Isaiah 38 – YCB & CARS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 38:1-22

Àìsàn Hesekiah

1Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”

2Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa, 3“Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.

4Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Isaiah wá pé, 5“Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé, Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. 6Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.

7“ ‘Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fihàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. 8Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

9Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán.

10Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi

èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú

kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

11Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,

àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;

èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́,

tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń

gbe orílẹ̀ ayé báyìí.

12Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn,

ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.

Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;

ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

13Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́,

ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;

ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

14Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀,

èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.

Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.

Ìdààmú bá mi, Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

15Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?

Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun

tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.

Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi

nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.

16Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;

àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú.

Ìwọ dá ìlera mi padà

kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.

17Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni,

ní ti pé mo ní ìkorò ńlá.

Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́,

kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;

ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.

18Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,

ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;

àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun

kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.

19Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,

gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;

àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

20Olúwa yóò gbà mí là

bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn

ní gbogbo ọjọ́ ayé wa

nínú tẹmpili ti Olúwa.

21Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”

22Hesekiah sì béèrè pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa?”

Священное Писание

Исаия 38:1-22

Болезнь и исцеление Езекии

(4 Цар. 20:1-11; 2 Лет. 32:24)

1В те дни Езекия заболел и был при смерти. Пророк Исаия, сын Амоца, пришёл к нему и сказал:

– Так говорит Вечный: «Распорядись своим домом, потому что ты умираешь; ты не выздоровеешь».

2Езекия отвернулся лицом к стене и взмолился Вечному:

3– Вспомни, о Вечный, как я верно служил Тебе от всего сердца и делал то, что было угодным в Твоих глазах!

И Езекия горько заплакал.

4Тогда к Исаии было слово Вечного:

5– Иди и скажи Езекии: Так говорит Вечный, Бог твоего предка Давуда: «Я услышал твою молитву и увидел твои слёзы; Я прибавлю к твоей жизни пятнадцать лет. 6Я избавлю тебя и этот город от руки царя Ассирии. Я защищу этот город. 7Вот тебе знамение от Вечного, что Вечный исполнит то, что обещал: 8Я отведу тень, которую заходящее солнце отбрасывает на лестницу Ахаза, на десять ступеней назад».

И солнце вернулось по лестнице Ахаза на те десять ступеней, которые оно прошло.

Молитва Езекии после его выздоровления

9Запись Езекии, царя Иудеи, после его болезни и выздоровления:

10Я сказал: «Неужели в расцвете дней

суждено мне пройти через ворота мира мёртвых,

и остатка лет я лишён?»

11Я сказал: «Я уже не увижу Вечного,

Вечного на земле живых;

не увижу больше людей,

не буду среди обитателей мира.

12Мой дом, как пастуший шатёр,

снят с места и уносится от меня.

Я скатал свою жизнь, как ткач – полотно;

Он отрежет меня от станка.

День и ночь Ты ведёшь меня к смерти!

13Я кричу о помощи до утра,

а Он, словно лев, ломает все кости мои.

День и ночь Ты ведёшь меня к смерти!

14Я кричу, словно ласточка или журавль,

и стенаю, как голубь.

Утомились глаза мои, глядя ввысь.

Я в беде! Помоги мне, Вечный!»

15Но что мне сказать?

Как Он мне говорил, так и сделал.

Буду в смирении проводить все мои годы,

помня скорбь моей души.

16Мой Владыка, этим живут люди,

этим живу и я.

Ты исцелил меня

и позволил мне жить.

17Да, во благо была мне такая мука;

Ты сохранил мою жизнь от гибельной пропасти,

все мои грехи бросил Себе за спину.

18Ведь мир мёртвых не славит Тебя,

смерть не воспоёт Тебе хвалы;

тем, кто спускается в пропасть,

нет надежды на Твою верность.

19Живые, лишь живые Тебя восславят,

как сегодня делаю я;

отцы расскажут детям

о Твоей верности.

20Вечный спасёт меня,

и под звуки струн мы будем петь

во все дни нашей жизни

в храме Вечного!

21Исаия сказал:

– Пусть возьмут пласт инжира, приложат его к нарыву, и царь выздоровеет.

22А Езекия спросил:

– Каково знамение, что я пойду в храм Вечного?