Joṣua 23 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 23:1-16

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Joṣua sí àwọn olórí

1Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, nígbà tí Olúwa sì ti fún Israẹli ní ìsinmi kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká, nígbà náà Joṣua sì ti di arúgbó. 2Ó sì pe gbogbo Israẹli jọ: àgbàgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó. 3Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín. 4Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti ṣẹ́gun ní àárín Jordani àti Òkun Ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. 5Olúwa Ọlọ́run yín fúnra rẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀ ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín.

6“Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì ṣọ́ra láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tí a kọ sí inú ìwé òfin Mose, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. 7Ẹ má ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ́kù láàrín yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn. 8Ṣùgbọ́n ẹ di Olúwa Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.

9Olúwa ti lé àwọn orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojúkọ yín. 10Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún (1,000) ọ̀tá, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí. 11Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín.

12“Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀. 13Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín.

14“Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà. 15Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín. 16Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Иешуа 23:1-16

Иешуа прощается с вождями

1Спустя много времени, после того как Вечный дал Исраилу покой от всех окружающих его врагов, Иешуа, уже состарившийся и достигший преклонного возраста, 2созвал всех старейшин, вождей, судей и начальников Исраила и сказал им:

– Я состарился и достиг преклонного возраста. 3Вы сами видели всё, что Вечный, ваш Бог, сделал ради вас со всеми этими народами. Вечный, ваш Бог, Сам сражался за вас. 4Помните, что я по жребию разделил между вашими родами всю землю между Иорданом и Средиземным морем23:4 Букв.: «Великим морем». на западе, которая принадлежала народам ещё оставшимся и тем, которых я уже искоренил. 5Вечный, ваш Бог, Сам прогонит их с вашего пути. Он вытеснит их перед вами, и вы завладеете их землёй, как Вечный, ваш Бог, вам и обещал.

6Будьте тверды, соблюдайте и исполняйте всё, что написано в книге Закона, переданного через Мусу, не уклоняясь ни вправо, ни влево. 7Не смешивайтесь с этими народами, которые остаются среди вас, не упоминайте имён их богов и не клянитесь ими. Не служите и не поклоняйтесь им. 8Крепко держитесь Вечного, вашего Бога, как вы делали до сегодняшнего дня.

9Вечный прогнал от вас великие и сильные народы. До сегодняшнего дня никто не мог устоять перед вами. 10Один из вас рассеивает тысячу, потому что Вечный, ваш Бог, Сам сражается за вас, как Он и обещал. 11Итак, больше всего любите Вечного, вашего Бога, потому что от этого зависит ваша жизнь.

12Но если вы отступите и объединитесь с уцелевшим остатком этих народов среди вас и станете заключать с ними браки, 13то знайте наверняка: Вечный, ваш Бог, уже не станет прогонять от вас эти народы. Вместо этого они станут для вас ловушкой и западнёй, плетью для ваших спин и колючками для ваших глаз, пока вы не будете искоренены из этой хорошей земли, которую дал вам Вечный, ваш Бог.

14Я собираюсь отправиться путём всей земли. Всем вашим сердцем и всей душой вы знаете, что из всех добрых обещаний Вечного, вашего Бога, не осталось ни одного неисполненного – все сбылись, ни одно не оказалось ложным. 15Но как сбылось для вас всё доброе, что обещал Вечный, ваш Бог, так Вечный наведёт на вас и всё злое, о котором предупреждал, пока не истребит вас с этой хорошей земли, которую Он вам дал. 16Если вы преступите священное соглашение с Вечным, вашим Богом, которое Он с вами заключил, и пойдёте служить другим богам и поклоняться им, то гнев Вечного вспыхнет на вас, и вы будете быстро искоренены из этой хорошей земли, которую Он вам дал.