Heberu 1 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 1:1-14

Ọmọ tí o ṣe pàtàkì fún àwọn Angẹli

1Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, 2ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: 3Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè. 4Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn.

51.5: Sm 2.7; 2Sa 7.14.Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé:

“Ìwọ ni ọmọ mi;

lónìí ni mo bí ọ”?

Àti pẹ̀lú pé;

“Èmi yóò jẹ́ baba fún un,

Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”?

61.6: De 32.43; Sm 97.7.Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,

“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”

71.7: Sm 104.4.Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé;

“Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí,

àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”

81.8-9: Sm 45.6-7.Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,

“Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni,

ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

9Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;

nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi ààmì òróró ayọ̀ yàn ọ

tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

10Ó tún sọ pé,

“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,

àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.

11Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀

gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.

12Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,

bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn.

Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ̀ kì yóò yípadà

àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”

131.13: Sm 110.1.Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,

“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ

di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?

14Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?

King James Version

Hebrews 1:1-14

1God, who at sundry times and in divers manners spake in time past unto the fathers by the prophets, 2Hath in these last days spoken unto us by his Son, whom he hath appointed heir of all things, by whom also he made the worlds; 3Who being the brightness of his glory, and the express image of his person, and upholding all things by the word of his power, when he had by himself purged our sins, sat down on the right hand of the Majesty on high; 4Being made so much better than the angels, as he hath by inheritance obtained a more excellent name than they. 5For unto which of the angels said he at any time, Thou art my Son, this day have I begotten thee? And again, I will be to him a Father, and he shall be to me a Son? 6And again, when he bringeth in the firstbegotten into the world, he saith, And let all the angels of God worship him. 7And of the angels he saith, Who maketh his angels spirits, and his ministers a flame of fire. 8But unto the Son he saith, Thy throne, O God, is for ever and ever: a sceptre of righteousness is the sceptre of thy kingdom. 9Thou hast loved righteousness, and hated iniquity; therefore God, even thy God, hath anointed thee with the oil of gladness above thy fellows. 10And, Thou, Lord, in the beginning hast laid the foundation of the earth; and the heavens are the works of thine hands: 11They shall perish; but thou remainest; and they all shall wax old as doth a garment; 12And as a vesture shalt thou fold them up, and they shall be changed: but thou art the same, and thy years shall not fail. 13But to which of the angels said he at any time, Sit on my right hand, until I make thine enemies thy footstool? 14Are they not all ministering spirits, sent forth to minister for them who shall be heirs of salvation?