Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé Jobu
1Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú. 2A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. 3Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
4Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. 5Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Ìdánwò Jobu àkọ́kọ́
6Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. 7Olúwa sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”
Nígbà náà ní Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
8Olúwa sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.”
9Nígbà náà ni Satani dá Olúwa lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” 10“Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. 11Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.”
12Olúwa sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”
Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.
13Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, 14oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé, “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn, 15àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”
16Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”
17Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
18Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. 19Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
20Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà 21wí pé,
“Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,
ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ.
Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,
ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”
22Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.
Job prövas
(1:1—2:13)
En god och framgångsrik person
1I landet Us levde en man som hette Job1:1 Berättelsen om Job, dvs. Jobs bok i sin helhet, är kanske den mest svårtydda texten i hela Gamla testamentet. När det är möjligt ges alternativa tolkningar. Job var från landet Edom, vars dialekt markant skiljde sig från den hebreiska dialekten i Kanaan. Septuaginta antog att Us var en del av Edom. Det skulle också kunna ha legat nära Hauran i Syrien. . Han var en god och rättsinnig man som fruktade Gud och höll sig borta från allt ont. 2Job hade sju söner och tre döttrar. 3Han ägde 7 000 får, 3 000 kameler, 500 par oxar och 500 åsneston, och han hade en mängd tjänare. Han var den mäktigaste i hela Östlandet.
4Jobs söner brukade turas om att hålla fester i sina hem, och de inbjöd sina tre systrar och åt och drack tillsammans med dem. 5När en fest, som kunde vara flera dagar, var över samlade Job sina barn och renade dem. Tidigt på morgonen bar han fram ett brännoffer för var och en av dem. Job tänkte: ”Kanske mina barn har syndat och förbannat Gud i sina hjärtan.” Så gjorde Job varje gång.
Anklagaren gör Job fattig
6En dag när Guds söner kom fram inför Herren, var Anklagaren, Satan, tillsammans med dem.
7”Varifrån kommer du?” frågade Herren Anklagaren. ”Från en färd runt hela jorden”, svarade denne.
8”Har du lagt märke till min tjänare Job?” frågade Herren Anklagaren. ”Det finns ingen annan som han på hela jorden, en god och rättsinnig man som fruktar Gud och inte vill ha något med det onda att göra.”
9”Job fruktar väl inte Gud för ingenting?” svarade Anklagaren. 10”Du har alltid skyddat både honom, hans hus och hans tillhörigheter. Du har välsignat allt han gör, och hans boskapshjordar breder ut sig över landet. 11Men räck ut din hand och rör vid all hans egendom, så ska du få se att han kommer att förbanna dig rakt i ansiktet!”
12Herren svarade Anklagaren: ”Du får göra vad du vill med hans egendom, men Job själv får du inte röra.”
Anklagaren lämnade sedan Herren.
13En dag, när Jobs söner och döttrar festade i den äldste broderns hus, 14kom en budbärare till Job och sa: ”Man plöjde med dina oxar och åsnorna betade i närheten, 15när sabéerna gick till anfall, drog i väg med dem och dödade allt ditt tjänstefolk utom mig. Jag är den ende som kom undan för att berätta detta för dig.”
16Medan denne budbärare fortfarande talade, kom en annan och sa: ”Guds eld föll ner från himlen och brände upp fåren och folket. Jag är den ende som kom undan för att berätta detta för dig.”
17Innan mannen hade slutat tala kom ytterligare en och sa: ”Kaldéerna delade upp sig i tre grupper och rövade bort kamelerna. De har även dödat tjänarna. Jag är den ende som kom undan för att berätta detta för dig.”
18Medan denne fortfarande talade kom ytterligare en annan och sa: ”Dina söner och döttrar hade fest i din äldste sons hem, 19när plötsligt en väldig storm kom svepande från öknen och tog tag i husets fyra hörn, så att taket störtade in och dödade allesammans. Jag är den ende som kom undan för att berätta detta för dig.”
20Då reste sig Job och rev sönder sin mantel. Han rakade av allt hår, föll ner på marken inför Gud och tillbad. 21Han sa:
”Jag kom naken ur min mors liv,
och naken vänder jag åter.
Herren gav och Herren tog.
Välsignat vare Herrens namn.”
22Under allt detta syndade inte Job och klandrade inte Gud.