Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 1:1-19

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. 2Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, 3Àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

Ìpè Jeremiah

4Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,

51.5: Isa 49.1; Ga 1.15.Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,

kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.

Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.

6Mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.”

7Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” 81.8: Isa 43.5; Ap 18.9-10.Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.

9Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ 101.10: If 10.11.Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.

11Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé:

“Kí ni o rí Jeremiah?”

Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

12Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

13Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

14Olúwa, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.

Àwọn ọba wọn yóò wá

gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé

Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo

àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn

ìlú Juda.

16Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi

nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,

nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn

àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

17“Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

耶利米書 1:1-19

1希勒迦的兒子耶利米便雅憫境內亞拿突城的一位祭司,以下是他的話。 2猶大亞們的兒子約西亞執政第十三年,耶和華的話傳給了耶利米3猶大約西亞的兒子約雅敬開始執政,一直到約西亞的另一個兒子西底迦猶大王的第十一年五月,就是耶路撒冷的居民被擄之日,耶和華的話常常傳給耶利米

耶利米蒙召

4耶和華對我說:

5「我還沒有使你在母腹中成形,就認識你;

你還未出生,我已使你聖潔,

立你做萬國的先知。」

6我回答說:「主耶和華啊,我太年輕,不懂得怎樣說話。」 7耶和華卻說:

「不要說你太年輕,

我派你去誰那裡,

你就去誰那裡;

我吩咐你說什麼,

你就說什麼。

8誰也不要怕,

因為我與你同在,

我必拯救你。

這是耶和華說的。」

9然後,耶和華伸手摸我的口,對我說:「看啊,我已把我的話放在你口中。 10今日,我派你到列邦列國去拔掉、拆除、毀滅、推翻、建造和栽植。」

兩個異象

11耶和華又對我說:「耶利米,你看見什麼?」我說:「我看見一根杏樹枝。」 12耶和華說:「不錯。我必實現我說過的話。」

13耶和華又對我說:「你看見什麼?」我回答說:「我看見一鍋煮沸的水,從北方傾倒下來。」 14耶和華說:「不錯。因為有災禍要從北方降臨到這地方的一切居民。 15我要召來北方各國,他們要在耶路撒冷的城門自立王位,攻打耶路撒冷周圍的城牆和猶大各城邑。這是耶和華說的。 16我要審判他們,因為他們犯罪作惡,背棄我,給別的神明燒香,又跪拜自己製造的神像。 17現在,你要做好準備,去把我吩咐你的話告訴他們。不要懼怕他們,不然我將使你在他們面前充滿恐懼。 18看啊,今天我已使你成為堅城、鐵柱、銅牆,來對抗整個猶大,對抗猶大的君王、首領、祭司和境內的眾民。 19他們必攻擊你,但絕不能勝過你,因為我與你同在,我必拯救你。這是耶和華說的。」