Isaiah 20 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 20:1-6

Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Ejibiti àti Kuṣi

1Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o— 2ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.

3Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi, 4bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti. 5Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi Ejibiti yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n. 6Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Asiria! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”

Bibelen på hverdagsdansk

Esajasʼ Bog 20:1-6

Assyrerne vil erobre Egypten og Kush

1Det år, da assyrerkongen Sargon sendte sin hærfører mod filisterbyen Ashdod og angreb og erobrede den, 2sagde Herren til Esajas: „Tag både dit tøj og dine sandaler af.” Esajas gjorde, som Herren havde sagt, og gik nøgen og barfodet omkring.

3Lang tid senere sagde Herren: „Min tjener Esajas har nu gået nøgen og barfodet omkring i tre år som et symbol på, hvad der vil ske med Egypten og Kush.20,3 Kush svarer til det nordlige Sudan plus muligvis en del af det nuværende Eritrea og Etiopien. 4Assyrerkongen vil nemlig bortføre de to landes befolkninger som fanger, og han vil lade dem gå nøgne og barfodede af sted, både unge og gamle, så deres blottede bagdel bringer skam over Egypten.” 5-6Folkeslagene langs havets kyst, som satte deres lid til en alliance med Egypten og Kush, vil blive forfærdede og sige: „Hvis det kan gå så galt for dem, hvordan vil det så gå for os? Vi troede, at Egypten kunne beskytte os imod assyrerkongen.”