4512.45: Jh 14.9.Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. 4612.46: Jh 1.4; 8.12; 9.5.Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.

4712.47: Jh 3.17.“Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là. 4812.48: Mt 10.14-15.Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí. 50Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀, nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”

New International Version

John 12:1-50

Jesus Anointed at Bethany

1Six days before the Passover, Jesus came to Bethany, where Lazarus lived, whom Jesus had raised from the dead. 2Here a dinner was given in Jesus’ honor. Martha served, while Lazarus was among those reclining at the table with him. 3Then Mary took about a pint12:3 Or about 0.5 liter of pure nard, an expensive perfume; she poured it on Jesus’ feet and wiped his feet with her hair. And the house was filled with the fragrance of the perfume.

4But one of his disciples, Judas Iscariot, who was later to betray him, objected, 5“Why wasn’t this perfume sold and the money given to the poor? It was worth a year’s wages.12:5 Greek three hundred denarii6He did not say this because he cared about the poor but because he was a thief; as keeper of the money bag, he used to help himself to what was put into it.

7“Leave her alone,” Jesus replied. “It was intended that she should save this perfume for the day of my burial. 8You will always have the poor among you,12:8 See Deut. 15:11. but you will not always have me.”

9Meanwhile a large crowd of Jews found out that Jesus was there and came, not only because of him but also to see Lazarus, whom he had raised from the dead. 10So the chief priests made plans to kill Lazarus as well, 11for on account of him many of the Jews were going over to Jesus and believing in him.

Jesus Comes to Jerusalem as King

12The next day the great crowd that had come for the festival heard that Jesus was on his way to Jerusalem. 13They took palm branches and went out to meet him, shouting,

“Hosanna!12:13 A Hebrew expression meaning “Save!” which became an exclamation of praise

“Blessed is he who comes in the name of the Lord!”12:13 Psalm 118:25,26

“Blessed is the king of Israel!”

14Jesus found a young donkey and sat on it, as it is written:

15“Do not be afraid, Daughter Zion;

see, your king is coming,

seated on a donkey’s colt.”12:15 Zech. 9:9

16At first his disciples did not understand all this. Only after Jesus was glorified did they realize that these things had been written about him and that these things had been done to him.

17Now the crowd that was with him when he called Lazarus from the tomb and raised him from the dead continued to spread the word. 18Many people, because they had heard that he had performed this sign, went out to meet him. 19So the Pharisees said to one another, “See, this is getting us nowhere. Look how the whole world has gone after him!”

Jesus Predicts His Death

20Now there were some Greeks among those who went up to worship at the festival. 21They came to Philip, who was from Bethsaida in Galilee, with a request. “Sir,” they said, “we would like to see Jesus.” 22Philip went to tell Andrew; Andrew and Philip in turn told Jesus.

23Jesus replied, “The hour has come for the Son of Man to be glorified. 24Very truly I tell you, unless a kernel of wheat falls to the ground and dies, it remains only a single seed. But if it dies, it produces many seeds. 25Anyone who loves their life will lose it, while anyone who hates their life in this world will keep it for eternal life. 26Whoever serves me must follow me; and where I am, my servant also will be. My Father will honor the one who serves me.

27“Now my soul is troubled, and what shall I say? ‘Father, save me from this hour’? No, it was for this very reason I came to this hour. 28Father, glorify your name!”

Then a voice came from heaven, “I have glorified it, and will glorify it again.” 29The crowd that was there and heard it said it had thundered; others said an angel had spoken to him.

30Jesus said, “This voice was for your benefit, not mine. 31Now is the time for judgment on this world; now the prince of this world will be driven out. 32And I, when I am lifted up12:32 The Greek for lifted up also means exalted. from the earth, will draw all people to myself.” 33He said this to show the kind of death he was going to die.

34The crowd spoke up, “We have heard from the Law that the Messiah will remain forever, so how can you say, ‘The Son of Man must be lifted up’? Who is this ‘Son of Man’?”

35Then Jesus told them, “You are going to have the light just a little while longer. Walk while you have the light, before darkness overtakes you. Whoever walks in the dark does not know where they are going. 36Believe in the light while you have the light, so that you may become children of light.” When he had finished speaking, Jesus left and hid himself from them.

Belief and Unbelief Among the Jews

37Even after Jesus had performed so many signs in their presence, they still would not believe in him. 38This was to fulfill the word of Isaiah the prophet:

“Lord, who has believed our message

and to whom has the arm of the Lord been revealed?”12:38 Isaiah 53:1

39For this reason they could not believe, because, as Isaiah says elsewhere:

40“He has blinded their eyes

and hardened their hearts,

so they can neither see with their eyes,

nor understand with their hearts,

nor turn—and I would heal them.”12:40 Isaiah 6:10

41Isaiah said this because he saw Jesus’ glory and spoke about him.

42Yet at the same time many even among the leaders believed in him. But because of the Pharisees they would not openly acknowledge their faith for fear they would be put out of the synagogue; 43for they loved human praise more than praise from God.

44Then Jesus cried out, “Whoever believes in me does not believe in me only, but in the one who sent me. 45The one who looks at me is seeing the one who sent me. 46I have come into the world as a light, so that no one who believes in me should stay in darkness.

47“If anyone hears my words but does not keep them, I do not judge that person. For I did not come to judge the world, but to save the world. 48There is a judge for the one who rejects me and does not accept my words; the very words I have spoken will condemn them at the last day. 49For I did not speak on my own, but the Father who sent me commanded me to say all that I have spoken. 50I know that his command leads to eternal life. So whatever I say is just what the Father has told me to say.”