Gẹnẹsisi 9 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 9:1-29

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Noa

19.1: Gẹ 1.28.Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé. 2Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. 3Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

49.4: Le 7.26,27; 17.10-14; De 12.16,23.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 5Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn.

69.6: Ek 20.13; Gẹ 1.26.“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀,

láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.

Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run

ni Ọlọ́run dá ènìyàn.

79.7: Gẹ 1.28.Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”

8Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, 9“Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 10Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. 11Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

12Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: 13Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé. 14Nígbàkígbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. 15Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. 16Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

17Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”

Àwọn ọmọ Noa

18Àwọn ọmọ Noa tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣemu, Hamu àti Jafeti. (Hamu ni baba Kenaani.) 19Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Noa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.

20Noa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà. 21Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀. 22Hamu tí í ṣe baba Kenaani sì rí baba rẹ̀ ní ìhòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta. 23Ṣùgbọ́n Ṣemu àti Jafeti mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòhò baba wọn. Wọ́n kọjú sẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòhò baba wọn.

24Nígbà tí Noa kúrò ní ojú ọtí, tí ó sì mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ kékeré ṣe sí i. 25Ó wí pé,

“Ègún ni fún Kenaani.

Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe

fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26Ó sì tún wí pé,

“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ṣemu

Kenaani yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣemu.

27Ọlọ́run yóò mú Jafeti gbilẹ̀,

Jafeti yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣemu

Kenaani yóò sì jẹ́ ẹrú fún un.”

28Noa wà láààyè fún irinwó ọdún dín àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi. 29Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Noa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín làádọ́ta (950), ó sì kú.

New International Version

Genesis 9:1-29

God’s Covenant With Noah

1Then God blessed Noah and his sons, saying to them, “Be fruitful and increase in number and fill the earth. 2The fear and dread of you will fall on all the beasts of the earth, and on all the birds in the sky, on every creature that moves along the ground, and on all the fish in the sea; they are given into your hands. 3Everything that lives and moves about will be food for you. Just as I gave you the green plants, I now give you everything.

4“But you must not eat meat that has its lifeblood still in it. 5And for your lifeblood I will surely demand an accounting. I will demand an accounting from every animal. And from each human being, too, I will demand an accounting for the life of another human being.

6“Whoever sheds human blood,

by humans shall their blood be shed;

for in the image of God

has God made mankind.

7As for you, be fruitful and increase in number; multiply on the earth and increase upon it.”

8Then God said to Noah and to his sons with him: 9“I now establish my covenant with you and with your descendants after you 10and with every living creature that was with you—the birds, the livestock and all the wild animals, all those that came out of the ark with you—every living creature on earth. 11I establish my covenant with you: Never again will all life be destroyed by the waters of a flood; never again will there be a flood to destroy the earth.”

12And God said, “This is the sign of the covenant I am making between me and you and every living creature with you, a covenant for all generations to come: 13I have set my rainbow in the clouds, and it will be the sign of the covenant between me and the earth. 14Whenever I bring clouds over the earth and the rainbow appears in the clouds, 15I will remember my covenant between me and you and all living creatures of every kind. Never again will the waters become a flood to destroy all life. 16Whenever the rainbow appears in the clouds, I will see it and remember the everlasting covenant between God and all living creatures of every kind on the earth.”

17So God said to Noah, “This is the sign of the covenant I have established between me and all life on the earth.”

The Sons of Noah

18The sons of Noah who came out of the ark were Shem, Ham and Japheth. (Ham was the father of Canaan.) 19These were the three sons of Noah, and from them came the people who were scattered over the whole earth.

20Noah, a man of the soil, proceeded9:20 Or soil, was the first to plant a vineyard. 21When he drank some of its wine, he became drunk and lay uncovered inside his tent. 22Ham, the father of Canaan, saw his father naked and told his two brothers outside. 23But Shem and Japheth took a garment and laid it across their shoulders; then they walked in backward and covered their father’s naked body. Their faces were turned the other way so that they would not see their father naked.

24When Noah awoke from his wine and found out what his youngest son had done to him, 25he said,

“Cursed be Canaan!

The lowest of slaves

will he be to his brothers.”

26He also said,

“Praise be to the Lord, the God of Shem!

May Canaan be the slave of Shem.

27May God extend Japheth’s9:27 Japheth sounds like the Hebrew for extend. territory;

may Japheth live in the tents of Shem,

and may Canaan be the slave of Japheth.”

28After the flood Noah lived 350 years. 29Noah lived a total of 950 years, and then he died.