Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Habakuku 1:1-17

1Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.

Ìráhùn Habakuku

21.2: Isa 13.1–14.23; 47; Jr 50–51.Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,

Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?

Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”

ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?

3Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé

Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?

Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;

ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.

4Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,

ìdájọ́ òdodo kò sì borí.

Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,

Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.

Ìdáhùn Olúwa

51.5: Ap 13.41.“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,

Kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.

Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín

tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,

bí a tilẹ̀ sọ fún yin.

61.6: If 20.9.Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,

àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn

tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já

láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.

7Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,

ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,

Yóò máa ti inú wọn jáde.

8Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,

wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ

àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;

wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,

wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun

9Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá

ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;

wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.

10Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín

wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.

Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;

Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á

11Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,

yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”

Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku

12Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?

Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú

Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;

Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí

13Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;

ìwọ kò le gbà ìwà ìkà

nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?

Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa

ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?

14Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,

bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso

15Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè

ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;

nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.

16Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,

ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀

nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn

tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.

17Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,

tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

哈巴谷書 1:1-17

1以下是哈巴谷先知得到的啟示。

哈巴谷的抱怨

2耶和華啊,

我要向你呼救到何時,

你才垂聽呢?

暴虐橫行,我向你呼求,

你卻不拯救。

3你為何讓我目睹罪惡?

你為何容忍邪惡?

我眼前盡是毀滅和暴力,

到處是紛爭和衝突。

4因此律法失效,

正義不彰,

惡人包圍義人,

正義被扭曲。

耶和華的答覆

5耶和華說:「你們環顧列國,

仔細察看,

必驚奇不已,

因為我要在你們的時代行一件事,

即使你們聽說了也不會相信。

6我要使兇殘、暴虐的迦勒底人興起。

他們要席捲天下,

強佔別人的家園。

7他們任意妄為,

令人膽戰心驚。

8「他們的馬比豹子還快,

比夜狼還猛。

他們的騎兵從遠方飛馳而來,

如鷹撲食。

9他們殘暴成性,

像狂風一樣撲來,

抓獲的俘虜多如塵沙。

10他們嘲笑君王,譏諷首領,

對一切堅城嗤之以鼻,

修築高臺將其攻取。

11他們如狂風橫掃而過,

這些有罪的人把自己的力量奉為神明。」

哈巴谷再次抱怨

12耶和華,

我的上帝,我的聖者啊,

你從亙古就存在,

你永不消逝1·12 你永不消逝」另有希伯來文抄本作「我們不會死」。

耶和華啊,你派迦勒底人來審判;

磐石啊,你立他們作施罰者。

13你的眼目極為清潔,

見不得邪惡,

也不能容忍罪惡。

但你為何容忍奸惡之人呢?

惡人吞滅比他們公義的人,

你為何默然不語呢?

14你為何使人像海裡的魚,

像沒有首領的爬蟲呢?

15迦勒底人用鉤子鉤住他們,

用漁網網住他們,

用拖網把他們聚在一起,

並因此而歡喜快樂。

16迦勒底人向漁網獻祭,

向漁網燒香,

因為他們靠漁網而富裕,

食物充足。

17難道他們要無休止地撒網,

無情地毀滅列國嗎?