Gẹnẹsisi 43 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 43:1-34

Ìrìnàjò ẹ̀ẹ̀kejì lọ sí Ejibiti

1Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. 2Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Ejibiti tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ si wá fún wa.”

3Ṣùgbọ́n Juda wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’. 4Tí ìwọ yóò bá rán Benjamini arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ. 5Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ”

6Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”

7Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”

8Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú. 9Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mú un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ. 10Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”

11Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi 12ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀. 13Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ. 14Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọ́hùn ún àti Benjamini padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó ṣọ̀fọ̀ wọn náà ni.”

15Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Benjamini, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Josẹfu. 16Nígbà tí Josẹfu rí Benjamini pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì ṣe àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.”

17Ọkùnrin náà sì ṣe bí Josẹfu ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu. 18Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”

19Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Josẹfu, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ilé náà. 20Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá, ní òtítọ́ ni àwa ti sọ̀kalẹ̀ síyìn-ín láti wá ra oúnjẹ ní ìṣáájú. 21Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu un padà wá pẹ̀lú wa. 22A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.”

23Ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà ni fún yín, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìṣúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Simeoni jáde tọ̀ wọ́n wá.

24Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú. 25Wọ́n pèsè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Josẹfu di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán.

26Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 27Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?”

28Wọ́n dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láààyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un.

29Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi.” 30Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Josẹfu yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sọkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sọkún níbẹ̀.

31Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun.

32Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Ejibiti tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Ejibiti kò le bá ará Heberu jẹun nítorí ìríra pátápátá ló jẹ́ fún àwọn Ejibiti. 33A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátápátá dé orí èyí tí ó kéré pátápátá, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu. 34A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Josẹfu. Oúnjẹ Benjamini sì tó ìlọ́po márùn-ún ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láìsí ìdíwọ́.

Thai New Contemporary Bible

ปฐมกาล 43:1-34

การเดินทางไปอียิปต์ครั้งที่สอง

1ขณะนั้นการกันดารอาหารยังคงรุนแรงอยู่ 2เมื่อข้าวที่พวกเขาเอามาจากอียิปต์หมดแล้ว บิดาก็พูดกับพวกเขาว่า “จงกลับไปซื้ออาหารมาให้เราอีกหน่อย”

3แต่ยูดาห์พูดกับบิดาว่า “คนๆ นั้นกำชับไว้ว่า ‘เจ้าจะไม่ได้รับอนุญาตให้มาพบเรา ถ้าไม่พาน้องชายคนเล็กมาด้วย’ 4ถ้าพ่อยอมให้น้องไปกับพวกเรา พวกเราก็จะลงไปอียิปต์เพื่อซื้ออาหารมาให้พ่อ 5แต่ถ้าพ่อไม่ยอมให้น้องไป พวกเราก็จะไม่ไป เพราะเจ้านายคนนั้นสั่งไว้ว่า ‘เจ้าจะไม่ได้รับอนุญาตให้มาพบเรา ถ้าไม่พาน้องชายคนเล็กมาด้วย’ ”

6อิสราเอลผู้เป็นบิดาจึงถามว่า “ทำไมเจ้านำปัญหามาให้เราเช่นนี้ เจ้าไปบอกเขาทำไมว่ามีน้องชายอีกคนหนึ่ง?”

7พวกเขาตอบว่า “ก็เขาเจาะจงถามถึงพวกเราและครอบครัวของเรา เขาถามเราว่า ‘พ่อของเจ้ายังมีชีวิตอยู่หรือ? เจ้ามีน้องอีกคนหนึ่งไหม?’ เราเพียงแต่ตอบไปตามที่เขาถาม เราจะไปรู้หรือว่าเขาจะสั่งว่า ‘จงพาน้องชายของพวกเจ้าลงมาที่นี่’?”

8แล้วยูดาห์ก็พูดกับอิสราเอลบิดาของเขาว่า “ให้น้องไปกับเราเถิด เราจะได้ออกเดินทางทันที เพื่อว่าพวกเรา ตัวพ่อ และลูกๆ ของเราจะไม่ต้องอดตาย 9ตัวข้าเองจะรับประกันความปลอดภัยของเขา ให้พ่อถือว่าข้าเป็นผู้รับผิดชอบเขาเอง ถ้าข้าพาเขากลับมาให้พ่อเห็นหน้าไม่ได้ ก็ขอให้เป็นตราบาปติดตัวข้าไปตลอดชีวิต 10ถ้าพวกเราไม่มัวรีรออยู่เช่นนี้ ป่านนี้พวกเราคงไปและกลับมาเป็นครั้งที่สองแล้ว”

11ในที่สุดอิสราเอลก็พูดกับพวกเขาว่า “หากต้องเป็นเช่นนี้ ก็ให้ทำดังนี้ก็แล้วกัน คือพวกเจ้าจงเอาของดีที่สุดในดินแดนของเรา ได้แก่ยางไม้ น้ำผึ้ง เครื่องเทศ มดยอบ ถั่วพิสทาชิโอ และอัลมอนด์ใส่กระสอบไปเป็นของกำนัลแด่ชายผู้นั้น 12เอาเงินไปสองเท่าด้วย จะได้คืนเงินที่ติดมาในกระสอบ นี่อาจจะเป็นเรื่องผิดพลาดก็ได้ 13จงพาน้องไปด้วย ไปพบชายผู้นั้นทันที 14ขอพระเจ้าผู้ทรงฤทธิ์ทรงเมตตาพวกเจ้าเมื่ออยู่ต่อหน้าชายผู้นั้น เขาจะได้ปล่อยสิเมโอนและเบนยามินกลับมาพร้อมกับพวกเจ้า ส่วนเราถ้าจะต้องไว้ทุกข์ก็ต้องยอม”

15พวกเขาจึงนำของกำนัลและเงินสองเท่าพร้อมกับเบนยามิน รีบเดินทางลงไปอียิปต์และเข้าพบโยเซฟ 16เมื่อโยเซฟเห็นเบนยามินมาด้วยจึงสั่งคนต้นเรือนว่า “จงพาชายเหล่านี้ไปที่บ้านของข้า แล้วฆ่าสัตว์สักตัวหนึ่งเตรียมอาหารไว้ พวกเขาจะกินอาหารกลางวันกับข้า”

17เขาก็ทำตามคำสั่ง แล้วพาชายเหล่านั้นไปยังบ้านของโยเซฟ 18พวกเขาตกใจกลัวมากเมื่อถูกพามาที่บ้านของโยเซฟ พวกเขาต่างคิดว่า “พวกเราถูกพามาที่นี่เพราะเงินที่ถูกใส่คืนให้เราในกระสอบเมื่อคราวก่อนแน่ๆ เลย เขาต้องการจะใส่ความเรา เล่นงานเรา แล้วก็จับตัวพวกเราเป็นทาสพร้อมทั้งริบลาของพวกเรา”

19ดังนั้นพวกเขาจึงไปหาคนต้นเรือนของโยเซฟที่ประตูบ้านและพูดว่า 20“ขอโทษขอรับท่าน คราวก่อนเมื่อพวกเราเดินทางมาซื้ออาหารที่นี่ 21คืนแรกที่พวกเราแวะพักแรม พวกเราได้เปิดกระสอบออกมาดูก็เห็นเงินค่าข้าวอยู่ที่ปากกระสอบของพวกเราแต่ละคนตามจำนวนที่พวกเราจ่ายไปพอดี ดังนั้นพวกเราจึงเอามาคืน 22พวกเราได้นำเงินมาเพิ่มอีกเพื่อที่จะซื้ออาหาร พวกเราไม่รู้ว่าใครนำเงินเหล่านี้ใส่เข้าไปในกระสอบของพวกเรา”

23คนต้นเรือนตอบว่า “ทำใจให้สงบเถิด อย่ากลัวเลย พระเจ้าของพวกท่าน พระเจ้าของบิดาท่านทรงประทานทรัพย์สินที่อยู่ในกระสอบให้ท่าน เราได้รับเงินจากพวกท่านเรียบร้อยแล้ว” แล้วคนต้นเรือนก็พาสิเมโอนออกมาพบพวกเขา

24จากนั้นคนต้นเรือนพาพวกเขาเข้าไปในบ้านของโยเซฟ เอาน้ำมาให้ล้างเท้า และให้อาหารแก่ลาของพวกเขา 25พวกเขาก็เตรียมของกำนัลเพื่อมอบให้แก่โยเซฟซึ่งจะมาถึงตอนเที่ยง เพราะพวกเขาได้ยินว่าจะรับประทานอาหารด้วยกันที่นั่น

26เมื่อโยเซฟมาถึงบ้าน พวกพี่น้องก็มอบของกำนัลให้เขา และหมอบกราบเขาลงถึงดิน 27โยเซฟถามถึงทุกข์สุขของพวกเขาและถามอีกว่า “พ่อผู้ชราที่พวกเจ้าพูดถึงยังสุขสบายดีไหม? ยังมีชีวิตอยู่หรือเปล่า?”

28พวกเขาตอบว่า “พ่อของเราผู้รับใช้ของท่าน ยังมีชีวิตอยู่และสบายดี” และพวกเขาก็หมอบกราบราบกับพื้นต่อหน้าโยเซฟ

29ขณะที่โยเซฟมองดูพวกเขาและเห็นเบนยามินน้องชายร่วมมารดา จึงถามว่า “คนนี้หรือคือน้องชายคนสุดท้องที่พวกเจ้าพูดถึง?” แล้วพูดกับเบนยามินว่า “ลูกเอ๋ย ขอพระเจ้าทรงเมตตาเจ้าเถิด” 30เมื่อโยเซฟได้พบหน้าน้องชายก็ตื้นตันใจเหลือล้นจนต้องผลุนผลันออกไปหาที่ร้องไห้ เขาจึงเข้าไปร้องไห้ในห้องส่วนตัว

31จากนั้นเขาก็ล้างหน้าล้างตา ควบคุมอารมณ์ และกลับออกมาสั่งว่า “ยกอาหารมาเถิด”

32พวกเขาจัดอาหารให้โยเซฟรับประทานแต่ลำพัง โต๊ะของพี่น้องแยกต่างหาก ส่วนชาวอียิปต์ที่ร่วมรับประทานอาหารกับโยเซฟก็อยู่อีกโต๊ะหนึ่ง คนอียิปต์ไม่นั่งร่วมโต๊ะกับคนฮีบรูเพราะถือว่าเป็นสิ่งน่ารังเกียจสำหรับชาวอียิปต์ 33โยเซฟจัดให้ชายเหล่านั้นแต่ละคนนั่งเรียงกันตามลำดับอายุ ตั้งแต่คนโตสุดถึงคนเล็กสุด ทำให้ชายเหล่านั้นมองหน้ากันด้วยความสงสัย 34เมื่ออาหารส่วนของพวกเขาถูกส่งมาจากโต๊ะของโยเซฟ เบนยามินได้มากเป็นห้าเท่าของคนอื่นๆ พวกเขาก็กินดื่มร่วมกับโยเซฟจนอิ่มหนำสำราญ