Jobu 23 – YCB & HTB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 23:1-17

Èsì Jobu

1Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé,

2“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;

ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.

3Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá

Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!

4Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,

ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.

5Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn;

òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.

6Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?

Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.

7Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,

níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.

8“Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú,

òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀.

9Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i,

ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.

10Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,

nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.

11Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀;

ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.

12Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀,

èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.

13“Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?

Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.

14Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;

ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.

15Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;

nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.

16Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,

Olódùmarè sì ń dààmú mi.

17Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,

bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.

Het Boek

Job 23:1-17

1Job antwoordde, en sprak: 2Al weer heet mijn klagen verzet: Maar zijn hand dwingt mij tot zuchten! 3Ach, dat ik Hem vinden kon, En voor zijn troon kon verschijnen! 4Dan zette ik Hem mijn zaak uiteen, En vulde mijn mond met bewijzen; 5Dan kende ik de woorden, waarmee Hij mij antwoordt, Vernam ik, wat Hij mij zegt. 6Zou Hij zijn macht in het geding moeten brengen? Neen, als Hij slechts naar mij hoorde! 7Dan zou Hij bemerken dat er bij Hem een onschuldige pleit, En ik was voorgoed van mijn Rechter bevrijd! 8Maar ga ik naar het oosten, Hij is er niet, Of naar het westen, ik bespeur Hem niet; 9Ik zoek Hem ten noorden, ik vind Hem niet, Wend mij naar het zuiden, ik zie Hem niet. 10Het is, omdat Hij mijn wandel kent Omdat ik als goud te voorschijn zou treden, als Hij mij toetst: 11Want mijn voet bleef steeds in zijn spoor, Ik hield zijn pad, en verliet het nooit! 12Van het bevel zijner lippen week ik niet af, Het woord van zijn mond heb ik in mijn boezem bewaard: 13Maar wil Hij iets, wie kan Hem beletten, Begeert Hij iets, Hij voert het uit! 14Ja, Hij volbrengt, wat Hij over mij heeft besloten, Met al het andere, wat Hij heeft beschikt: 15En daarom ben ik voor Hem zo bang, Sidder ik, als ik aan Hem denk. 16Het is God, die mijn hart murw heeft geslagen, De Almachtige, die mij verschrikt; 17Neen, niet door de duisternis ben ik ontsteld Niet door het donker, dat mijn gelaat bedekt!