Joṣua 16 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 16:1-10

Ìpín fún ẹ̀yà Efraimu àti Manase

1Ìpín ti àwọn ọmọ Josẹfu láti Jordani lẹ́bàá Jeriko, ní omi Jeriko ní ìhà ìlà-oòrùn, àní aginjù, tí ó gòkè láti Jeriko lọ dé ilẹ̀ òkè Beteli. 2Ó sì tẹ̀síwájú láti Beteli (tí í ṣe Lusi) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Arki ní Atarotu, 3Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jefileti, títí dé ilẹ̀ ìsàlẹ̀ Beti-Horoni, àní dé Geseri, ó sì parí sí etí Òkun.

4Báyìí ni Manase àti Efraimu, àwọn ọmọ Josẹfu, gba ilẹ̀ ìní wọn.

5Èyí ni ilẹ̀ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.

Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Addari ní ìlà-oòrùn lọ sí òkè Beti-Horoni. 6Ó sì lọ títí dé Òkun. Láti Mikmeta ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Ṣilo, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Janoa ní ìlà-oòrùn. 7Láti Janoa ó yípo lọ sí gúúsù sí Atarotu àti Naara, ó sì dé Jeriko, ó sì pín sí odò Jordani. 8Láti Tapua ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Rafini, ó sì parí ní Òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.

9Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Efraimu tí ó wà ní àárín ìní àwọn ọmọ Manase.

1016.10: On 1.29; 2Sa 5.6.Wọn kò lé àwọn ara Kenaani tí ń gbé ni Geseri kúrò, títí di òní yìí ni àwọn ará Kenaani ń gbé láàrín àwọn ènìyàn Efraimu, ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.

Korean Living Bible

여호수아 16:1-10

에브라임과 므낫세 서쪽 반 지파에게 분배된 땅

1요셉 자손이 제비 뽑아 얻은 땅의 경계선은 여리고 맞은편의 요단강에서

2거기서 아렉 사람이 살고 있는 아다롯 – 앗달을 지나

3서쪽으로 야블렛 사람의 경계로 내려가 아래 벧 – 호론까지 미치고 거기서 게셀에 이르러 지중해에서 그 경계선이 끝났다.

4이상은 요셉 자손, 곧 에브라임 지파와 므낫세 서쪽 반 지파가 분배받은 땅의 경계선이다.

에브라임 지파

5에브라임 지파가 그 집안별로 얻은 땅의 경계선은 동쪽 아다롯 – 앗달에서 시작하여 윗 벧 – 호론에 이르고

6거기서 서쪽으로 나아가 지중해에 이르렀다. 다시 그 경계선은 북쪽 믹므닷에서 시작하여 동쪽으로 돌아 다아낫 – 실로와 야노아를 지난 다음

7아다롯과 나아라로 내려가서 여리고에 이르러 요단강에서 끝났다.

8다시 그 경계선은 북쪽 답부아에서 시작하여 서쪽으로 나아가 가나 시내를 따라 지중해까지 가서 끝났다. 이상은 에브라임 지파가 집안별로 분배받은 땅의 경계선이다.

9이 밖에 에브라임 지파는 므낫세 서쪽 반 지파의 땅 중에서도 일부 성과 부락을 얻었다.

10그러나 그들은 게셀에 사는 가나안 사람을 쫓아내지 않았으므로 그들이 오늘날까지 에브라임 지파 가운데 살면서 종살이하고 있다.