Isaiah 57 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 57:1-21

1Olódodo ṣègbé

kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;

a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,

kò sì ṣí ẹni tó yé

pé a ti mú àwọn olódodo lọ

láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.

2Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé

ń wọ inú àlàáfíà;

wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.

3“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,

ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!

4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?

Ta ni o ń yọ ṣùtì sí

tí o sì yọ ahọ́n síta?

Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,

àti ìran àwọn òpùrọ́?

5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù

àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;

ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn

àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.

6Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán

wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;

àwọ̀n ni ìpín in yín.

Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀

àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.

Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ

kí n dáwọ́ dúró?

7Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;

níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.

8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín

níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.

Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,

ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;

ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,

ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.

9Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi

ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.

Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;

ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!

10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,

ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘Kò sí ìrètí mọ́?’

Ẹ rí okun kún agbára yín,

nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.

11“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù

tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,

àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi

tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?

Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́

tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?

12Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,

wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́

ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!

Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,

èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀

ni yóò jogún ilẹ̀ náà

yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́

14A ó sì sọ wí pé:

“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!

Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”

1557.15: Mt 5.3.Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí

ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:

“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,

ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,

láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí

àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

16Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,

tàbí kí n máa bínú sá á,

nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò

rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi

èémí ènìyàn tí mo ti dá.

17Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;

mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú;

síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.

18Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;

Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,

1957.19: Ap 2.39; Ef 2.13,17.ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.

Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”

ni Olúwa wí, “Àti pé, Èmi yóò wo wọ́n sàn.”

20Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun

tí kò le è sinmi,

tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.

21“Kò sí àlàáfíà fún àwọn ìkà,” ni Ọlọ́run mi wí.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以赛亚书 57:1-21

1没有人关心义人的死亡,

没有人明白虔诚人的去世。

其实义人去世是脱离灾难。

2这些正直的人得享平安,

在坟墓里得到安息。

3耶和华说:“你们这些巫婆的儿子,

奸夫和妓女的孩子,

上前来吧!

4你们在嘲笑谁,

向谁吐舌头呢?

你们难道不是悖逆的儿女、

诡诈的子孙吗?

5你们在橡树下,在青翠树下以淫乱的方式祭拜假神,

在山谷中和石缝间杀儿女作祭物。

6你们把谷中光滑的石头当神明敬奉,

效忠于它们,

向它们浇奠献祭。

我岂能容忍?

7你们在高山上淫乱、献祭,

8在门后供奉神像。

你们背弃我,

脱衣上床跟它们肆意苟合,

与它们立约,

迷恋它们的床,

爱看它们的淫态。

9你们带着橄榄油和许多香料去拜假神,

差遣使者到远方,

甚至去阴间寻找神明。

10虽然遥远的路途使你们疲倦,

你们却从不放弃。

你们找到了新的力量,

所以没有晕倒。

11“你们惧怕谁,

以致对我说谎,

不把我放在心上,忘记我?

你们不再敬畏我,

是因为我长期沉默吗?

12我要揭露你们的所谓公义行为,

它们对你们毫无益处。

13当你们呼求的时候,

让你们收集的神像来救你们吧!

风会把它们刮去,

就是一口气也会把它们吹走。

但投靠我的必承受这片土地,

拥有我的圣山。”

主安慰痛悔者

14耶和华说:

“要修路,修路,铺平道路,

清除我子民路上的障碍。”

15那至高至上、永远长存的圣者说:

“我住在至高至圣之处,

但我也跟痛悔、

谦卑的人同住,

使他们心灵振作。

16我不会永远指责,

也不会一直发怒,

以免世人——我所造的生灵昏倒。

17他们贪婪的罪恶使我发怒,

我惩罚他们,愤怒地转脸不理他们,

他们却怙恶不悛。

18我看见了他们的所作所为,

但我还是要医治他们,

引领他们,

使他们和那些哀伤的人得安慰,

19使他们开口赞美。

愿远近各方的人都得到平安!

我要医治他们。

这是耶和华说的。

20然而,恶人就像波涛汹涌、

难以平静的大海,

海浪中涌出淤泥和污物。”

21我的上帝说:“他们必得不到平安。”