Isaiah 6 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 6:1-13

Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah

1Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 36.3: If 4.8.Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun

gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

46.4: If 15.8.Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

5Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

6Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. 7Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

8Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”

Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

96.9-10: Mt 13.14-15; Mk 4.12; Lk 8.10; Jh 12.39-41; Ap 28.26-27.Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé,

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;

ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

10Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,

mú kí etí wọn kí ó wúwo,

kí o sì dìwọ́n ní ojú.

Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,

kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,

kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,

kí wọn kí ó má ba yípadà

kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

11Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”

Òun sì dáhùn pé:

“Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,

láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,

títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,

títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.

12Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré

tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.

13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,

yóò sì tún pàpà padà di rírun.

Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,

ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Исаия 6:1-13

Призвание Исаии

1В год смерти царя Уззии6:1 Царь Уззия умер приблизительно в 740 г. до н. э. я видел Владыку, сидящего на престоле, высоком и превознесённом, и края Его одеяния наполняли храм. 2Над Ним парили серафимы6:2 Серафим – один из высших ангельских чинов., и у каждого было по шесть крыльев: двумя крыльями они закрывали свои лица, двумя закрывали ноги и двумя летали. 3Они восклицали друг другу:

– Свят, свят, свят Вечный, Повелитель Сил;

вся земля полна Его славы!

4От звука их голосов дрогнули косяки дверей, и храм наполнился дымом.

И тогда я воскликнул:

5– Горе мне! Я погиб! Я человек с нечистыми устами, и живу среди народа с нечистыми устами, а глаза мои видели Царя, Вечного, Повелителя Сил.

6Тогда один из серафимов подлетел ко мне, держа горящий уголь, который он взял щипцами с жертвенника. 7Он коснулся им моих уст и сказал:

– Вот, это прикоснулось к твоим устам; твоя вина снята, и твой грех очищен.

8Затем я услышал голос Владыки, говорящего:

– Кого Мне послать? И кто пойдёт для Нас?

И я сказал:

– Вот я. Пошли меня!

9Он сказал:

– Пойди и скажи этому народу:

«Слушать слушайте, но не понимайте,

смотреть смотрите, но не разумейте».

10Ожесточи сердце этого народа,

закрой их уши

и сомкни им глаза,

чтобы они не смогли увидеть глазами,

услышать ушами

и понять сердцем,

чтобы не обратились и не получили исцеление.

11Тогда я спросил:

– Надолго ли Ты отправляешь меня, Владыка?

И Он ответил:

– Пока города не лягут руинами

и не останутся без жителей;

пока дома не будут брошены,

и поля не будут опустошены и разграблены;

12пока Вечный не изгонит всех,

и страна не будет совершенно заброшена.

13И пусть в ней останется десятая часть её жителей,

она будет снова опустошена.

Но как от теревинфа6:13 Теревинф – невысокое дерево (до пяти метров) с широкой кроной. Распространено в тёплых сухих местах в самом Исроиле и в соседних районах. и от дуба

остаётся корень, когда их срубят,

так и оставшийся святой народ, словно корень,

породит новую жизнь.