Isaiah 5 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 5:1-30

Orin ọgbà àjàrà náà

15.1-7: Mt 21.33-46; Mk 12.1-12; Lk 20.9-19.Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn

orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.

Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan

ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.

2Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò

ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.

Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀

ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.

Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,

ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

3“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu

àti ẹ̀yin ènìyàn Juda

ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti

ọgbà àjàrà mi.

4Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.

Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?

Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,

èéṣe tí ó fi so kíkan?

5Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ

ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi.

Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,

a ó sì pa á run,

Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀

yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

6Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro

láì kọ ọ́ láì ro ó,

ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.

Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru

láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”

7Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun

ni ilé Israẹli

àwọn ọkùnrin Juda

sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.

Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí.

Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

Ègún àti ìdájọ́

8Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé

tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀

tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù

tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.

9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:

“Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńlá

yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.

10Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú

ìkòkò wáìnì kan wá,

nígbà tí òsùwọ̀n homeri kan yóò mú

agbọ̀n irúgbìn kan wá.”

11Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde

ní kùtùkùtù òwúrọ̀

láti lépa ọtí líle,

tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́

títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.

12Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,

ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,

ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,

wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn

nítorí òye kò sí fún wọn,

ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;

ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ yóò sì gbẹ.

14Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,

ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,

nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí

pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.

15Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀

àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀

ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.

16Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,

Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.

17Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,

àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.

18Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,

àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,

19sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,

jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,

jẹ́ kí ó súnmọ́ bí

jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,

kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

20Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,

tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,

tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.

21Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn

tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.

22Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu

àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,

23tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,

tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.

24Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run

àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,

bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà

tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:

nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀

wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.

25Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀,

ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.

Àwọn òkè sì wárìrì,

òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro.

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò,

ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.

26Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà,

yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.

Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.

27Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀,

kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn;

bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú,

bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja.

28Àwọn ọfà wọn múná,

gbogbo ọrun wọn sì le;

pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,

àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.

29Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún,

wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún,

wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú

tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.

30Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí

gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun.

Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,

yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;

pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.

New Amharic Standard Version

ኢሳይያስ 5:1-30

ስለ ወይን ቦታ የተነገረ ቅኔ

1ስለ ወዳጄ፣

ደግሞም ስለ ወይን ቦታው ልዘምር፤

ወዳጄ በለምለም ኰረብታ ላይ

የወይን ቦታ ነበረው።

2መሬቱን ቈፈረ፤ ድንጋይንም ለቅሞ አወጣ፤

ምርጥ የሆነውንም ወይን ተከለበት።

በመካከሉ መጠበቂያ ማማ ሠራ፤

የወይን መጭመቂያ ጕድጓድም አበጀ፤

ከዚያ መልካም ፍሬ ያፈራል ብሎ ዐሰበ፤

ነገር ግን ኮምጣጣ ፍሬ አፈራ።

3“እናንት በኢየሩሳሌም የምትኖሩና የይሁዳ ሰዎች ሆይ፤

በእኔና በወይኔ ቦታ መካከል እስቲ ፍረዱ።

4ከዚህ ካደረግሁለት በላይ ለወይኔ ቦታ ምን

ሊደረግለት ይገባ ነበር?

መልካም የወይን ፍሬ ያፈራል ብዬ

ስጠብቅ ለምን ኮምጣጣ ፍሬ አፈራ?

5እንግዲህ በወይኔ ቦታ

ምን እንደማደርግ ልንገራችሁ፤

ዐጥሩን እነቅላለሁ፤

ለጥፋት ይጋለጣል፤

ግንቡንም አፈርሳለሁ፣

መረጋገጫም ይሆናል።

6የማይኰተኰትና የማይታረም

ጠፍ መሬት አደርገዋለሁ፤

ኵርንችትና እሾኽም ይበቅልበታል፤

ዝናብም እንዳይዘንብበት

ደመናዎችን አዝዛለሁ።”

7የሰራዊት ጌታ የእግዚአብሔር

የወይን ቦታው የእስራኤል ቤት ነው፤

የይሁዳ ሰዎችም

የደስታው አትክልት ናቸው።

ፍትሕን ፈለገ፤ ነገር ግን ደም ማፍሰስን አየ፤

ጽድቅን ፈለገ፤ ነገር ግን የጭንቅን ጩኸት ሰማ።

ወዮታና ፍርድ

8ስፍራ ለሌሎች እስከማይተርፍ፣

ቤትን በቤት ላይ በመጨመር፣

መሬትን ከመሬት ጋር በማያያዝ፣

ለብቻችሁ በምድር ተስፋፍታችሁ ለምትኖሩ ወዮላችሁ

9የሰራዊት ጌታ እግዚአብሔር ጆሮዬ እየሰማ እንዲህ ሲል ተናገረ፤

“ታላላቅ ቤቶች ወና ይቀራሉ፣

የሚያማምሩም ቤቶች ኗሪ ያጣሉ።

10ከሩብ ጋሻ5፥10 በዕብራይስጥ፣ ሩብ ጋሻ መሬት በዐሥር ጥማድ በሬ በአንድ ቀን የሚታረስ ነው። የወይን ቦታ አንድ የባዶስ መስፈሪያ ያህል የወይን ጭማቂ ብቻ ይገኛል፤ አንድ የቆሮስ መስፈሪያ ዘር ተዘርቶ አንድ የኢፍ መስፈሪያ እህል ብቻ ይሰጣል።”5፥10 ምናልባት አንድ ባዶስ ሀያ ሁለት ሊትር ያህል ነው። አንድ የቆሮስ መስፈሪያ መቶ ስድሳ ኪሎ ግራም ያህል ነው። አንድ የኢፍ መስፈሪያ ዐሥራ ስምንት ኪሎ ግራም ያህል ነው።

11የሚያሰክር መጠጥ ፍለጋ

ማልደው ለሚነሡ፣

እስኪያነድዳቸውም ወይን በመጠጣት

ሌሊቱን ለሚያነጉ ወዮላቸው!

12በግብዣቸው ላይ በገናና መሰንቆ፣

ከበሮና ዋሽንት እንዲሁም የወይን ጠጅ አለ፤

ነገር ግን ለእግዚአብሔር ሥራ ቦታ አልሰጡም፤

ለእጆቹም ሥራ ክብር አላሳዩም።

13ስለዚህ ሕዝቤ

ዕውቀት በማጣቱ ይማረካል፤

መኳንንቱም በራብ ይሞታሉ፤

ሕዝቡም በውሃ ጥም ይቃጠላል።

14ስለዚህ ሲኦል5፥14 በዕብራይስጡ፣ መቃብር ማለት ነው። ሆዷን አሰፋች፣

አፏንም ያለ ልክ ከፈተች፤

መኳንንቱና ሕዝቡ ከረብሸኞቻቸውና ከጨፋሪዎቻቸው ጋር

ወደዚያ ይወርዳሉ።

15ሰው ይዋረዳል፤

የሰው ልጅም ዝቅ ዝቅ ይላል፤

የእብሪተኛውም ዐይን ይሰበራል።

16የሰራዊት ጌታ እግዚአብሔር ግን በፍትሕ ከፍ ከፍ ይላል፤

ቅዱሱም አምላክ ቅድስናውን በጽድቅ ይገልጻል።

17በጎችም በገዛ መሰማሪያቸው እንደሚሰማሩ ሆነው ይግጣሉ፤

የበግ ጠቦቶችም በባለጠጎች ፍርስራሽ ላይ ሣር ይበላሉ5፥17 በዕብራይስጡ፣ እንግዶች ይበሉታል ይለዋል።

18ኀጢአትን በማታለል ገመድ ለሚስቡ፣

በደልንም በሠረገላ ማሰሪያ ለሚጐትቱ ወዮላቸው!

19“በዐይናችን እንድናይ

እግዚአብሔር ይቸኵል፤

ሥራውንም ያፋጥን፤

የእስራኤልን ቅዱስ፣ የእርሱን ዕቅድ

እንድናውቃት ትቅረብ፤

ትምጣም” ለሚሉ ወዮላቸው!

20ክፉውን መልካም፣

መልካሙን ክፉ ለሚሉ

ብርሃኑን ጨለማ፣

ጨለማውን ብርሃን ለሚያደርጉ፣

ጣፋጩን መራራ፣

መራራውንም ጣፋጭ ለሚያደርጉ ወዮላቸው!

21ራሳቸውን እንደ ብልኅ ለሚቈጥሩ፣

በራሳቸውም አመለካከት ጥበበኛ ለሆኑ ወዮላቸው!

22የወይን ጠጅ ለመጠጣት ጀግኖች፣

የሚያሰክር መጠጥ ለመደባለቅ ብርቱ ለሆኑ ወዮላቸው!

23ጕቦን በመቀበል በደለኛን ንጹሕ ለሚያደርጉ፣

ለበደል አልባ ሰው ፍትሕን ለሚነፍጉ ወዮላቸው!

24ስለዚህ የእሳት ነበልባል ገለባን እንደሚበላ፣

ድርቆሽም በእሳት ጋይቶ እንደሚጠፋ፣

የእነርሱም ሥር እንዲሁ ይበሰብሳል፤

አበባቸውም እንደ ትቢያ ይበንናል፤

የሰራዊት ጌታ የእግዚአብሔርን ሕግ ንቀዋልና፤

የእስራኤል ቅዱስ የተናገረውንም ቃል አቃልለዋል።

25የእግዚአብሔር ቍጣ በሕዝቡ ላይ ነድዷል፤

እጁን አንሥቶ መትቷቸዋል፤

ተራሮች ራዱ፤

ሬሳዎችም በመንገድ ላይ እንደ ተጣለ ጥራጊ ሆኑ፤

ይህ ሁሉ ሆኖ ግን ቍጣው ገና አልተመለሰም፤

እጁም እንደ ተነሣ ነው።

26ከሩቅ ያሉትን ሕዝቦች የሚጠራበትን

ምልክት ያቆማል፤

ከምድር ዳርቻም በፉጨት ይጠራቸዋል፤

እነርሱም እየተጣደፉ በፍጥነት ይመጣሉ።

27በመካከላቸው ደካማና ስንኩል አይገኝም፤

የሚያንቀላፋና የሚተኛ አይኖርም፤

የወገባቸው መቀነት አይላላም፤

የጫማቸውም ማሰሪያ አይበጠስም።

28ፍላጻቸው የተሳለ፣

ቀስታቸውም የተደገነ ነው፤

የሠረገሎቻቸውም መንኰራኵሮች እንደ

ዐውሎ ነፋስ ናቸው።

29ጩኸታቸው እንደ አንበሳ ነው፤

እንደ አንበሳ ደቦል ያገሣሉ፤

ያደኑትንም ይዘው ይጮኻሉ፤

ተሸክመውት ይሄዳሉ፤ የሚያስጥልም የለም።

30በዚያን ቀን

እንደ ባሕር ሞገድ ይጮኹበታል፤

ማንም ወደ ምድር ቢመለከት፣

ጨለማንና መከራን ያያል፤

ብርሃን እንኳ በደመናዎች ይጋረዳል።