Heberu 11 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 11:1-40

Nípa ìgbàgbọ́

1Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń retí, ìjẹ́rìí ohun tí a kò rí. 2Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà àtijọ́ ní ẹ̀rí rere.

3Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri.

411.4: Gẹ 4.3-10.Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀, àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.

511.5: Gẹ 5.21-24.Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Enoku ní ipò padà kí o má ṣe rí ikú; a kò sì rí i mọ́, nítorí Ọlọ́run ṣí i ní ipò padà ṣáájú ìṣípò padà rẹ̀, a jẹ́rìí yìí sí i pé o wu Ọlọ́run. 6Ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣe é ṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè ṣàì gbàgbọ́ pé ó ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.

711.7: Gẹ 6.13-22.Nípa ìgbàgbọ́ ni Noa, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tí ì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.

811.8-9: Gẹ 12.1-8.Nípa ìgbàgbọ́ ní Abrahamu, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè. 9Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Isaaki àti Jakọbu, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀, 10nítorí tí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀; èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí ó sì kọ́. 1111.11: Gẹ 17.19; 18.11-14; 21.2.Nípa ìgbàgbọ́ ni Sara tìkára rẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérí sí olóòótọ́. 1211.12: Gẹ 15.5-6; 22.17; 32.12.Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti bí iyanrìn etí Òkun láìníye.

1311.13: Sm 39.12; Gẹ 23.4.Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. 14Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. 15Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà. 1611.16: El 3.6,15; 4.5.Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run, nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.

1711.17: Gẹ 22.1-10.Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ. 1811.18: Gẹ 21.12.Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” 19Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìde kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.

2011.20: Gẹ 27.27-29,39-40.Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀.

2111.21: Gẹ 48; 47.31.Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

2211.22: Gẹ 50.24-25; Ek 13.19.Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.

2311.23: Ek 2.2; 1.22.Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Mose pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí tiwọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

2411.24: Ek 2.10,11-15.Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; 25o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 26Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà. 2711.27: Ek 2.15.Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí. 2811.28: Ek 12.21-28,29-30.Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrékọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má bá a fi ọwọ́ kan wọn.

2911.29: Ek 14.21-31.Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀ ni: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.

3011.30: Jo 6.12-21.Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jeriko wo lulẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ọjọ́ méje.

3111.31: Jo 2.1-21; 6.22-25.Nípa ìgbàgbọ́ ni Rahabu panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́rọ̀ nígbà tí o tẹ́wọ́gbà àwọn àmì ní àlàáfíà.

3211.32: On 6–8; 4–5; 13–16; 11–12; 1Sa 16–30; 2Sa 1–24; 1Ọb 1.1–2.11; 1Sa 1–12; 15.1–16.13.Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì, 3311.33: Da 6.àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tiwọn ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ́ òdodo, tiwọn gba ìlérí, tiwọn dí àwọn kìnnìún lénu, 3411.34: Da 3.tí wọ́n pa agbára iná, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, tí wọ́n dí akọni nínú ìjà, wọ́n lé ogun àwọn àjèjì sá. 3511.35: 1Ọb 17.17-24; 2Ọb 4.25-37.Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà. 36Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú. 37A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn, wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; 38àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún. Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.

39Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà, 40nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.

New Russian Translation

Евреям 11:1-40

О вере

1Вера – это уверенность в том, чего мы с надеждой ожидаем, подтверждение того, чего мы не видим. 2Древние жили такой верой и заслужили одобрение.

3Именно верой мы понимаем, что вселенная была создана по повелению Бога и что все видимое было создано из невидимого.

4Верой Авель принес Богу жертву лучшую, чем Каин. Верой он заслужил одобрение как праведник, когда Бог похвалил его жертву11:4 См. Быт. 4:2-5.. И, хотя Авель умер, он, благодаря своей вере,11:4 Благодаря своей вере—букв. «благодаря ей». все еще говорит.

5Благодаря вере, Енох был взят из этого мира, не увидев смерти. Его нигде не могли найти, потому что Бог взял его. Но до того, как он был взят, он заслужил одобрение как человек, угодивший Богу11:5 См. Быт. 5:18-24..

6Без веры же Богу угодить невозможно, потому что каждый, кто приходит к Нему, должен верить в то, что Он есть и что Он вознаграждает тех, кто Его ищет.

7Верой Ной, получив предупреждение о том, чего еще нельзя было видеть, в благоговении построил ковчег для спасения своей семьи. В результате мир был осужден11:7 Букв.: «ею он осудил мир»., а Ной стал наследником праведности, которая приходит через веру11:7 См. Быт. 6:9-22..

8Верой Авраам, призванный идти в землю, которую ему было обещано получить в будущем в наследие, подчинился и пошел, хотя он и сам не знал, куда идет11:8 См. Быт. 12:1-4; Деян. 7:2-4.. 9Верой он поселился в обещанной земле как чужеземец, живя в палатках, как и Исаак и Иаков, которые вместе с ним были наследниками согласно тому же обещанию, 10потому что он ожидал города, стоящего на прочных основаниях, архитектор и строитель которого Сам Бог11:10 См. 12:22; Отк. 21..

11Верой Авраам стал отцом, хотя и сама Сарра была бесплодна, и он был уже стар, – ведь он полагался на Того, Кто обещал ему11:11 Или: «Верой и сама Сарра, несмотря на то, что была бесплодна, смогла зачать ребенка в столь преклонном возрасте, – ведь она полагалась на Того, Кто обещал ей». См. Быт. 21:1-2.. 12И таким образом, от одного человека, тело которого состарилось, произошло столько людей, сколько звезд в небе и сколько песчинок на берегу моря11:12 См. Быт. 15:5-6; 22:17; 32:12; Ис. 51:2.. 13Все эти люди так и умерли, храня веру, не дождавшись того, что им было обещано. Они лишь издали видели и приветствовали все это. Они признавали, что на этой земле они всего лишь пришельцы и странники11:13 См. Быт. 23:4; 1 Пар. 29:15; Пс. 38:13; 1 Пет. 2:11.. 14Те, кто считает себя таковыми, показывают тем самым, что они ищут свою истинную родину. 15Если бы они думали лишь о той стране, которую им пришлось покинуть, они могли бы в нее и возвратиться. 16Но на самом деле они стремятся к лучшей стране – к небесной. Поэтому Бог не стыдится называться их Богом, ведь Он приготовил для них город.

17Верой Авраам, когда Бог испытывал его, принес Исаака в жертву. Ему было дано обещание, и он готов был принести в жертву своего единственного11:17 Единственный – на языке оригинала это слово, которое можно перевести и как «уникальный», и как «единственный». В данном контексте это слово нужно понимать как «уникальный», в том смысле, что Исаак был обещан Аврааму Богом. сына, 18и это невзирая на то, что Бог сказал ему: «Через Исаака ты будешь иметь потомство11:18 Букв.: «семя»., которое Я тебе обещал»11:18 Быт. 21:12.. 19Авраам считал, что Бог может даже воскрешать из мертвых, и, образно говоря, Исаак был действительно возвращен ему из мертвых.

20Верой Исаак благословил будущее Иакова и Исава11:20 См. Быт. 27..

21Верой Иаков, находясь при смерти, благословил каждого из сыновей Иосифа и поклонился Богу, оперевшись на свой посох11:21 См. Быт. 47:31; 48:1-20..

22Верой Иосиф в конце своей жизни говорил о выходе израильтян из Египта и сделал распоряжение о своих собственных останках11:22 См. Быт. 50:24-25..

23Верой родители Моисея прятали его три месяца после того, как он родился, потому что они видели, что он был прекрасным ребенком, и их не напугал царский указ11:23 См. Исх. 1:22; 2:2; Деян. 7:20..

24Верой Моисей, став взрослым, отказался называться сыном дочери фараона. 25Он предпочел лучше быть притесняемым вместе с народом Божьим, чем наслаждаться кратковременными греховными удовольствиями. 26Он видел, какая награда ждет его впереди, и поэтому унижение ради Христа для него было ценнее богатств Египта. 27Верой он вышел из Египта, не боясь гнева царя. Он вытерпел все, как человек, который видел бы перед собой Невидимого11:27 См. Исх. гл. 2-3; Деян. 7:23-29. 28Верой он совершил Пасху с окроплением дверных косяков кровью, чтобы губитель первенцев не прикоснулся к семьям11:28 Букв.: «к ним». См. Исх. 12:21-23. израильтян.

29Верой народ перешел Красное море11:29 Красное море – Среди современных специалистов существуют различные версии того, о каком водоеме здесь идет речь. Красным морем могли называть как цепи озер, расположенных на Суэцком перешейке и, вероятно, соединявшихся тогда проливами с Красным морем, так и Суэцкий и Акабский (см. 3 Цар. 9:26) заливы Красного моря., как по суше; когда же египтяне попытались сделать то же самое, они утонули11:29 См. Исх. 14:10-28; Иуда 5..

30Верой упали стены Иерихона после того, как семь дней подряд израильтяне обходили город11:30 См. Нав. 6..

31Верой блудница Раав, с миром приняв израильских лазутчиков, не была убита вместе с неверующими11:31 См. Нав. 2; 6:22-25; Иак. 2:25..

32Есть ли нужда говорить больше? Время не позволяет мне рассказать о Гедеоне, Вараке, Самсоне, Иеффае, Давиде, Самуиле и пророках. 33Они верой покоряли царства, восстанавливали справедливость, получали обещанное, закрывали пасти львам11:33 См. Дан. 6:16-23., 34гасили яростное пламя, спасались от острия меча. Их слабость становилась силой, они были крепкими в битве и обращали в бегство чужеземные армии. 35К женщинам возвращались их умершие11:35 См., напр., 3 Цар. 17:17-24; 4 Цар. 4:8-36. близкие, воскрешенные к жизни. Другие были замучены до смерти, отказавшись от предложенной им свободы. Они ожидали воскресения к лучшей жизни. 36Иные терпели насмешки и побои, а также цепи и темницу. 37Их побивали камнями, распиливали надвое, убивали мечом, им приходилось скитаться в овечьих и козьих шкурах, они были в нужде, их преследовали и над ними издевались. 38Те, кого весь мир не был достоин, скитались по пустыням, горам, пещерам и ущельям.

39Все они получили одобрение Бога за свою веру, но ни один из них при жизни не получил того, что было обещано, 40потому что и для нас Бог предусмотрел нечто лучшее, чтобы только вместе с нами они достигли совершенства.