Isaiah 27 – YCB & NAV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 27:1-13

Ìdáǹdè Israẹli

1Ní ọjọ́ náà,

Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà

idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára

Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,

Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;

Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.

2Ní ọjọ́ náà,

“Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.

3Èmi Olúwa ń bojútó o,

Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà.

Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru

kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.

4Inú kò bí mi.

Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!

Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun,

Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.

5Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;

jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,

bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”

6Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,

Israẹli yóò tanná yóò sì rudi

èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.

7Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú

gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?

Ǹjẹ́ a ti pa á

gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?

8Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó

fi dojúkọ ọ́

pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,

gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́.

9Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà

fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,

èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti

ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ

dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,

kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí

tí yóò wà ní ìdúró.

10Ìlú olódi náà ti dahoro,

ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì

gẹ́gẹ́ bí aginjù;

níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko

níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;

wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.

11Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù

àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná

nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́,

nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn;

bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.

12Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 1327.13: Mt 24.31; 1Kọ 15.52; 1Tẹ 4.16.Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Ketab El Hayat

إشعياء 27:1-13

خلاص إسرائيل

1فِي ذَلِكَ الْيَوْمِ يُعَاقِبُ الرَّبُّ بِسَيْفِهِ الْقَاسِي الْعَظِيمِ الْمَتِينِ لَوِيَاثَانَ الْحَيَّةَ الْهَارِبَةَ الْمُتَلَوِّيَةَ، وَيَقْتُلُ التِّنِّينَ الَّذِي فِي الْبَحْرِ.

2فِي ذَلِكَ الْيَوْمِ غَنُّوا لِشَعْبِي، الْكَرْمَةِ الْمُشْتَهَاةِ، 3فَأَنَا الرَّبُّ رَاعِيهَا أُرْوِيهَا فِي كُلِّ لَحْظَةٍ، وَأَحْرُسُهَا لَيْلَ نَهَارَ لِئَلَّا يُتْلِفَهَا أَحَدٌ. 4لَسْتُ أُضْمِرُ غَيْظاً، وَمَنْ قَاوَمَنِي بِالْشَّوْكِ وَالْحَسَكِ فَإِنَّنِي أَهْجُمُ عَلَيْهِمْ جَمِيعاً وَأَحْرِقُهُمْ. 5أَوْ لِيَسْتَجِيرُوا بِحِمَايَتِي وَلْيَعْقِدُوا مَعِي سَلاماً؛ أَجَلْ! لِيَعْقِدُوا مَعِي سَلاماً.

6وَيَتَأَصَّلُ يَعْقُوبُ فِي الأَيَّامِ الْمُقْبِلَةِ وَيُزْهِرُ إِسْرَائِيلُ، وَيُنْبِتُ فُرُوعاً تَمْلَأُ الأَرْضَ كُلَّهَا بِالثِّمَارِ. 7هَلْ ضَرَبَهُ الرَّبُّ كَمَا ضَرَبَ ضَارِبِيهِ، أَمْ هَلَكَ كَمَا هَلَكَ قَاتِلُوهُ؟ 8عَاقَبْتَهُ إِذْ خَاصَمْتَهُ وَنَفَيْتَهُ بِنَفْخَةٍ عَاصِفَةٍ فِي يَوْمِ هُبُوبِ رِيحٍ شَرْقِيَّةٍ. 9لِهَذَا يُكَفَّرُ عَنْ إِثْمِ يَعْقُوبَ، وَيَكُونُ هَذَا هُوَ كُلُّ ثَمَرِ مَحْوِ خَطِيئَتِهِ، عِنْدَمَا يَجْعَلُ جَمِيعَ حِجَارَةِ الْمَذْبَحِ كَحِجَارَةِ الْكِلْسِ الْمَسْحُوقَةِ، وَلا يَبْقَى تِمْثَالٌ لِعَشْتَارُوثَ أَوْ مَذْبَحٌ قَائِماً.

10لأَنَّ الْمَدِينَةَ الْمَنِيعَةَ تُصْبِحُ مُقْفِرَةً، وَيُصْبِحُ الْمَسْكِنُ مَهْجُوراً مَتْرُوكاً كَالْقَفْرِ. وَهُنَاكَ يَرْعَى الْعِجْلُ وَيَرْبِضُ وَيَقْرِضُ أَغْصَانَهَا. 11وَمَتَى يَبِسَتْ فُرُوعُهَا تَتَكَسَّرُ، فَتُقْبِلُ النِّسَاءُ وَيَسْتَخْدِمْنَهَا وَقُوداً لِلنَّارِ. لأَنَّ هَذَا شَعْبٌ جَاهِلٌ، لِذَلِكَ لَا يَرْحَمُهُ صَانِعُهُ وَلا يَرْفُقُ بِهِ خَالِقُهُ.

12فِي ذَلِكَ الْيَوْمِ يَنْتَقِيكُمُ الرَّبُّ مِنْ مَجْرَى الْفُرَاتِ إِلَى وَادِي النِّيلِ، كَمَا يُنْتَقَى الْقَمْحُ، وَيَجْمَعُكُمْ وَاحِداً فَوَاحِداً يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ. 13فِي ذَلِكَ الْيَوْمِ يَنْفُخُ فِي بُوقٍ عَظِيمٍ فَيَأْتِي التَّائِهُونَ فِي أَرْضِ أَشُورَ، وَالْمَنْفِيُّونَ إِلَى دِيَارِ مِصْرَ، لِيَسْجُدُوا لِلرَّبِّ فِي جَبَلِ قُدْسِهِ، فِي أُورُشَلِيمَ.