Isaiah 39 – YCB & NIVUK

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 39:1-8

Àwọn ikọ̀ ọba láti Babeli

139.1-8: 2Ọb 20.12-19; 2Ki 32.31.Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn. 2Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.

3Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”

“Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”

4Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”

Hesekiah si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”

5Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 6Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí. 7Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”

8Hesekiah wí fún Isaiah pé, “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”

New International Version – UK

Isaiah 39:1-8

Envoys from Babylon

1At that time Marduk-Baladan son of Baladan king of Babylon sent Hezekiah letters and a gift, because he had heard of his illness and recovery. 2Hezekiah received the envoys gladly and showed them what was in his storehouses – the silver, the gold, the spices, the fine olive oil – his entire armoury and everything found among his treasures. There was nothing in his palace or in all his kingdom that Hezekiah did not show them.

3Then Isaiah the prophet went to King Hezekiah and asked, ‘What did those men say, and where did they come from?’

‘From a distant land,’ Hezekiah replied. ‘They came to me from Babylon.’

4The prophet asked, ‘What did they see in your palace?’

‘They saw everything in my palace,’ Hezekiah said. ‘There is nothing among my treasures that I did not show them.’

5Then Isaiah said to Hezekiah, ‘Hear the word of the Lord Almighty: 6the time will surely come when everything in your palace, and all that your predecessors have stored up until this day, will be carried off to Babylon. Nothing will be left, says the Lord. 7And some of your descendants, your own flesh and blood who will be born to you, will be taken away, and they will become eunuchs in the palace of the king of Babylon.’

8‘The word of the Lord you have spoken is good,’ Hezekiah replied. For he thought, ‘There will be peace and security in my lifetime.’