Isaiah 26 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 26:1-21

Orin ìyìn kan

1Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda.

Àwa ní ìlú alágbára kan,

Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe

ògiri àti ààbò rẹ̀.

2Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn

kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,

orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.

3Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé

ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,

nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,

nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.

5Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀

ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;

ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ

ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

6Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀

ẹsẹ̀ aninilára n nì,

ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.

7Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú,

ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà

àwọn olódodo ṣe geere.

8Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ

àwa dúró dè ọ́;

orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ

àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.

9Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;

ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.

Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé

àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà

wọn kò kọ́ láti sọ òdodo;

kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n

tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi

wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.

11Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè

ṣùgbọ́n àwọn kò rí i.

Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ

kí ojú kí ó tì wọ́n;

jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn

ọ̀tá rẹ jó wọn run.

12Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;

ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni

ó ṣe é fún wa.

13Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn

lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí,

ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.

14Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́;

gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.

Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,

ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.

15Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa;

ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.

Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;

ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.

16Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn;

nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn,

wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

17Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ

tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa.

18Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora,

ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ.

Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé;

àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.

19Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè

ara wọn yóò dìde.

Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,

dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.

Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,

ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.

20Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ

kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín,

ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀

títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá.

21Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀

láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀;

kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

以賽亞書 26:1-21

猶大的凱歌

1到那日,猶大境內的人必唱這首歌:

「我們有一座堅城,

耶和華使祂的拯救成為保護我們的城牆和屏障。

2打開城門,

讓忠信的公義之民進來。

3你使堅信不移的人全然平安,

因為他們信靠你。

4要永遠信靠耶和華,

因為耶和華是永遠屹立的磐石。

5祂貶抑高傲的人,

拆毀他們高聳的城邑,

把它們夷為平地、化為塵土,

6被困苦人的腳踐踏,被貧窮人的足踩踏。」

7義人的道路是平坦的,

公正的主啊,你必修平義人所走的道路。

8耶和華啊,我們等候你,

遵從你的法令,

我們心裡渴慕尊崇你的名。

9在夜間,我思慕你,

我切切地尋求你。

你在世上施行審判的時候,

世人就知道何為公義。

10你恩待惡人,

但他們仍然不學習行義。

即使在公義之地,

他們依然作惡,

全不把耶和華的威嚴放在眼裡。

11你懲罰的手高高舉起,

他們卻看不見。

願他們因看見你向你子民所發的熱心而感到羞愧。

願你為敵人預備的火燒滅他們。

12耶和華啊,你必賜我們平安,

因為我們所做的事都是你為我們成就的。

13我們的上帝耶和華啊!

在你以外曾有別的主人管轄我們,

但我們只尊崇你的名。

14他們都已死去,再不能復生,

逝去的靈魂不能回來。

因為你懲罰他們,毀滅他們,

使他們被人徹底遺忘。

15耶和華啊,你增添我們的人口,

增添我們的人口,

擴張我們的疆界,

你得到了榮耀。

16耶和華啊,我們是你的子民,

我們在危難中尋求你。

你管教我們的時候,

我們就向你祈求。

17耶和華啊,我們在你面前呼求,

如臨產的婦人在陣痛中喊叫。

18我們曾懷胎,痛苦呻吟,

但產下來的卻是一陣風。

我們沒有給世界帶來拯救,

也沒有給世上帶來生命。

19然而,屬你的人必復活,

他們的屍體必站起來。

睡在塵土中的人必醒來歡唱!

你必使死人復活,

如清晨的甘露使大地恢復生機。

20我的百姓啊,

回到你們的房子裡,

關上門躲藏一會兒,

等耶和華的憤怒平息。

21看啊,耶和華要走出祂的居所,

懲罰世上犯罪的人。

大地必不再隱藏被殺之人的屍首,

必將所流的血顯露出來。