Isaiah 11 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 11:1-16

Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese

111.1: Isa 11.10; Ro 15.12.Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese,

láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.

211.2: 1Pt 4.14.Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e,

ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye,

ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,

ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa.

3Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.

Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,

tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

4ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,

pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu

fún àwọn aláìní ayé.

Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,

pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

511.5: Ef 6.14.Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀

àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

611.6-9: Isa 65.25; Hk 2.14.Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,

ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́

ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún

àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀

ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.

7Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,

àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,

kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko

gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.

8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,

ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.

9Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run

ní gbogbo òkè mímọ́ mi,

nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa

gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.

1011.10: Isa 11.1; Ro 15.12.Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.

12Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,

yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,

yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,

láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.

13Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,

àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,

Efraimu kò ní jowú Juda,

tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.

14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini

sí apá ìwọ̀-oòrùn,

wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn

ènìyàn apá ìlà-oòrùn.

Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,

àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.

15Olúwa yóò sọ di gbígbé

àyasí Òkun Ejibiti,

pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,

kọjá lórí odò Eufurate.

Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje

tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn

yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.

16Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù

tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,

gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli

nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.

Korean Living Bible

이사야 11:1-16

111:1 원문에는 ‘이새의 줄기에서 한 싹이 나며 그 뿌리에서 한 가지가 나서 결실할 것이요’다윗 왕족의 혈통은 잘라진 나무처럼 끊어질 것이지만 줄기에서 새 순 이 돋고 뿌리에서 새 가지가 나오듯이 다윗의 후손 가운데서 한 새로운 왕이 일어날 것이다.

이새의 후손

2여호와의 성령께서 그에게 자기 백성을 다스릴 지혜와 지식과 재능을 주실 것이며 그는 여호와의 뜻을 알고 그를 두려운 마음으로 섬길 것이며

3그에게 순종하는 것을 즐거움으로 여길 것이다. 그는 눈에 보이는 외모나 귀에 들리는 소문으로 심판하지 않을 것이며

4가난하고 힘없는 자들을 옹호하고 세상의 악인들을 쳐서 죽이실 것이며

5정의와 성실로 자기 백성을 다스릴 것이다.

6그때 이리와 어린 양이 함께 살며 표범이 어린 염소와 함께 눕고 송아지와 사자 새끼가 함께 먹으며 어린 아이들이 그것들을 돌볼 것이다.

7그리고 암소와 곰이 함께 먹고 그 새끼들이 함께 누울 것이며 사자가 소처럼 풀을 먹고

8젖먹이가 독사 곁에서 놀며 어린 아이들이 독사 굴에 손을 넣어도 해를 입지 않을 것이다.

9하나님의 거룩한 산 시온에는 해로운 것이나 악한 것이 아무것도 없을 것이다. 이것은 바다에 물이 가득하듯이 세상에 여호와를 아는 지식이 충만할 것이기 때문이다.

10그 날에 11:10 원문에는 ‘이새의 뿌리’이새의 후손이 온 세계에 구원의 상징이 될 것이며 모든 민족이 그에게 모여들 것이요 그가 사는 땅은 영광스러운 곳이 될 것이다.

11그때 여호와께서 다시 능력을 나타내셔서 앗시리아, 이집트, 에티오피아, 엘람, 바빌로니아, 하맛, 그리고 여러 섬과 해안 지역에서 자기 백성을 돌아오게 하실 것이다.

12여호와께서 온 세계를 향하여 기를 세우시고 세계 각처에 흩어져 있는 이스라엘 사람들을 다시 모으실 것이다.

13그 때에는 유다와 이스라엘이 서로 질투하는 일이 없을 것이며 더 이상 싸우지도 않을 것이다.

14그들은 합세하여 서쪽으로 블레셋을 치고 동쪽에 사는 사람들을 약탈하며 에돔과 모압과 암몬을 정복할 것이다.

15여호와께서 홍해를 말리시고 뜨거운 바람을 일으켜 유프라테스강을 일곱 갈래로 나눠 사람이 걸어서 건너갈 수 있게 하실 것이다.

16그가 살아 남은 자기 백성을 위해 앗시리아에서부터 대로를 만들 것이니 이스라엘 민족이 이집트를 떠나올 때와 같을 것이다.