Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Hosea 1:1-11

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli:

Ìdílé Hosea

2Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.” 3Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.

4Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin. 5Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní Àfonífojì Jesreeli.”

61.6,9: Ho 2.23; 1Pt 2.10.Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n. 7Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”

8Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-rúhámà, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni 9Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.

10“Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ 11Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

何西阿書 1:1-11

1烏西雅約坦亞哈斯希西迦猶大王,約阿施的兒子耶羅波安以色列王期間,耶和華將祂的話傳給備利的兒子何西阿

何西阿娶妓女為妻

2耶和華首次向何西阿說話時,對他說:「你去娶一個妓女為妻,和她生養兒女,因為這片土地上的人極其淫亂,背棄了耶和華。」 3於是,何西阿娶了滴拉音的女兒歌蜜為妻,她懷孕為他生了一個兒子。 4耶和華對何西阿說:「給他取名叫耶斯列1·4 耶斯列」意思是「上帝撒種」。此處指上帝要像撒種一樣驅散以色列人,但在1·11指上帝要賜福他們,就像撒種後獲得了大豐收。,因為再過不久,我就要因耶戶家在耶斯列的屠殺而懲罰他們,消滅以色列國。 5那時,我要在耶斯列平原折斷以色列的弓。」 6後來,歌蜜又懷孕生了一個女兒。耶和華對何西阿說:「給她取名叫羅·路哈瑪1·6 羅·路哈瑪」意思是「不蒙憐憫」。,因為我將不再憐憫以色列家,也不再赦免他們的罪。 7但我要憐憫猶大家,使他們依靠他們的上帝耶和華得到拯救,而不是依靠戰弓、刀劍、馬匹、騎兵和戰爭。」 8羅·路哈瑪斷奶後,歌蜜又懷孕生了一個兒子。 9耶和華說:「給他取名叫羅·阿米1·9 羅·阿米」意思是「不是我的子民」。,因為以色列人不再是我的子民,我也不再是他們的上帝。

以色列的復興

10「然而,以色列的人數必像海沙一樣量不盡、數不完。從前我在什麼地方對他們說『你們不是我的子民』,將來也要在那裡對他們說『你們是永活上帝的兒女』。 11那時,猶大人和以色列人將被聚集起來,為自己選立一位首領,從流亡之地返回故鄉,安居樂業。耶斯列的日子將是偉大的日子。