Jobu 42 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 42:1-17

Ìrònúpìwàdà Jobu

1Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé,

2“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,

àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

3Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?

Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,

ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

4“Ìwọ wí pé, ‘Gbọ́ tèmi báyìí,

èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,

ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’

5Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,

ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.

6Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,

mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”

Ọlọ́run bùkún Jobu

7Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ. 8Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe. 9Bẹ́ẹ̀ ní Elifasi, ara Temani, àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Olúwa sì gbọ́ àdúrà Jobu.

10Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí. 11Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a. Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.

12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 13Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 14Ó sì sọ orúkọ àkọ́bí ní Jemima, àti orúkọ èkejì ni Kesia àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kereni-Happuki. 15Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.

16Lẹ́yìn èyí Jobu wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin. 17Bẹ́ẹ̀ ni Jobu kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Аюб 42:1-17

Раскаяние Аюба

1Тогда Аюб ответил Вечному:

2– Я знаю: Ты можешь всё,

и невозможно противиться Тебе.

3Ты спросил:

«Кто этот невежда, омрачающий Мой замысел?»

Да, я говорил о том, чего не понимал,

о делах для меня чудесных, которых я не знал.

4Ты сказал:

«Внимай Мне, и Я буду говорить;

Я буду спрашивать, а ты отвечай».

5Я только слышал о Тебе,

а теперь мои глаза видят Тебя.

6Поэтому я отступаю

и раскаиваюсь в прахе и пепле.

Эпилог

7Сказав это Аюбу, Вечный обратился к Елифазу из Темана:

– Я разгневан на тебя и на двух твоих друзей за то, что вы говорили обо Мне не так верно, как Мой раб Аюб. 8Поэтому возьмите семь молодых быков и семь баранов, пойдите к Моему рабу Аюбу и принесите за себя жертву всесожжения. Мой раб Аюб помолится за вас, и Я приму его молитву и не поступлю с вами по вашей глупости. Вы говорили обо Мне не так верно, как Мой раб Аюб.

9Елифаз из Темана, Билдад из Шуаха и Цофар из Наамы сделали, как велел им Вечный. И Вечный принял молитву Аюба.

10После того как Аюб помолился за своих друзей, Вечный вернул ему благополучие и дал ему вдвое больше того, что было у него прежде. 11Все его братья и сёстры и все, кто знал его прежде, пришли и ели с ним у него в доме. Они жалели и утешали его за все испытания, которые послал ему Вечный. Каждый из них дал ему по мере серебра42:11 Букв.: «по кесите». Кесита – древняя денежная единица, вес и достоинство которой неизвестны. Довольно большой участок земли можно было купить за 100 кесит (см. Нач. 33:19). и по золотому кольцу.

12А Вечный благословил последующие дни Аюба больше, нежели прежние. У него теперь было тринадцать тысяч овец, шесть тысяч верблюдов, тысяча пар волов и тысяча ослиц. 13Ещё у него было семеро сыновей и три дочери. 14Первую он назвал Иемима, вторую Кеция, а третью Керен-Гаппух42:14 Иемима, Кеция и Керен-Гаппух – эти имена, переводимые как «голубка», «цветок корицы» и «рожок для косметики», отражают внешние и душевные достоинства дочерей Аюба.. 15Нигде на земле не было женщин столь прекрасных, как дочери Аюба. Их отец дал им наследство наравне с братьями.

16После этого Аюб прожил ещё сто сорок лет. Он видел своих потомков до четвёртого поколения. 17И умер он в старости, насытившись жизнью.