Jobu 7 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 7:1-21

Jobu ha ni ìrètí bí?

1“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀?

Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?

2Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji,

àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.

3Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù,

òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.

4Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’

Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.

5Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ,

awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.

6“Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ,

o sì di lílò ní àìní ìrètí.

7Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;

ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.

8Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;

ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.

9Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ,

bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.

10Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

11“Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,

èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,

èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.

12Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú,

tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?

13Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára,

ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.

14Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi,

ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí.

15Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa

àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.

16O sú mi, èmi kò le wà títí:

jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

177.17: Sm 8.4.“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?

Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?

18Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,

ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkígbà!

19Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,

tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.

20Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ.

Ìwọ Olùsójú ènìyàn?

Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe àmì itasi níwájú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ?

21Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn,

kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò?

Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀,

ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

约伯记 7:1-21

1“人生在世岂不像服劳役吗?

他有生之年岂不像个雇工吗?

2他像切望阴凉的奴隶,

又如盼望报酬的雇工。

3同样,我注定要度过虚空的岁月,

熬过悲惨的黑夜。

4我躺在床上,想着何时起来。

长夜漫漫,我辗转难眠,直到拂晓。

5我身上布满蛆虫、伤疤,

皮肤破裂,流脓不止。

6我的年日飞逝,比梭还快,

转眼结束,毫无盼望。

7“上帝啊,别忘了我的生命不过是一口气,

我再也看不见幸福。

8注视我的眼睛将再也看不见我,

你将寻找我,而我已不复存在。

9人死后一去不返,

就像烟消云散;

10他永不再返回家园,

故土也不再认识他。

11“因此我不再缄默不语,

我要吐露胸中的悲愁,

倾诉心里的苦楚。

12上帝啊,我岂是大海,岂是海怪,

值得你这样防范我?

13我以为床铺是我的安慰,

卧榻可解除我的哀愁,

14你却用噩梦惊我,

用异象吓我,

15以致我宁愿窒息而死,

也不愿这样活着。

16我厌恶生命,不想永活。

不要管我,因为我的日子都是虚空。

17“人算什么,你竟这样看重他,

这样关注他?

18你天天早上察看他,

时时刻刻考验他。

19你的视线何时离开我,

给我咽口唾沫的时间?

20鉴察世人的主啊,

我若犯了罪,又于你何妨?

为何把我当成你的箭靶?

难道我成了你的重担?

21为何不赦免我的过犯,

饶恕我的罪恶?

我很快将归于尘土,

你将寻找我,

而我已不复存在。”