Jobu 37 – YCB & AKCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 37:1-24

Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí

1“Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,

ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.

2Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,

àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.

3Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,

mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.

4Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;

ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.

Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,

nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.

5Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;

ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.

6Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’

àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’

7Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,

ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.

8Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,

wọn a sì wà ni ipò wọn.

9Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,

àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.

10Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,

ibú omi á sì súnkì.

11Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,

a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.

12Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,

kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun

tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.

13Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,

tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14“Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;

dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.

15Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,

tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?

16Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,

iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?

17Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,

nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.

18Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,

tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?

19“Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;

nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.

20A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?

Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?

21Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí

oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,

ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.

22Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;

lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.

23Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;

nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.

24Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,

òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”

Akuapem Twi Contemporary Bible

Hiob 37:1-24

1“Eyi ma me koma bɔ kitirikitiri

na ehuruw fi nʼatenae.

2Tie! Tie ne nne mmubomu,

ne huuyɛ a efi nʼanom reba no.

3Ogyaa nʼanyinam mu wɔ ɔsoro ase nyinaa

na ɔma ekodu asase ano.

4Ɛno akyi na ne mmubomu no ba;

ɔde nne kɛse bobɔ mu.

Sɛ ɔkasa a,

biribiara nsianka no.

5Onyankopɔn nne bobɔ mu ma no yɛ nwonwa;

ɔyɛ nneɛma akɛse a ɛboro yɛn adwene so.

6Ɔka kyerɛ sukyerɛmma se, ‘Tɔ gu asase so,’

ne osu nso se, ‘Yɛ osutɔ kɛse.’

7Sɛnea nnipa a wabɔ wɔn nyinaa behu nʼadwuma nti,

ɔma nnipa nyinaa gyae wɔn adwumayɛ.

8Wuram mmoa kɔtetɛw;

wɔkɔhyehyɛ wɔn abon mu.

9Ahum tu fi ne pia mu,

na awɔw nso fi mframa a ɛrebɔ mu.

10Onyankopɔn home de sukyerɛmma ba,

na nsu tamaa no kyen.

11Ɔde fuonwini hyɛ omununkum ma;

na otwa nʼanyinam fa mu.

12Ɔhyɛ ma wokyinkyin

fa asase so nyinaa hyia

yɛ nea ɔhyɛ sɛ wɔnyɛ biara.

13Ɔde omununkum ba bɛtwe nnipa aso,

anaasɛ ɔma ɛtɔ gu asase so de kyerɛ nʼadɔe.

14“Tie eyi, Hiob;

gyae na dwene Onyankopɔn anwonwade ho.

15Wunim sɛnea Onyankopɔn si fa di omununkum so,

na ɔma nʼanyinam twa?

16Wunim sɛnea omununkum si fa sensɛn wim,

nea ɔwɔ nimdeɛ a so nni no anwonwade no?

17Mo a mufi fifiri wɔ mo ntade mu

bere a anafo mframa ma asase no yɛ dinn no,

18wubetumi aboa no ama watrɛw wim,

a ɛyɛ den sɛ kɔbere mfrafrae ahwehwɛ?

19“Kyerɛ yɛn nea ɛsɛ sɛ yɛka kyerɛ no;

yɛrentumi nka yɛn asɛm, efisɛ yennim.

20Ɛsɛ sɛ wɔka nea mepɛ sɛ meka kyerɛ no ana?

Onipa bi wɔ hɔ a ɔbɛpɛ sɛ wɔbɛmene no ana?

21Obiara rentumi nhwɛ owia,

sɛnea ɛhyerɛn wɔ wim

bere a mframa abɔ ama wim atew.

22Ofi atifi fam ba wɔ anuonyam sononko mu;

Onyankopɔn ba wɔ ahenni nwonwaso mu.

23Otumfo no korɔn wɔ yɛn so na wɔpagyaw no wɔ tumi mu;

nʼatɛntrenee ne treneeyɛ kɛse akyi no mpo, ɔnyɛ nhyɛso.

24Ɛno nti nnipa de nidi ma no,

efisɛ onnwen koma mu anyansafo nyinaa ho ana?”