Isaiah 53 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 53:1-12

153.1: Jh 12.38; Ro 10.16.Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́

àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?

2Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,

àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.

Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀

tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.

3A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.

Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún

a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

453.4: Mt 8.17.Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ

ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,

síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,

tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

553.5-6: 1Pt 2.24-25.Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa

a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;

ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,

àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

6Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,

ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;

Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀

gbogbo àìṣedéédéé wa.

753.7-8: Ap 8.32-33.A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,

síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;

a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,

àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,

síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

8Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,

ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?

Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;

nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

953.9: 1Pt 2.22.A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,

àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,

tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára

àti láti mú kí ó jìyà,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀

fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,

Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé

rẹ̀ yóò pẹ́ títí,

àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

11Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,

òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;

nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,

Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.

1253.12: Lk 22.37.Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá

òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,

nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,

tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.

Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,

ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Исаия 53:1-12

1Кто поверил слышанному от нас,

и кому открылась сила Вечного?

2Он пророс перед Ним, как нежный побег

и как корень из сухой земли.

Не было в Нём ни красы, ни величия,

чтобы нам смотреть на Него;

не было в Его облике ничего,

что привлекло бы нас.

3Он был презрен и отвергнут людьми,

человек скорбей, знакомый с недугом.

Как тот, от кого прячут лица, Он был презираем,

и мы ни во что не ставили Его.

4Но Он взял на Себя наши немощи

и понёс наши болезни.

Мы же думали: разит Его Аллах

за Его собственные грехи,

бьёт Его – вот Он и мучается.

5А Он был изранен за наши грехи,

сокрушаем за наши беззакония;

Он понёс наказание, чтобы мы получили мир,

и ранами Его мы исцелились.

6Все мы, как овцы, сбились с пути,

каждый из нас пошёл своей дорогой,

но на Него Вечный возложил

все грехи наши.

7Он был угнетаем и мучим,

но уст Своих не открывал.

Как ягнёнок, Он был ведён на заклание,

и как овца перед стригущими безмолвна,

так и Он не открывал уст Своих.

8Он был арестован и несправедливо судим.

Но кто из Его поколения подумал,

что53:8 Или: «Но кто может понять Его происхождение?»; или: «Разве Он оставил после Себя потомков?» Он был отторгнут от земли живых

за преступления Моего народа,

которому причиталась эта кара?

9Могилу Ему отвели с нечестивыми,

но Он был похоронен у богатого,

потому что Он не был жесток,

и в устах Его не было никакой лжи.

10Но Вечному было угодно сокрушить Его и предать мучению.

Когда же Его жизнь станет приношением за грех,

Он увидит Своё потомство и продлит Свои дни;

и свершится через Него воля Вечного.

11После страданий Своих Он увидит свет жизни

и порадуется.

Через познание Его53:11 Или: «Своим знанием». Мой праведный Раб многих оправдает

и понесёт их грехи.

12Поэтому Я дам Ему удел с великими,

и добычу разделит Он с сильными,

потому что Себя Он предал на смерть

и был причислен к преступникам,

тогда как Он понёс грех многих

и за преступников ходатайствовал.