Joṣua 15 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 15:1-63

Ìpín fún ẹ̀yà Juda

1Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.

2Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀, 3ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka. 4Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.

5Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani.

Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jordani, 6ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni. 7Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli. 8Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá. 9Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu). 10Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna. 11Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun.

12Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá.

Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.

13Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.) 1415.14-19: On 1.10-15,20.Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta jáde láti Hebroni; Ṣeṣai, Ahimani, àti Talmai, ìran Anaki. 15Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí). 16Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 17Otnieli ọmọ Kenasi, arákùnrin Kalebu, sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

18Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

19Ó sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.

20Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn.

21Ìlú ìpẹ̀kun gúúsù ti ẹ̀yà Juda ní gúúsù ní ààlà Edomu nìwọ̀nyí:

Kabṣeeli, Ederi, Jaguri, 22Kina, Dimona, Adada, 23Kedeṣi, Hasori, Itina, 24Sifi, Telemu, Bealoti, 25Hasori Hadatta, Kerioti Hesroni (tí í ṣe Hasori), 26Amamu, Ṣema, Molada, 27Hasari Gada, Heṣmoni, Beti-Peleti, 28Hasari-Ṣuali, Beerṣeba, Bisiotia, 29Baalahi, Limu, Esemu, 30Eltoladi, Kesili, Horma, 31Siklagi, Madmana, Sansanna, 32Leboati, Ṣilhimu, Aini àti Rimoni, àpapọ̀ ìlú mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti àwọn ìletò wọn.

33Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹsẹ̀ òkè:

Eṣtaoli, Sora, Aṣna, 34Sanoa, Eni-Gannimu, Tapua, Enamu, 35Jarmatu, Adullamu, Soko, Aseka, 36Ṣaaraimu, Adittaimu àti Gedera (tàbí Gederotaimu). Ìlú mẹ́rìnlá àti àwọn ìletò wọn.

37Senani, Hadaṣa, Migdali Gadi, 38Dileani, Mispa, Jokteeli, 39Lakiṣi, Boskati, Egloni, 40Kabboni, Lamasi, Kitlisi, 41Gederoti, Beti-Dagoni, Naama àti Makkeda, ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.

42Libina, Eteri, Aṣani, 43Hifita, Aṣna, Nesibu, 44Keila, Aksibu àti Meraṣa: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò wọn.

45Ekroni, pẹ̀lú ibùgbé àti àwọn ìletò rẹ̀ tó yí i ká, 46ìwọ̀-oòrùn Ekroni, gbogbo èyí tí ń bẹ nítòsí Aṣdodu, pẹ̀lú àwọn ìletò wọn, 47Aṣdodu, agbègbè ìlú rẹ̀ àti ìletò; àti Gasa, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé odò Ejibiti àti agbègbè Òkun Ńlá.15.47 Òkun Mẹditarenia

48Ní ilẹ̀ òkè náà:

Ṣamiri, Jattiri, Soko, 49Dannah, Kiriati-Sannnah (tí í ṣe Debiri), 50Anabu, Eṣitemo, Animu, 51Goṣeni, Holoni àti Giloni, ìlú mọ́kànlá àti ìletò wọn.

52Arabu, Duma, Eṣani, 53Janimu, Beti-Tapua, Afeka, 54Hamuta, Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) àti Ṣiori: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò rẹ̀

55Maoni, Karmeli, Sifi, Jutta, 56Jesreeli, Jokdeamu, Sanoa, 57Kaini, Gibeah àti Timna: ìlú mẹ́wàá àti àwọn ìletò wọn.

58Halhuli, Beti-Suri, Gedori, 59Maarati, Beti-Anoti àti Eltekoni: ìlú mẹ́fà àti àwọn ìletò wọn.

60Kiriati-Baali (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu) àti Rabba ìlú méjì àti ìletò wọn.

61Ní aginjù:

Beti-Araba, Middini, Sekaka, 62Nibṣani, Ìlú Iyọ̀ àti En-Gedi: ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn.

6315.63: On 1.21; 2Sa 5.6.Juda kò lè lé àwọn ọmọ Jebusi jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Juda títí dí òní.

New Russian Translation

Навин 15:1-63

Надел Иуды

(Суд. 1:11-15)

1Жребий рода Иуды по их кланам простирался до земель Эдома, до пустыни Цин на самом юге.

2Их южная граница начиналась от залива, что на южной оконечности Соленого моря, 3проходила южнее Скорпионовой возвышенности15:3 Или: «возвышенности Акраббим»., продолжалась к Цину и поднималась к югу от Кадеш-Барнеа. Затем она шла мимо Хецрона к Аддару и поворачивала к Каркае. 4Далее она проходила Ацмон, выходила к египетскому потоку и оканчивалась у моря. Вот их15:4 Букв.: «ваша». южная граница.

5Восточная граница – это Соленое море до устья Иордана.

Северная граница начиналась от залива в море при устье Иордана, 6поднималась к Бет-Хогле и продолжалась севернее Бет-Аравы до камня Богана, сына Рувима. 7Затем граница поднималась к Давиру из долины Ахор и поворачивала на север к Гилгалу, что напротив возвышенности Адуммим к югу от потока. Она тянулась к водам Эн-Шемеша и заканчивалась у Эн-Рогела. 8Затем она поднималась к долине Бен-Гинном по южному склону иевусейского города (то есть Иерусалима). Оттуда она восходила на вершину горы к западу от долины Гинном в северном конце долины Рефаим. 9С вершины горы граница тянулась к источнику вод Нефтоах, оттуда – к городам горы Эфрон, а затем поворачивала к Баале (то есть Кирьят-Иеариму). 10Затем она поворачивала к западу от Баалы к горе Сеир, проходила по северному склону горы Иарим (то есть Кесалон), спускалась к Бет-Шемешу и проходила через Тимну. 11Она шла к северному склону Экрона, поворачивала к Шикарону, проходила к горе Баала, достигала Иавнеила, и заканчивалась у моря.

12Западная граница – это побережье Великого моря.

Таковы границы вокруг народа Иуды по его кланам.

13По повелению Господа, Иисус дал Халеву, сыну Иефоннии, земельный надел среди народа Иуды – Кирьят-Арбу, то есть Хеврон. (Арба был отцом Анака). 14Из Хеврона Халев прогнал трех анакитов – Шешая, Ахимана и Талмая, потомков Анака. 15Оттуда он пошел на жителей Давира (который прежде назывался Кирьят-Сефер). 16Халев сказал:

– Я отдам свою дочь Ахсу в жены тому, кто нападет на Кирьят-Сефер и возьмет его.

17Отниил, сын Кеназа, брата Халева15:17 Или: «Отниил, потомок Кеназа, брат Халева»., взял его, и Халев отдал ему в жены свою дочь Ахсу.

18В день, когда была назначена свадьба, она говорила с Отниилом, чтобы просить у ее отца поле. Когда она слезла со своего осла, Халев спросил ее:

– Чего ты хочешь?

19Она ответила:

– Окажи мне особую милость. Ты дал мне землю в Негеве – так дай мне и источники воды.

И Халев дал ей верхние и нижние источники.

20Вот удел рода Иуды по их кланам:

21Города рода Иуды на самом юге, в Негеве по направлению к границе Эдома:

Кавцеил, Едер, Иагур, 22Кина, Димона, Адада, 23Кедеш, Хацор, Ифнан, 24Зиф, Телем, Валоф, 25Хацор-Хадафа, Кериот-Хецрон (то есть Хацор), 26Амам, Шема, Молада, 27Хацар-Гадда, Хешмон, Бет-Пелет, 28Хацар-Шуал, Вирсавия, Визиофея, 29Баала, Иим, Ецем, 30Элтолад, Кесил, Хорма, 31Циклаг, Мадманна, Сансана, 32Леваоф, Шилхим, Аин и Риммон – всего двадцать девять городов с окрестными поселениями15:32 То, что число городов в списке превышает двадцать девять, может иметь два объяснения: 1) возможно некоторые города были добавлены в список позже; 2) в тексте стоит число двадцать девять, так как семь из перечисленных городов позднее были отданы роду Симеона (см. 19:1-7)..

33В западных предгорьях:

Эштаол, Цора, Ашна, 34Заноах, Эн-Ганним, Таппуах, Энам, 35Ярмут, Адуллам, Сохо, Азека, 36Шаараим, Адифаим, Гедера (или Гедерофаим)15:36 Или: «Гедера и Гедерофаим». – четырнадцать городов с окрестными поселениями.

37Ценан, Хадаша, Мигдал-Гад, 38Дилеан, Мицпе, Иоктеил, 39Лахиш, Боцкат, Эглон, 40Каббон, Лахмас, Хитлиш, 41Гедероф, Бет-Дагон, Наама и Македа – шестнадцать городов с окрестными поселениями. 42Ливна, Ефер, Ашан, 43Ифтах, Ашна, Нецив, 44Кеила, Ахзив и Мареша – девять городов с окрестными поселениями.

45Экрон, с окрестными деревнями и поселениями; 46к западу от Экрона – все, что рядом с Ашдодом вместе с их селами; 47Ашдод с окрестными деревнями и селами; Газа с ее деревнями и поселениями до египетского потока и побережья Великого моря.

48В нагорьях:

Шамир, Иаттир, Сохо, 49Данна, Кирьят-Санна (то есть Давир), 50Анав, Эштемо, Аним, 51Гошен, Холон и Гило – одинадцать городов с окрестными поселениями.

52Арав, Дума, Ешан, 53Ианум, Бет-Таппуах, Афека, 54Хумта, Кирьят-Арба (то есть Хеврон) и Цигор – девять городов с окрестными поселениями.

55Маон, Кармил, Зиф, Ютта, 56Изреель, Иокдам, Заноах, 57Каин, Гива и Тимна – десять городов с окрестными поселениями.

58Халхул, Бет-Цур, Гедор, 59Маараф, Бет-Аноф и Элтекон – шесть городов с окрестными поселениями15:59 В древнем переводе список продолжается: «Текоа, Ефрафа (то есть Вифлеем), Пеор, Етам, Кулон, Татам, Шореш, Керем, Галлим, Бет-Эр и Манахат – одинадцать городов с окрестными поселениями»..

60Кирьят-Баал (то есть Кирьят-Иеарим) и Равва – два города с окрестными поселениями.

61В пустыне:

Бет-Арава, Миддин, Секаха, 62Нившан, Ир-Мелах и Эн-Геди – шесть городов с окрестными поселениями.

63Иуда не смог выселить иевусеев, которые жили в Иерусалиме; до сегодняшнего дня иевусеи живут там вместе с народом Иуды.