Gẹnẹsisi 48 – YCB & HLGN

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 48:1-22

Manase àti Efraimu

1Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀. 2Nígbà tí a sọ fún Jakọbu pé, “Josẹfu ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Israẹli rọ́jú dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀.

348.3,4: Gẹ 28.13,14.Jakọbu wí fún Josẹfu pé, “El-Ṣaddai,48.3 El-Ṣaddai tí ó túmọ̀ sí, Ọlọ́run Olódùmarè fi ara hàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi. 4Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí o bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’

5“Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi. 6Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n. 748.7: Gẹ 35.16-19.Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata. Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu).

8Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?”

9Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”

Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.”

10Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.

11Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.”

12Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. 13Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. 14Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí.

15Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé,

“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi

Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀,

Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò

mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,

16Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,

kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.

Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi

Abrahamu àti Isaaki,

kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀

lórí ilẹ̀ ayé.”

17Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. 18Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”

19Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 2048.20: Hb 11.21.Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,

“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé,

‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”

Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.

21Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”

Ang Pulong Sang Dios

Genesis 48:1-22

Si Manase Kag si Efraim

1Sang ulihi may nagsugid kay Jose nga nagamasakit ang iya amay nga si Jacob. Gani gindala niya ang iya duha ka anak nga si Manase kag si Efraim kag nagkadto sa iya. 2Sang ginsugiran si Jacob nga nag-abot ang iya anak nga si Jose, gintinguhaan niya nga makapungko sa iya hiligdaan. 3Nagsiling si Jacob kay Jose, “Sang didto pa ako sa Luz, sa duta sang Canaan, nagpakita sa akon ang Makagagahom nga Dios kag ginbendisyunan niya ako. 4Siling niya, ‘Hatagan ko ikaw sang madamo nga mga kaliwat agod mangin amay ka sang madamo nga mga katawhan. Kag ihatag ko ang ini nga duta sang Canaan sa imo mga kaliwat kag mangin ila ini hasta san-o.’ ”

5Nagpadayon si Jacob sa pagsiling, “Ang duha mo ka anak nga si Efraim kag si Manase, nga natawo diri sa Egipto antes ako mag-abot, kabigon ko nga akon mga anak. Gani pareho kay Reuben kag kay Simeon, magahalin man sa ila ang mga Israelinhon nga mga tribo. 6Pero ang masunod mo nga mga anak magapabilin nga imo, kag makabaton sila sang palanublion halin kay Efraim kag kay Manase.

7“Nadumduman ko nga sang paghalin namon sa Padan kag nagapanglakaton kami sa duta sang Canaan, napatay ang imo iloy.48:7 ang imo iloy: sa Hebreo, si Raquel. Natabo ini sang malapit na kami sa Efrata, gani ginlubong ko na lang siya sa higad sang dalan nga pakadto sa Efrata”48:7 Efrata: sa Hebreo, Efrat. (nga amo man ang Betlehem.)

8Sang makita ni Israel48:8 Israel: Siya amo man si Jacob. ang mga anak ni Jose, nagpamangkot siya, “Sin-o sila?” 9Nagsabat si Jose, “Sila ang akon mga anak nga ginhatag sa akon sang Dios diri sa Egipto.” Dayon nagsiling si Israel, “Dal-a sila diri sa akon agod mabendisyunan ko sila.” 10Daw indi na makakita si Israel tungod sa iya katigulangon, gani gindala ni Jose ang iya mga anak palapit kay Israel. Ginhakos sila ni Israel kag ginhalukan. 11Nagsiling si Israel kay Jose, “Wala na gid ako maglaom nga makita ko pa ikaw, pero karon gintugot sang Dios nga indi lang ikaw ang akon makita kundi pati man ang imo mga anak.”

12Ginkuha dayon ni Jose ang iya mga anak sa sabak ni Israel kag nagluhod siya bilang pagtahod sa iya amay. 13Dayon ginpapalapit niya liwat ang iya mga anak sa ila lolo agod bendisyunan sila. Si Efraim sa may tuo ni Jose, bali sa wala ni Israel; kag si Manase sa may wala ni Jose, bali sa tuo ni Israel. 14Pero gintungtong ni Israel ang iya tuo nga kamot sa ulo ni Efraim nga amo ang manghod, kag gintungtong niya ang iya wala nga kamot sa ulo ni Manase nga amo ang magulang. 15Dayon ginbendisyunan niya sila nga nagasiling,

“Kabay pa nga bendisyunan ini nga mga bata sang Dios nga gin-alagad sang akon katigulangan nga si Abraham kag si Isaac, nga amo man ang Dios nga nagabantay sa akon halin sang akon pagkatawo hasta subong.

16Kag kabay pa nga bendisyunan man sila sang anghel nga nagluwas sa akon sa tanan nga katalagman.

Kabay pa nga madumduman ako kag ang akon katigulangan nga si Abraham kag si Isaac paagi sa ila.

Kag kabay pa nga magdamo gid sila sa kalibutan.”

17Pagkakita ni Jose nga ginatungtong sang iya amay ang iya tuo nga kamot sa ulo ni Efraim, naglain iya buot. Gani gin-uyatan niya ang kamot sang iya amay agod sayluhon kay Manase, 18kag nagsiling, “Tay, indi ina amo. Ari ang magulang; itungtong ang imo tuo nga kamot sa iya ulo.” 19Pero nagsabat ang iya amay, “Huo, nahibaluan ko man anak. Ang mga kaliwat ni Manase mangin bantog man nga katawhan. Pero mas mangin bantog ang mga kaliwat ni Efraim kag mangin madamo sila nga mga grupo sang mga katawhan.” 20Gani ginhimo niya si Efraim nga labaw sang sa kay Manase. Kag sang sadto nga adlaw, ginbendisyunan niya sila nga nagasiling, “Pagagamiton sang mga Israelinhon ang inyo mga ngalan sa pagbendisyon. Magasiling sila, ‘Kabay pa nga pakamaayuhon ka sang Dios pareho kay Efraim kag kay Manase.’ ”

21Dayon nagsiling si Israel kay Jose, “Madali na lang ako mapatay, pero indi kamo magkabalaka kay pagaupdan kamo sang Dios kag pabalikon sa duta sang inyo katigulangan. 22Kag ikaw Jose ang magapanubli sang Shekem kag indi ang imo mga utod. Ina nga lugar naangkon ko sa pagpakig-away sa mga Amornon.”