Joṣua 22 – YCB & CARS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 22:1-34

Àwọn ẹ̀yà ti ìlà-oòrùn padà sí ilẹ̀ ìní wọn

122.1-34: Jo 1.12-18; Nu 32.20-22.Joṣua sì pe àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase 2ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa pàṣẹ, ẹ sì ti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun gbogbo tí mo pàṣẹ. 3Ẹ kò fi àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ láti ìgbà yí títí di òní, ṣùgbọ́n ẹ ti kíyèsára láti pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́. 4Nísinsin yìí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ẹ padà sí ilẹ̀ yín níbi tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin ní òdìkejì Jordani. 5Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”

6Nígbà náà ni Joṣua súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn. 7(Mose ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani, Joṣua sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yòókù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jordani, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Joṣua súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn, 8Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógun tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.”

9Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá.

10Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani. 11Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli, 12gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.

13Àwọn ọmọ Israẹli rán Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà, sí ilẹ̀ Gileadi, sí Reubeni, sí Gadi àti sí ìdajì ẹ̀yà Manase. 14Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan tiwọn jẹ́ olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.

15Nígbà tí wọ́n lọ sí Gileadi—sí Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase—wọ́n sì sọ fún wọn pé, 16“Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe, ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Israẹli nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa? 17Ẹ̀ṣẹ̀ Peori kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-ààrùn ti jà láàrín ènìyàn Olúwa! 18Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí?

“ ‘Tí ẹ̀yin bá ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Israẹli. 19Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa. 20Nígbà tí Akani ọmọ Sera ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Israẹli nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”

21Nígbà náà ni Reubeni, Gadi àti ẹ̀yà Manase sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Israẹli pé. 22Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀, jẹ́ kí Israẹli pẹ̀lú kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìṣọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa, ẹ má ṣe gbà wa ní òní yìí. 23Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san.

24“Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yin ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Israẹli? 25Olúwa ti fi Jordani ṣe ààlà láàrín àwa àti ẹ̀yin—àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa.

26“Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ẹbọ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’ 27Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàrín àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’

28“Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé, “Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.” ’

29“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.”

30Nígbà tí Finehasi àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Israẹli gbọ́ ohun tí Reubeni, Gadi àti Manase ti sọ, ó dùn mọ́ wọn. 31Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ Olúwa”.

32Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kenaani láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ní Gileadi, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ. 33Inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìròyìn náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run. Wọn kò sì sọ̀rọ̀ mọ́ nípa lílọ bá wọn jagun láti run ilẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ń gbé.

34Ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi sì fún pẹpẹ náà ní orúkọ yìí, “Ẹ̀rí láàrín wa pé Olúwa ni Ọlọ́run.”

Священное Писание

Иешуа 22:1-34

Восточные роды возвращаются на свои земли

1Иешуа созвал роды Рувима, Гада и половину рода Манассы 2и сказал им:

– Вы исполнили всё, что повелел вам Муса, раб Вечного, и были послушны мне во всём, что я вам повелевал. 3Долгое время, до этого самого дня, вы не оставляли своих братьев, но несли служение, которое дал вам Вечный, ваш Бог. 4Теперь Вечный, ваш Бог, дал вашим братьям покой, как Он и обещал. Поэтому возвращайтесь домой, в землю, которую Муса, раб Вечного, дал вам на другой стороне Иордана. 5Только прилежно исполняйте повеления и Закон, которые дал вам Муса, раб Вечного: любите Вечного, вашего Бога, ходите всеми Его путями, храните Его повеления, крепко держитесь Его и служите Ему от всего сердца и от всей души.

6Иешуа благословил и отпустил их, и они вернулись в свои шатры. 7(Одной половине рода Манассы Муса дал землю в Башане, а другой половине рода Иешуа дал землю рядом с их братьями на западной стороне Иордана.) Отпуская домой, Иешуа благословил их, 8сказав:

– Возвращайтесь домой со своим великим богатством – большими стадами, серебром, золотом, бронзой, и железом, и великим множеством одежд – и поделитесь со своими братьями добычей, взятой вами у врагов.

9И роды Рувима, Гада и половина рода Манассы оставили исраильтян в Шило, что в Ханаане, чтобы вернуться в Галаад, в свою землю, которой они завладели по повелению Вечного, данному через Мусу.

Жертвенник «Свидетель»

10Придя в Гелилот, что рядом с Иорданом, в земле Ханаана, роды Рувима, Гада и половина рода Манассы соорудили у Иордана огромный жертвенник. 11Когда исраильтяне услышали, что те соорудили на границе Ханаана в Гелилоте, что рядом с Иорданом на исраильской стороне, жертвенник, 12весь народ Исраила собрался в Шило, чтобы идти на них войной.

13Исраильтяне послали в землю Галаада, к родам Рувима, Гада и половине рода Манассы, Пинхаса, сына священнослужителя Элеазара. 14С ним отправилось десять вождей, по одному от каждого из исраильских родов, каждый из них был главой семейства среди исраильских кланов.

15Когда они пришли в Галаад – к родам Рувима, Гада и половине рода Манассы, – они сказали им:

16– Всё общество Вечного говорит: «Как вы могли совершить такое предательство против Бога Исраила? Как вы могли отступить от Вечного и соорудить себе жертвенник, восстав ныне против Вечного? 17Разве не было с нас довольно греха Пеора?22:17 См. Чис. 25:1-9. До этого самого дня мы ещё не очистились от того греха, за который весь народ Вечного поразил мор! 18А сегодня вы собираетесь отступить от Вечного? Если сегодня вы восстанете против Вечного, то завтра Он разгневается на весь народ Исраила. 19Если ваша земля нечиста, то перейдите в землю Вечного, где стоит священный шатёр Вечного, и разделите землю с нами. Только не восставайте против Вечного и против нас22:19 Или: «и не делайте мятежниками и нас»., сооружая себе иной жертвенник, нежели жертвенник Вечного, нашего Бога. 20Разве, когда Ахан, правнук Зераха, нечестно поступил с подлежащими уничтожению вещами, не обрушился гнев на весь народ Исраила? А за тот грех умер не он один».

21Рувимиты, гадиты и половина рода Манассы ответили главам исраильских кланов:

22– Вечный – Бог богов! Вечный – Бог богов! Он знает, и Исраил пусть знает, – если это было восстание или предательство против Вечного, то не щадите22:22 Или: «пусть Он не пощадит». нас сегодня. 23Если мы построили свой собственный жертвенник, чтобы, отступив от Вечного, приносить на нём всесожжения и хлебные приношения или совершать жертвы примирения, то пусть Сам Вечный призовёт нас к ответу. 24Нет! Мы сделали это из страха, что однажды ваши потомки могут сказать нашим: «Что вам до Вечного, Бога Исраила? 25Вечный сделал Иордан границей между нами и вами, рувимиты и гадиты! Нет у вас доли в Вечном». Так ваши потомки могут заставить наших перестать чтить Вечного.

26Вот почему мы сказали: «Приготовимся и соорудим жертвенник, но не для всесожжений или жертвоприношений». 27Напротив, пусть он будет свидетелем между нами и вами и грядущими поколениями, что мы чтим Вечного в Его святилище своими всесожжениями, приношениями и жертвами примирения. Тогда в будущем ваши потомки не смогут сказать нашим: «Нет у вас доли в Вечном». 28Мы решили, что если они когда-нибудь скажут это нам или нашим потомкам, то мы ответим: «Посмотрите на жертвенник, который соорудили наши отцы по образу жертвенника Вечного не для всесожжений или приношений, но для свидетельства между нами и вами».

29Да не будет того, чтобы нам сегодня восстать против Вечного и отступить от Него, соорудив иной жертвенник для всесожжений, хлебных приношений и жертв примирения, нежели тот жертвенник Вечного, нашего Бога, что находится перед Его священным шатром.

30Когда священнослужитель Пинхас и вожди народа, главы исраильских кланов, услышали, что сказали рувимиты, гадиты и половина рода Манассы, они были удовлетворены. 31И священнослужитель Пинхас, сын Элеазара, сказал рувимитам, гадитам и половине рода Манассы:

– Сегодня мы узнали, что Вечный с нами, что вы не совершили против Вечного этого предательства. Теперь вы избавили исраильтян от руки Вечного.

32И священнослужитель Пинхас, сын Элеазара, возвратился вместе с вождями от рувимитов и гадитов в Галааде и принёс от них ответ в Ханаан, к исраильтянам. 33Те были рады услышать эту весть и возблагодарили Всевышнего. И больше они не говорили о том, чтобы пойти войной на страну, где живут рувимиты и гадиты, и опустошить её.

34А рувимиты и гадиты назвали жертвенник «Свидетель», потому что они говорили: «Это свидетель между нами, что Вечный – наш Бог».