Heberu 8 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 8:1-13

Olórí àlùfáà ti májẹ̀mú tuntun

18.1: Sm 110.1.Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí. Àwa ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọláńlá nínú àwọn ọ̀run, 2Ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tòótọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.

3Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rú ẹbọ, nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀. 4Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀. 58.5: Ek 25.40.Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́, nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.” 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

7Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì. 88.8-12: Jr 31.31-34.Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé,

“Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí,

tí Èmi yóò bá ilé Israẹli

àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.

9Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú

tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá,

nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde

kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi

èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí.

10Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli

dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.

Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,

èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,

èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,

wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.

11Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,

tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Olúwa,’

nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,

láti kékeré dé àgbà.

12Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn,

àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”

13Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.

New Amharic Standard Version

ዕብራውያን 8:1-13

የአዲስ ኪዳን ሊቀ ካህናት

1እንግዲህ የምንናገረው ዋናው ነገር ይህ ነው፤ በሰማያት በግርማው ዙፋን ቀኝ የተቀመጠ እንዲህ ያለ ሊቀ ካህናት አለን፤ 2እርሱም በሰው ሳይሆን በጌታ በተተከለችው፣ እውነተኛ ድንኳን በሆነችው ቤተ መቅደስ አገልጋይ ነው።

3እያንዳንዱ ሊቀ ካህናት የሚሾመው መባንና መሥዋዕትን ለማቅረብ ነው፤ ስለዚህ ይህኛውም ሊቀ ካህን የሚያቀርበው ነገር ያስፈልገዋል። 4እርሱ በምድር ቢኖር ኖሮ ካህን ባልሆነም ነበር፤ ምክንያቱም በሕግ በታዘዘው መሠረት መባን የሚያቀርቡ ሰዎች አሉ። 5እነርሱ ያገለገሉት በሰማይ ላለችው መቅደስ ምሳሌና ጥላ በሆነችው ውስጥ ነው፤ ሙሴ ድንኳኒቱን ለመሥራት በተነሣ ጊዜ፣ “በተራራው ላይ በተገለጠልህ ምሳሌ መሠረት ሁሉን ነገር እንድታደርግ ተጠንቀቅ” የሚል ትእዛዝ የተሰጠው በዚህ ምክንያት ነበር። 6ነገር ግን ኢየሱስ መካከለኛ የሆነበት ኪዳን ከቀድሞው እንደሚበልጥ ሁሉ፣ የተቀበለውም አገልግሎት ከእነርሱ አገልግሎት ይበልጣል፤ ይህም የተመሠረተው በተሻለ የተስፋ ቃል ላይ ነው።

7የመጀመሪያው ኪዳን ምንም ጕድለት ባይገኝበት ኖሮ፣ ለሁለተኛው ስፍራ ባልተፈለገም ነበር። 8ነገር ግን እግዚአብሔር በሕዝቡ ላይ ጕድለት በማግኘቱ እንዲህ ይላቸዋል8፥8 አንዳንድ የጥንት ቅጆች ጕድለት በማግኘቱ ለሕዝቡ እንዲህ ይላቸዋል

“ከእስራኤል ቤት ጋር፣

ከይሁዳም ቤት ጋር፣

አዲስ ኪዳን የምገባበት፣

ጊዜ ይመጣል፤ ይላል ጌታ።

9ይህም እነርሱን ከግብፅ ምድር

ለማውጣት እጃቸውን በያዝሁ ጊዜ፣

ከቀድሞ አባቶቻቸው ጋር እንደ ገባሁት ኪዳን አይደለም፤

ምክንያቱም እነርሱ በኪዳኔ አልጸኑም፤

እኔም ከእነርሱ ዘወር አልሁ፤

ይላል ጌታ።

10ከዚያን ጊዜ በኋላ፣

ከእስራኤል ቤት ጋር የምገባው ኪዳን ይህ ነው፤ ይላል ጌታ፤

ሕጌን በአእምሯቸው አኖራለሁ፤

በልባቸውም እጽፈዋለሁ።

እኔ አምላካቸው እሆናለሁ፤

እነርሱም ሕዝቤ ይሆናሉ።

11ከእንግዲህ ማንም ሰው ጎረቤቱን

ወይም ወንድሙን፣ ‘ጌታን ዕወቅ’ ብሎ አያስተምርም፤

ምክንያቱም ከታናሹ ጀምሮ እስከ ታላቁ ድረስ፣

ሁሉም ያውቁኛል።

12በደላቸውን ይቅር እላለሁ፤ ኀጢአታቸውን

ከእንግዲህ አላስብም።”

13ይህን ኪዳን፣ “አዲስ” በማለቱ የፊተኛውን ኪዳን አሮጌ አድርጎታል፤ ስለዚህ ያረጀ ያፈጀው የሚጠፋበት ጊዜ ተቃርቧል።