Jakọbu 5 – YCB & NUB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jakọbu 5:1-20

Ìkìlọ̀ fún àwọn aninilára ọlọ́rọ̀

1Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. 2Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. 3Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn. 4Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 5Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. 6Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín.

Sùúrù nínú ìjìyà

7Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. 9Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.

10Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. 115.11: Jb 1.21-22; 2.10; Sm 103.8; 111.4.Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.

125.12: Mt 5.37.Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi.

Àdúrà ìgbàgbọ́

13Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́. 14Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa. 15Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í. 16Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.

175.17: 1Ọb 17.1; 18.1; Lk 4.25.Ènìyàn bí àwa ni Elijah, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà. 185.18: 1Ọb 18.42.Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.

19Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà; 20jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

Swedish Contemporary Bible

Jakob 5:1-20

Varning till rika människor

1Ni som är rika, gråt och jämra er över den olycka som ska drabba er. 2Er rikedom ska ruttna bort och era kläder ätas av mal. 3Ert guld och silver ska förstöras av rost. Rosten ska vittna mot er och er kropp brännas upp som av eld. Ni har samlat på er rikedomar för den sista tiden. 4Ni har undanhållit lönen för skördearbetarna på era åkrar. Nu ropar de, och skördearbetarnas rop har nått härskarornas5:4 Det hebreiska ordet Sevaot , som kan översättas härskarorna, har i den grekiska texten inte översatts utan bara transkriberats Sabaot. Herres öron.5:4 Jfr v. 2 samt 5 Mos 24:14-15. En sådan egoistisk livsstil förebådade i Gamla testamentet Guds kommande dom vid tidens slut. 5Ni har levt i lyx och överflöd här på jorden. Ni har ätit era hjärtan feta inför slakten.5:5 Jfr Jer 25:34. 6Ni har dömt och dödat den rättfärdige, han gjorde inte motstånd mot er.

Herren Jesus kommer snart tillbaka

7Syskon, vänta tåligt på att Herren ska komma tillbaka. Se hur jordbrukaren tåligt väntar på skörden och ser fram emot höstregn och vårregn. 8Visa tålamod och styrk era hjärtan, ni också, för Herren kommer snart.

9Klaga inte på varandra, syskon, så att ni inte blir dömda. Domaren står redan utanför dörren.

10Syskon, ta profeterna som talat i Herrens namn till ert föredöme när det gäller att lida och visa tålamod. 11Vi prisar ju dem lyckliga som har hållit ut. Ni har hört om Jobs uthållighet och sett hur Herren lät hans liv sluta. Herren är full av medlidande och barmhärtighet.5:11 Jfr Job 42.

12Framför allt, mina syskon, svär inga eder, vare sig vid himlen eller vid jorden eller vid något annat. Säg bara ett enkelt ja eller nej, så att ni inte drabbas av domen.5:12 Jfr vad Jesus säger i Matt 5:33-37.

Bönens kraft

13Om någon av er får lida, ska han be. Och om någon är glad, ska han sjunga glädjesånger. 14Om någon är sjuk, ska han kalla på församlingens ledare, och de ska be för honom och smörja honom med olja i Herrens namn.5:14 Olivolja var en välkänd medicin på den här tiden. Men här användes oljan antagligen som en symbol för att kraften från Herren Jesus skulle bota den sjuke. 15Deras bön, som bes i tro, ska göra den sjuke frisk, och Herren ska resa upp honom. Och om den sjuke har syndat ska han bli förlåten. 16Bekänn därför era synder för varandra och be för varandra, så att ni kan bli botade.5:16 Förutsättningen för att Gud ska bota en människa är att hon tror på honom och ber om förlåtelse för det onda hon har gjort. Det betyder inte att sjukdomen är ett straff från Gud. Jfr vad Jesus säger i Joh 9:2-3. Den rättfärdiges bön har stor verkan.

17Elia var en människa precis som vi. Men när han ivrigt bad att det inte skulle regna, då regnade det inte i landet på tre och ett halvt år. 18När han sedan bad igen, då kom regnet från himlen, och jorden gav sin skörd.5:18 Jfr 1 Kung 17:1; 18:41-45.

Rädda den som har kommit bort från Jesus

19Mina syskon, om någon av er har kommit bort från sanningen och någon för honom tillbaka, 20så ska ni veta att den som lyckas föra en syndare tillbaka från hans villoväg, han räddar den personen från döden och gör så att många synder blir förlåtna.