Heberu 12 – YCB & SZ-PL

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 12:1-29

Ìbáwí àwọn Ọmọ Ọlọ́run

1Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, 212.2: Sm 110.1.kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. 3Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìsọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

4Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. 512.5-8: Òw 3.11-12.Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,

“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,

kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí,

6nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,

a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”

7Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí, Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? 8Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. 9Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n Òun tọ́ wa fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.

1212.12: Isa 35.3.Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera, 1312.13: Òw 4.26.“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.

Ìkìlọ̀ lòdì sí kíkọ Ọlọ́run

14Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa. 1512.15: De 29.18.Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí gbòǹgbò ìkorò kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 1612.16: Gẹ 25.29-34.Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 1712.17: Gẹ 27.30-40.Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi.

1812.18-19: Ek 19.12-22; 20.18-21; De 4.11-12; 5.22-27.Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì. 19Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́, 2012.20: Ek 19.12-13.nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.” 2112.21: De 9.19.Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”

22Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye, 23si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, 2412.24: Gẹ 4.10.àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ.

2512.25: Ek 20.19.Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀yìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá, 2612.26: Hg 2.6.ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà, ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” 27Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.

28Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. 2912.29: De 4.24.Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”

Słowo Życia

Hebrajczyków 12:1-29

Bóg nas wychowuje

1Skoro otacza nas tak wielu ludzi wiary, odrzućmy wszystko, co nam przeszkadza—a zwłaszcza grzech—i wytrwale biegnijmy do mety w tych zawodach życia. 2Wpatrujmy się w Jezusa, który jest początkiem i celem naszej wiary. On zgodził się ponieść haniebną śmierć na krzyżu, bo wiedział, jaka potem spotka Go radość. Teraz zaś zasiada w niebie, po prawej stronie Boga. 3Pomyślcie jednak, jaką wrogość okazali Mu wcześniej grzeszni ludzie! I nie pozwólcie, aby cokolwiek zniechęciło was lub doprowadziło do upadku! 4Przecież dotychczas, w walce z grzechem, nie musieliście przelewać ani kropli krwi.

5Nie zapominajcie o wezwaniu, które Bóg skierował do was, jako do swoich dzieci:

„Moje dziecko,

gdy Pan wymierza ci karę,

nie lekceważ tego.

A gdy zwraca ci uwagę na grzech,

nie załamuj się.

6Pan bowiem karze wszystkich,

których kocha,

i dyscyplinuje tych,

których uważa za swoje dzieci”.

7Bądźcie cierpliwi, gdy Bóg wymierza wam karę, znaczy to bowiem, że postępuje z wami jak ze swoimi dziećmi. Czy istnieje dziecko, które jeszcze nigdy nie było ukarane przez swojego ojca? 8Jeśli nigdy nie byliście karani przez Boga—a przecież dyscyplinuje On wszystkich wierzących—to znaczy, że nie jesteście Jego prawdziwymi dziećmi!

9Gdy byliśmy dziećmi, nasi ojcowie wymierzali nam kary, a przecież szanujemy ich. Czy nie powinniśmy więc pozwolić naszemu duchowemu Ojcu, aby On również wychowywał nas i prowadził do wiecznego życia? 10Ojcowie karali nas, aby jak najlepiej przygotować nas do krótkiego przecież życia na tym świecie. Bóg zaś czyni to dla naszego dobra, abyśmy byli święci—tak jak On! 11Gdy spotyka nas kara, nie czujemy radości, ale ból. Potem jednak, dzięki tej karze, w naszym życiu pojawia się pokój i prawość.

12Podnieście więc osłabione ręce, wyprostujcie zdrętwiałe kolana 13i idźcie prostą drogą. A wtedy ci, którzy kroczą za wami, nawet jeśli kuleją, nie upadną, ale również nabiorą sił.

Ostrzeżenie przed odrzuceniem Bożej łaski

14Żyjcie ze wszystkim w zgodzie i prowadźcie święte życie, bez tego bowiem nikt nie zobaczy Pana. 15Uważajcie też, aby nikt z was nie pozbawił się Bożej łaski. Nie pozwólcie też, aby w waszych sercach zakorzeniło się i rozrosło zgorzknienie, szkodzące innym ludziom. 16Niech nikt z was nie będzie tak niemoralny lub bezbożny jak Ezaw, który za jeden posiłek sprzedał prawo do szczególnego błogosławieństwa, które—jako najstarszy syn—miał otrzymać od swojego ojca. 17Wiecie przecież, że potem, gdy je chciał odzyskać, został odrzucony. Gorzko żałował swojego czynu, ale było już za późno na jakąkolwiek zmianę.

Majestat Boga

18Nie zbliżyliście się do góry Synaj, której można dotknąć. Nie widzieliście też buchającego z niej ognia, nie zobaczyliście też ciemności, mroku i strasznej burzy, 19nie słyszeliście również dźwięku trąby i potężnego głosu.

Izraelici, gdy usłyszeli ten głos, błagali, aby zamilkł. 20Przeraził ich bowiem nakaz:

„Nawet zwierzę, które dotknie tej góry,

musi zostać ukarane śmiercią”.

21Wszystko to było tak przerażające, że nawet Mojżesz powiedział: „Cały trzęsę się ze strachu!”.

22Wy jednak zbliżyliście się do góry Syjon i do miasta żywego Boga, czyli do niebiańskiej Jerozolimy. W mieście tym niezliczone rzesze aniołów uczestniczą w uroczystym zgromadzeniu. 23Są tam także ci, którzy jako pierwsi zostali wybrani przez Boga i których imiona zostały zapisane w niebie. Jest tam również sam Bóg, który jest sędzią wszystkich ludzi. Są tam także duchy prawych, którzy osiągnęli już doskonałość. 24W mieście tym jest również obecny Jezus—pośrednik nowego przymierza, którego przelana krew znaczy wiele więcej niż krew Abla.

25Uważajcie, żeby nie odwrócić się od Tego, który do was przemawia. Izraelici nie słuchali Mojżesza, który mówił do nich tu, na ziemi—i nie uniknęli kary. Jeśli więc my odwrócimy się od Tego, który przemawia do nas z nieba, tym bardziej zostaniemy za to ukarani przez Boga. 26Za pierwszym razem, gdy Bóg przemówił do ludzi, od Jego głosu zadrżała ziemia. Teraz zaś, zapowiedział On: „Ponownie wstrząsnę ziemią i niebem”. 27Słowo „ponownie” oznacza, że wszystko to, co jest zniszczalne, zostanie przemienione, a przetrwa tylko to, co jest niezniszczalne.

28Skoro więc otrzymaliśmy niezniszczalne królestwo, okazujmy Bogu wdzięczność, cześć i respekt. 29Nasz Bóg jest bowiem tak potężny, jak ogień, który może wszystko pochłonąć.