Hosea 1 – YCB & APSD-CEB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Hosea 1:1-11

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli.

Ìdílé Hosea

2Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.” 3Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.

4Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin. 5Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní àfonífojì Jesreeli.”

61.6,9: Ho 2.23; 1Pt 2.10.Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ruhama, nítorí pé, Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n. 7Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”

8Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-ruhama, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni 9Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.

10“Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ 11Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.

Ang Pulong Sa Dios

Hosea 1:1-11

1Mao kini ang mensahe nga gipadayag sa Ginoo kang Hosea nga anak ni Beeri, sa mga panahon nga naghari sa Juda sila si Uzia, Jotham, Ahaz, ug Hezekia, ug sa panahon nga naghari sa Israel si Jeroboam nga anak ni Joas.

Ang Asawa ug mga Anak ni Hosea

2Ang unang gisulti sa Ginoo kang Hosea mao kini: “Pangasawa ug babayeng maluibon,1:2 maluibon: o, nagabaligya sa iyang dungog. ug ang inyong mga anak isipon nga mga anak sa babayeng maluibon. Kay sama kaniya, ang akong mga katawhan daw nanapaw usab pinaagi sa ilang pagsalikway sa Ginoo ug sa pagsimba sa mga dios-dios.”

3Busa gipangasawa ni Hosea si Gomer nga anak ni Diblaim, ug nagmabdos si Gomer ug nanganak ug lalaki. 4Miingon ang Ginoo kang Hosea, “Nganli ang bata ug Jezreel,1:4 Jezreel: Ang buot ipasabot sa Hebreo, nagasabwag ang Dios, nga nagkahulogan sa pagtubo ug kauswagan (tan-awa ang bersikulo 11). Apan niini nga bersikulo, kining ngalana nagakahulogan nga patibulaagon sa Dios ang mga Israelinhon tungod sa ilang kadaotan. kay sa dili madugay silotan ko ang hari sa Israel tungod sa mga pagpamatay nga gihimo sa iyang katigulangan nga si Jehu didto sa lungsod sa Jezreel. Ug wagtangon ko ang gingharian sa Israel. 5Nianang panahona ipapildi ko ang mga sundalo sa Israel didto sa Kapatagan sa Jezreel.”

6Nagmabdos pag-usab si Gomer ug nanganak ug babaye. Miingon ang Ginoo kang Hosea, “Nganli ang bata ug Lo Ruhama,1:6 Lo Ruhama: Ang buot ipasabot sa Hebreo, wala kaloy-i. kay dili ko na kaloy-an o pasayloon ang katawhan sa Israel. 7Apan kaloy-an ko ang katawhan sa Juda. Ako, ang Ginoo nga ilang Dios, moluwas kanila pinaagi sa akong gahom ug dili pinaagi sa gira—sa pana, sa espada, sa mga kabayo o sa mga tigkabayo.”

8Sa dihang nalutas na ni Gomer ang iyang anak nga si Lo Ruhama, nagmabdos siya pag-usab ug nanganak ug lalaki. 9Miingon ang Ginoo kang Hosea, “Nganli ang bata ug Lo Ami,1:9 Lo Ami: Ang buot ipasabot sa Hebreo, dili akong katawhan. kay kamong mga Israelinhon dili akong katawhan ug ako dili inyong Dios. 10Apan moabot ang panahon nga mahisama kamo kadaghan sa balas sa baybayon nga dili masukod o maihap. Sa dapit diin gitawag kamo nga, ‘Dili akong katawhan,’ pagatawgon unya kamo nga, ‘Mga anak sa buhi nga Dios.’ 11Mahiusa pag-usab ang mga katawhan sa Juda ug sa Israel, ug magpili sila ug usa ka pangulo. Mouswag sila pag-usab sa ilang yuta. Pagkamalipayon gayod unya nianang panahona alang sa lungsod sa Jezreel.